Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jóòbù 3:1-26

3  Lẹ́yìn èyí ni Jóòbù la ẹnu rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pe ibi wá sórí ọjọ́ rẹ̀.+  Wàyí o, Jóòbù dáhùn, ó sì wí pé:   “Kí ọjọ́ tí a bí mi kí ó ṣègbé,+ Àti òru tí ẹnì kan sọ pé, ‘A ti lóyún abarapá ọkùnrin kan!’   Ní ti ọjọ́ yẹn, kí ó di òkùnkùn. Kí Ọlọ́run má ṣe wá a láti òkè, Bẹ́ẹ̀ ni kí ìmọ́lẹ̀ ojúmọ́ má tàn yanran sórí rẹ̀.   Kí òkùnkùn àti ibú òjìji tún gbà á padà. Kí àwọsánmà òjò máa gbé lórí rẹ̀. Kí àwọn ohun tí ń mú ọjọ́ ṣókùnkùn kó ìpayà bá a.+   Òru yẹn—kí ìṣúdùdù gbà á;+ Kí ó má yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ láàárín àwọn ọjọ́ tí ó wà nínú ọdún; Kí ó má wọnú iye oṣù òṣùpá.   Wò ó! Òru yẹn—kí ó di aláìlè-méso-jáde; Kí igbe ìdùnnú kankan má ṣe wá sínú rẹ̀.+  Kí àwọn tí ń fi ọjọ́ gégùn-ún fi í bú, Àwọn tí ó múra tán láti jí Léfíátánì.+   Kí àwọn ìràwọ̀ wíríwírí ọjọ́ rẹ̀ ṣókùnkùn; Kí ó dúró de ìmọ́lẹ̀, kí ó má sì sí ìkankan; Kí ó má sì rí ìtànyanran ọ̀yẹ̀. 10  Nítorí kò ti àwọn ilẹ̀kùn ikùn ìyá mi,+ Kí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ pa ìdààmú mọ́ kúrò ní ojú mi. 11  [Èé ṣe] tí èmi [kò] fi kú láti inú ilé ọlẹ̀ wá?+ Èé ṣe tí èmi kò fi jáde wá láti inú ikùn, kí n sì gbẹ́mìí mì nígbà yẹn? 12  Èé ṣe tí eékún fi pàdé mi, Èé sì ti ṣe tí ọmú+ tí èmi yóò mu fi pàdé mi? 13  Nítorí, nísinsìnyí, èmi ì bá ti dùbúlẹ̀, kí n bàa lè wà láìní ìyọlẹ́nu;+ Èmi ì bá ti sùn nígbà náà; èmi ì bá ti sinmi+ 14  Pẹ̀lú àwọn ọba àti àwọn agbani-nímọ̀ràn ilẹ̀ ayé,+ Àwọn tí ń kọ́ ibi ahoro fún ara wọn,+ 15  Tàbí pẹ̀lú àwọn ọmọ aládé tí ó ní wúrà, Àwọn tí ó fi fàdákà kún ilé wọn; 16  Tàbí, gẹ́gẹ́ bí ìṣẹ́nú tí ó fara sin,+ èmi kì bá ti sí, Bí àwọn ọmọ tí kò rí ìmọ́lẹ̀.+ 17  Ibẹ̀ ni àwọn ẹni burúkú ti ṣíwọ́ ṣìbáṣìbo,+ Ibẹ̀ sì ni àwọn tí agbára wọ́n ti tán ti sinmi.+ 18  Àní àwọn ẹlẹ́wọ̀n jùmọ̀ wà ní ìdẹ̀rùn; Ní ti tòótọ́, wọn kò gbọ́ ohùn ẹni tí ń kó wọn ṣiṣẹ́.+ 19  Ẹni kékeré àti ẹni ńlá wà bákan náà níbẹ̀,+ A sì dá ẹrú sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ọ̀gá rẹ̀. 20  Èé ṣe tí ó fi fún ẹni tí ó ní ìdààmú ní ìmọ́lẹ̀, Tí ó sì fún àwọn ọlọ́kàn kíkorò ní ìyè?+ 21  Èé ṣe tí àwọn tí ń dúró de ikú fi ń bẹ, tí kò sì sí,+ Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń bá a nìṣó ní wíwalẹ̀ nítorí rẹ̀ ju wíwalẹ̀ nítorí àwọn ìṣúra fífarasin? 22  Àwọn tí ń yọ ayọ̀ pọ̀rọ́, Wọ́n ń yọ ayọ̀ ńláǹlà nítorí pé wọ́n wá ibi ìsìnkú rí. 23  [Èé ṣe tí ó fi fún] abarapá ọkùnrin [ní ìmọ́lẹ̀], ẹni tí a ti fi ọ̀nà rẹ̀ pa mọ́,+ Ẹni tí Ọlọ́run sì sé mọ́ inú ọgbà?+ 24  Nítorí ṣáájú oúnjẹ mi, ìmí ẹ̀dùn mi dé,+ Ariwo igbe mi sì tú jáde bí omi;+ 25  Nítorí pé mo ti ní ìbẹ̀rùbojo fún ohun akún-fún-ìbẹ̀rùbojo, ó sì wá sórí mi; Ohun ti mo sì fòyà rẹ̀ dé bá mi.+ 26  Èmi kò wà láìní àníyàn, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò wà láìní ìyọlẹ́nu, Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sinmi, síbẹ̀, ṣìbáṣìbo dé.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé