Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jóòbù 24:1-25

24  “Èé ṣe tí Olódùmarè fúnra rẹ̀ kò to ìgbà jọ pa mọ́,+Àní tí àwọn tí ó mọ̀ ọ́n kò sì rí àwọn ọjọ́ rẹ̀?+   Àwọn tí ń sún ààlà sẹ́yìn wà;+Agbo ẹran ọ̀sìn ni wọ́n já gbà, kí wọ́n lè máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn rẹ̀.   Wọ́n tilẹ̀ lé akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba dànù;Wọn fi ipá gba akọ màlúù opó gẹ́gẹ́ bí ohun ìdógò.+   Wọ́n ti àwọn òtòṣì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan kúrò lójú ọ̀nà;+Ní àkókò kan náà, àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ ní ilẹ̀ ayé ti fi ara pa mọ́.   Wò ó! Gẹ́gẹ́ bí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà+ nínú aginjùWọ́n ti jáde lọ nínú ìgbòkègbodò wọn, wọ́n ń wá oúnjẹ.Pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ ń fún olúkúlùkù ní oúnjẹ fún àwọn ọmọdékùnrin.   Wọ́n ń kórè oúnjẹ ẹran rẹ̀ ní pápá,Wọ́n sì fi ìkánjú wàràwàrà fi ọgbà àjàrà ẹni burúkú ṣe ìjẹ.   Ní ìhòòhò, wọ́n sùn mọ́jú láìní ẹ̀wù,+Àti láìní ìbora èyíkéyìí nínú òtútù.+   Ìjì òjò àwọn òkè ńláńlá mú wọn rin gbingbin,Wọ́n sì ní láti ta mọ́ àpáta nítorí pé kò sí ibi ààbò.+   Wọ́n já ọmọdékùnrin aláìníbaba gbà kúrò lẹ́nu ọmú pàápàá,+Wọ́n sì gba ohun tí ó wà lára ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ohun ìdógò.+ 10  Ní ìhòòhò, wọ́n yóò lọ káàkiri láìní ẹ̀wù,Àti ní ebi, wọn yóò ru àwọn ṣírí tí wọ́n kárúgbìn rẹ̀.+ 11  Wọ́n lo ìgbà ọ̀sán gangan láàárín ògiri àfidábùú ilẹ̀ onípele títẹ́jú;Wọn yóò tẹ ìfúntí wáìnì, síbẹ̀ òùngbẹ yóò gbẹ wọ́n.+ 12  Àwọn tí ń kú lọ ń kérora ṣáá láti inú ìlú ńlá,Ọkàn àwọn tí ó ti gbọgbẹ́ ikú sì ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́;+Ọlọ́run kò sì kà á sí ohun tí kò bẹ́tọ̀ọ́ mu.+ 13  Ní tiwọn, wọ́n wà lára àwọn aṣọ̀tẹ̀ sí ìmọ́lẹ̀;+Wọn kò dá àwọn ọ̀nà rẹ̀ mọ̀,Wọn kò sì gbé ní àwọn òpópónà rẹ̀. 14  Òṣìkàpànìyàn dìde ní ojúmọmọ,Ó sì tẹ̀ síwájú láti pa ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ àti òtòṣì;+Ó sì di ajìhànrín olè ní òru.+ 15  Ní ti ojú panṣágà,+ ó dúró de òkùnkùn alẹ́,+Ó wí pé, ‘Kò sí ojú tí yóò rí mi!’+Ó sì fi ìbòjú bo ojú ara rẹ̀. 16  Ó ti walẹ̀ lọ sínú àwọn ilé nínú òkùnkùn;Wọn yóò ti ara wọn mọ́lé ní ọ̀sán.Wọn kò mọ ojúmọmọ.+ 17  Nítorí tí òwúrọ̀ jẹ́ bákan náà bí ibú òjìji+ fún wọn,Nítorí wọ́n mọ ohun tí ìpayà òjijì ti ibú òjìji jẹ́. 18  Ó ń yára lójú omi.Abá ilẹ̀ wọn ni a óò gégùn-ún fún ní ilẹ̀ ayé.+Òun kì yóò yíjú síhà àwọn ọgbà àjàrà. 19  Ọ̀gbẹlẹ̀, àti ooru pẹ̀lú, já omi ìrì dídì gbà;Bẹ́ẹ̀ ni Ṣìọ́ọ̀lù ń ṣe sí àwọn tí ó dẹ́ṣẹ̀!+ 20  Ilé ọlẹ̀ yóò gbàgbé rẹ̀, ìdin yóò fi tadùntadùn fà á mu,+A kì yóò rántí rẹ̀ mọ́.+A ó sì ṣẹ́ àìṣòdodo bí igi.+ 21  Ó ń ní ìbálò pẹ̀lú àgàn tí kò bímọ,Àti pẹ̀lú opó,+ tí kò ṣe rere kankan fún. 22  Òun yóò sì fi agbára rẹ̀ fa àwọn alágbára lọ dájúdájú;Yóò dìde, ìwàláàyè rẹ̀ kì yóò sì dá a lójú. 23  Òun yóò yọ̀ǹda kí ó ní ìgbọ́kànlé,+ kí ó bàa lè ti ara rẹ̀ lẹ́yìn;Ojú rẹ̀ yóò sì wà ní ọ̀nà wọn.+ 24  Wọ́n ti ròkè fún ìgbà díẹ̀, lẹ́yìn náà, wọn kò sí mọ́,+A sì ti rẹ̀ wọ́n sílẹ̀;+ a fà wọ́n tu bí àwọn ẹlòmíràn,A sì ké wọn kúrò bí erín ṣírí ọkà. 25  Nítorí náà, nísinsìnyí o, ta ni yóò mú mi ní òpùrọ́Tàbí tí yóò sọ ọ̀rọ̀ mi di aláìjámọ́ nǹkan kan?”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé