Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jóòbù 29:1-25

29  Jóòbù tún tẹ̀ síwájú láti gbẹ́nu lé gbólóhùn òwe rẹ̀, ó sì ń bá a lọ ní wíwí pé:   “Ì bá ṣe pé mo wà gẹ́gẹ́ bí mo ti wà ní oṣù òṣùpá ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn,+ Bí ti àwọn ọjọ́ tí Ọlọ́run ń fi ìṣọ́ ṣọ́ mi;+   Nígbà tí ó mú kí fìtílà rẹ̀+ tàn sí mi lórí, Nígbà tí mo ń fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ rìn nínú òkùnkùn;   Gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ṣe rí ní àwọn ọjọ́ téńté ògo mi,+ Nígbà tí ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run wà ní àgọ́ mi;+   Nígbà tí Olódùmarè ṣì wà pẹ̀lú mi, Nígbà tí àwọn ẹmẹ̀wà mi wà yí mi ká!   Nígbà tí mo fi bọ́tà wẹ àwọn ìṣísẹ̀ mi, Tí àpáta sì ń tú ìṣàn òróró jáde fún mi;+   Nígbà tí mo jáde lọ sí ẹnubodè lẹ́bàá ìlú,+ Èmi a sì pèsè ìjókòó mi sílẹ̀ ní ojúde ìlú!+   Àwọn ọmọdékùnrin rí mi, wọ́n sì fi ara pa mọ́, Àwọn àgbàlagbà pàápàá dìde, wọ́n dúró,+   Àwọn ọmọ aládé gan-an ṣẹ́ ọ̀rọ̀ kù, Wọn a sì fi àtẹ́lẹwọ́ lé ẹnu wọn.+ 10  Ohùn àwọn aṣáájú fara sin, Àní ahọ́n wọ́n sì lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu wọn.+ 11  Nítorí etí gbọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pè mí ní aláyọ̀, Àní ojú sì rí, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ́rìí mi. 12  Nítorí èmi a gba ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ sílẹ̀,+ Àti ọmọdékùnrin aláìníbaba àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́.+ 13  Ìbùkún+ ẹni tí ń ṣègbé lọ—a wá sórí mi, Èmi a sì mú ọkàn-àyà opó yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀.+ 14  Mo fi òdodo wọ ara mi, ó sì wọ̀ mí.+ Ìdájọ́ òdodo mi dà bí aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá—àti láwàní. 15  Mo di ojú fún afọ́jú;+ Mo sì jẹ́ ẹsẹ̀ fún ẹni tí ó yarọ. 16  Mo jẹ́ baba gidi fún àwọn òtòṣì;+ Àti ẹjọ́ ẹni tí n kò mọ̀—èmi a wádìí rẹ̀ wò.+ 17  Èmi a sì fọ́ egungun páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ oníwà àìtọ́,+ Èmi a sì já ẹran ọdẹ gbà kúrò ní eyín rẹ̀. 18  Èmi sì máa ń sọ tẹ́lẹ̀ rí pé, ‘Èmi yóò gbẹ́mìí mì nínú ìtẹ́ mi,+ Èmi yóò sì sọ ọjọ́ mi di púpọ̀ bí egunrín iyanrìn.+ 19  Gbòǹgbò mi ṣí sílẹ̀ fún omi,+ Ìrì pàápàá yóò sì wà lórí ẹ̀tun mi mọ́jú. 20  Ògo mi jẹ́ ọ̀tun lọ́dọ̀ mi, Ọrun mi yóò sì tafà léraléra ní ọwọ́ mi.’ 21  Wọ́n fetí sí mi; wọ́n sì dúró, Wọn a sì dákẹ́ jẹ́ẹ́ fún ìmọ̀ràn mi.+ 22  Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ mi, wọn kì yóò tún sọ̀rọ̀ mọ́, Ọ̀rọ̀ mi a sì rọ̀ sí wọn lórí.+ 23  Wọ́n sì dúró dè mí bí ẹni pé fún òjò,+ Wọ́n sì la ẹnu wọn sílẹ̀ gbayawu de òjò ìgbà ìrúwé.+ 24  Èmi yóò rẹ́rìn-ín músẹ́ sí wọn—wọn kì yóò gbà á gbọ́— Wọn kì yóò sì mú ìmọ́lẹ̀ ojú mi rẹ̀wẹ̀sì.+ 25  Èmi a yan ọ̀nà fún wọn, mo sì ń jókòó bí olórí; Mo sì ń gbé bí ọba láàárín ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun rẹ̀,+ Gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń tu àwọn aṣọ̀fọ̀ nínú.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé