Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jóòbù 28:1-28

28  “Ní tòótọ́, ibi tí a ti lè rí fàdákà wàÀti ibi tí a ti lè rí wúrà tí wọ́n yọ́ mọ́;+   Àní irin ni a ń mú láti inú ekuru gan-an,+Bàbà ni a sì ń dà jáde láti inú òkúta.   Ó ti gbé òpin òkùnkùn kalẹ̀;Ó sì ń wá òkúta kàn nínú ìṣúdùdù àti ibú òjìjiDé gbogbo ààlà ìpẹ̀kun.+   Ó ri ojú ihò abẹ́lẹ̀ jìnnà sí ibi tí àwọn ènìyàn ti ń ṣe àtìpó,+Àwọn ibi ìgbàgbé tí ó jìnnà sí ẹsẹ̀;Àwọn kan lára àwọn ẹni kíkú ti fì làkàlàkà sísàlẹ̀, wọ́n ti rọ̀ dirodiro.   Ní ti ilẹ̀, inú rẹ̀ ni oúnjẹ ti ń jáde wá;+Ṣùgbọ́n lábẹ́ rẹ̀, a ti yí i sókè bí ẹni pé nípasẹ̀ iná.   Àwọn òkúta rẹ̀ jẹ́ ibi tí sàfáyà wà,+Ó sì ní ekuru wúrà.   Ipa ọ̀nà kan—kò sí ẹyẹ aṣọdẹ+ tí ó mọ̀ ọ́n,Bẹ́ẹ̀ ni àwòdì+ dúdú kò tajú kán rí i.   Àwọn ẹranko ẹhànnà ọlọ́lá-ńlá kò tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ di líle;Ẹgbọrọ kìnnìún kò rìn lórí rẹ̀.   Ó na ọwọ́ rẹ̀ jáde sórí akọ òkúta;Ó ti bi àwọn òkè ńláńlá ṣubú kúrò lórí gbòǹgbò wọn; 10  Ó ti la ojú ọ̀nà abẹ́lẹ̀ akún-fún-omi+ sínú àwọn àpáta,Ojú rẹ̀ sì ti rí ohun ṣíṣeyebíye gbogbo. 11  Àwọn ibi tí odò ti ń sun ni ó ti ṣe ìsédò sí,+Ó sì ń mú ohun tí ó pa mọ́ jáde wá sí ìmọ́lẹ̀. 12  Ṣùgbọ́n ọgbọ́n—ibo ni a ti lè rí i,+Ibo sì ni ibi tí òye wà? 13  Ẹni kíkú kò tíì mọ ìdíyelé rẹ̀,+A kò sì rí i ní ilẹ̀ àwọn alààyè. 14  Àní ibú omi wí pé,‘Kò sí nínú mi!’Òkun pẹ̀lú wí pé, ‘Kò sí lọ́dọ̀ mi!’+ 15  A kò lè fi ògidì wúrà ṣe pàṣípààrọ̀ rẹ̀,+A kò sì lè wọn fàdákà láti fi í ṣe iye owó rẹ̀. 16  A kò lè fi wúrà Ófírì+ san owó rẹ̀,Àní a kò lè fi òkúta ónísì ṣíṣọ̀wọ́n àti sàfáyà san án. 17  A kò lè fi í wé wúrà àti dígí,Bẹ́ẹ̀ ni a kò lè fi ohun èlò èyíkéyìí tí a fi wúrà tí a yọ́ mọ́ ṣe ṣe pàṣípààrọ̀ rẹ̀. 18  Iyùn+ àti òkúta kírísítálì alára ni a kì yóò mẹ́nu kàn,Ṣùgbọ́n ẹ̀kún àpò ọgbọ́n níye lórí ju èyí tí ó kún fún péálì.+ 19  A kò lè fi tópásì+ ti Kúṣì wé e;Àní a kò lè fi wúrà tí ó jẹ́ ògidì san án. 20  Ṣùgbọ́n ọgbọ́n—ibo ni ó ti wá,+Ibo sì ni ibi tí òye wà? 21  Ó ti fara sin àní fún ojú gbogbo àwọn tí ó wà láàyè,+Ó sì pa mọ́ fún àwọn ẹ̀dá tí ń fò lójú ọ̀run. 22  Ìparun àti ikú ti sọ pé,‘A ti fi etí wa gbọ́ ìròyìn nípa rẹ̀.’ 23  Ọlọ́run ni Ẹni tí ó lóye ọ̀nà rẹ̀,+Òun tìkára rẹ̀ sì mọ ipò rẹ̀, 24  Nítorí òun fúnra rẹ̀ ń wo ìkángun ilẹ̀ ayé pàápàá;+Ó rí gbogbo abẹ́ ọ̀run, 25  Láti ṣe ìwọ̀n fún ẹ̀fúùfù,+Nígbà tí ó fi ìwọ̀n pín omi;+ 26  Nígbà tí ó ṣe ìlànà fún òjò,+Àti ọ̀nà fún àwọsánmà ìjì tí ń sán ààrá, 27  Ìgbà náà ni ó rí ọgbọ́n, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀;Ó pèsè rẹ̀ sílẹ̀, ó sì yẹ̀ ẹ́ wò látòkè délẹ̀ pẹ̀lú. 28  Ó sì ń bá a lọ láti sọ fún ènìyàn pé,‘Wò ó! Ìbẹ̀rù Jèhófà—ìyẹn ni ọgbọ́n,+Yíyípadà kúrò nínú ìwà búburú sì ni òye.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé