Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jóòbù 25:1-6

25  Bílídádì+ ọmọ Ṣúáhì sì bẹ̀rẹ̀ sí dáhùn, ó sì wí pé:   “Agbára ìṣàkóso àti ìbẹ̀rùbojo ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀;+Ó ń pèsè àlàáfíà ní àwọn ibi gíga rẹ̀.   Ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ha níye?Ta sì ni ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kì í mọ́ sí lára?   Nítorí náà, báwo ni ẹni kíkú ṣe lè jàre níwájú Ọlọ́run,+Tàbí báwo ni ẹni tí obìnrin bí ṣe lè mọ́?+   Wò ó! Òṣùpá pàápàá wà, kò sì mọ́lẹ̀;Àwọn ìràwọ̀ pàápàá kò sì mọ́ lójú rẹ̀.   Áńbọ̀sìbọ́sí ẹni kíkú, tí ó jẹ́ ìdin,Àti ọmọ ènìyàn, tí ó jẹ́ kòkòrò mùkúlú!”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé