Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jóòbù 27:1-23

27  Jóòbù sì tún tẹ̀ síwájú láti gbẹ́nu lé gbólóhùn òwe rẹ̀,+ ó sì ń bá a lọ ní wíwí pé:   “Bí Ọlọ́run ti ń bẹ,+ ẹni tí ó mú ìdájọ́ mi kúrò,+ Àti bí Olódùmarè ti ń bẹ, ẹni tí ó mú ọkàn mi korò,+   Nígbà tí gbogbo èémí mi ṣì ń bẹ nínú mi, Tí ẹ̀mí Ọlọ́run sì wà ní ihò imú mi,+   Ètè mi kì yóò sọ̀rọ̀ àìṣòdodo, Ahọ́n mi kì yóò sì sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn lábẹ́lẹ̀!   Kò ṣée ronú kàn níhà ọ̀dọ̀ mi pé èmi yóò polongo yín ní olódodo!+ Títí èmi yóò fi gbẹ́mìí mì, èmi kì yóò mú ìwà títọ́ mi+ kúrò lọ́dọ̀ mi!   Mo ti di ìṣẹ̀tọ́ mi mú, èmi kì yóò sì jẹ́ kí ó lọ;+ Ọkàn-àyà mi kì yóò ṣáátá mi fún èyíkéyìí nínú àwọn ọjọ́ mi.+   Kí ọ̀tá mi di ènìyàn burúkú ní gbogbo ọ̀nà,+ Kí ẹni tí ń dìtẹ̀ sí mi sì di oníwà àìtọ́ ní ti gidi.   Nítorí kí ni ìrètí apẹ̀yìndà bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ó ké e kúrò,+ Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé Ọlọ́run gba ọkàn rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ rẹ̀?+   Ọlọ́run yóò ha gbọ́ igbe ẹkún rẹ̀ Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé wàhálà dé bá a?+ 10  Tàbí yóò ha ní inú dídùn kíkọyọyọ sí Olódùmarè? Yóò ha máa pe Ọlọ́run nígbà gbogbo? 11  Èmi yóò fún yín ní ìtọ́ni nípa ọwọ́ Ọlọ́run; Èyí tí ń bẹ lọ́dọ̀ Olódùmarè ni èmi kì yóò fi pa mọ́.+ 12  Wò ó! Gbogbo yín ni ẹ ti rí ìran; Nítorí náà, èé ṣe tí ẹ fi fi ara yín hàn pé asán pátápátá ni yín?+ 13  Èyí ni ìpín ènìyàn burúkú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run;+ Ogún àwọn afìkà-gboni-mọ́lẹ̀ ni wọn yóò sì gbà láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè fúnra rẹ̀. 14  Bí àwọn ọmọ rẹ̀ bá di púpọ̀, fún idà ni;+ Àwọn ọmọ ìran rẹ̀ pàápàá kì yóò ní ànító oúnjẹ. 15  Àwọn tirẹ̀ tí ó là á já ní a ó sin nígbà ìyọnu àjàkálẹ̀ tí ń ṣekú pani, Àwọn opó wọn kì yóò sì sunkún.+ 16  Bí ó ba tilẹ̀ to fàdákà jọ pelemọ bí ekuru, Tí ó sì pèsè aṣọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí amọ̀, 17  Òun yóò pèsè sílẹ̀, ṣùgbọ́n olódodo ni yóò fi aṣọ náà wọ ara rẹ̀,+ Aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ sì ni yóò ní ìpín nínú fàdákà náà. 18  Ó ti kọ́ ilé ara rẹ̀ bí òólá lásán-làsàn, Àti bí àtíbàbà+ tí olùṣọ́ ṣe. 19  Òun yóò dùbúlẹ̀ ní ọlọ́rọ̀, ṣùgbọ́n a kì yóò kó nǹkan kan jọ; Ó ti la ojú rẹ̀, ṣùgbọ́n kì yóò sí nǹkan kan.+ 20  Ìpayà òjijì yóò dé bá a bí omi;+ Ẹ̀fúùfù oníjì yóò jí i gbé lọ dájúdájú ní òru. 21  Ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn yóò gbé e lọ,+ yóò sì lọ, Yóò sì fi àjà gbé e lọ kúrò ní ipò rẹ̀.+ 22  Yóò sì fi ara rẹ̀ sọ̀kò lù ú, kì yóò sì ní ìyọ́nú;+ Láìsí àní-àní, yóò gbìyànjú láti fẹsẹ̀ fẹ kúrò lọ́wọ́ agbára rẹ̀.+ 23  Ẹnì kan yóò pàtẹ́wọ́ sí i,+ Yóò sì súfèé+ sí i láti ipò rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé