Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jóòbù 21:1-34

21  Jóòbù sì bẹ̀rẹ̀ sí dáhùn, ó sì wí pé:   “Ẹ fara balẹ̀ fetí sí ọ̀rọ̀ mi,Kí ẹ sì jẹ́ kí èyí di ìtùnú yín.   Ẹ ní ìfaradà fún mi, èmi alára yóò sì sọ̀rọ̀;Lẹ́yìn tí mo bá sì ti sọ̀rọ̀ tán, olúkúlùkù yín lè máa fi mí ṣẹ̀sín.+   Ní tèmi, ènìyàn ha ni mo fi ìdàníyàn mi hàn fún bí?Tàbí èé ṣe tí ẹ̀mí mi kò di aláìlélẹ̀?   Ẹ yí ojú yín sọ́dọ̀ mi, kí ẹ sì máa fi kàyéfì wò sùn-ùn,Kí ẹ sì fi ọwọ́ yín lé ẹnu yín.+   Bí mo bá sì rántí, ìyọlẹ́nu ti bá mi pẹ̀lú,Ìgbọ̀njìnnìjìnnì sì ti gbá ẹran ara mi mú.   Èé ṣe tí àwọn ẹni burúkú fi ń wà láàyè nìṣó,+Tí wọ́n darúgbó, tí wọ́n sì di ẹni tí ó pọ̀ ní ọlà pẹ̀lú?+   Ọmọ wọ́n ti fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in pẹ̀lú wọn ní ìṣojú wọn,Àti àwọn ọmọ ìran wọn lójú wọn.   Ilé wọn wà ní àlàáfíà, láìsí ìbẹ̀rùbojo,+Ọ̀pá Ọlọ́run kò sì sí lára wọn. 10  Akọ màlúù rẹ̀ máa ń mú abo gbọlẹ̀ ní ti tòótọ́, kì í sì í fi àtọ̀ ṣòfò;Abo màlúù rẹ̀ ń bí,+ oyún kì í sì í ṣẹ́ lára rẹ̀. 11  Wọ́n ń rán àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin wọn jáde bí agbo ẹran,Àwọn ọmọ wọn tí ó jẹ́ ọkùnrin sì ń tọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri. 12  Wọ́n ń bá a lọ ní fífi ìlù tanboríìnì àti háàpù gbé ohùn wọn sókè,+Wọ́n sì ń yọ̀ sí ìró fèrè ape. 13  Wọ́n ń gbádùn ara wọn ní ọjọ́ wọn,+Ní ìṣẹ́jú kan, wọn a sì sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Ṣìọ́ọ̀lù. 14  Wọ́n sì sọ fún Ọlọ́run tòótọ́ pé, ‘Yí padà kúrò lọ́dọ̀ wa!+Àwa kò sì ní inú dídùn sí ìmọ̀ àwọn ọ̀nà rẹ.+ 15  Kí ni Olódùmarè jámọ́, tí àwa yóò fi máa sìn ín,+Báwo sì ni ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ ṣe lè ṣe wá láǹfààní?’+ 16  Wò ó! Wíwà tí wọ́n wà ní àlàáfíà kì í ṣe nínú agbára wọn.+Àní ìmọ̀ràn àwọn ẹni burúkú ti jìnnà réré sí mi.+ 17  Ìgbà mélòó ni a ń fẹ́ fìtílà àwọn ẹni burúkú pa,+Ìgbà mélòó sì ni àjálù wọ́n fi ń dé bá wọn?Ìgbà mélòó ni ó ń pín ìparun nínú ìbínú rẹ̀?+ 18  Wọ́n ha dà bí èérún pòròpórò níwájú ẹ̀fúùfù,+Àti bí ìyàngbò tí ẹ̀fúùfù oníjì jí gbé lọ? 19  Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò to ọṣẹ́ tí ènìyàn ń ṣe jọ pa mọ́ de àwọn ọmọ rẹ̀;+Òun yóò san án fún un, kí ó bàa lè mọ̀.+ 20  Ojú rẹ̀ yóò rí ìjẹrà òun fúnra rẹ̀,Òun yóò sì máa mu nínú ìhónú Olódùmarè.+ 21  Nítorí kí ni yóò jẹ́ inú dídùn rẹ̀ nínú ilé rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀,Nígbà tí a óò gé iye àwọn oṣù rẹ̀ sí méjì ní ti gidi?+ 22  Òun yóò ha kọ́ Ọlọ́run pàápàá ní ìmọ̀,+Nígbà tí Ẹni yẹn fúnra rẹ̀ ń ṣe ìdájọ́ àwọn ẹni gíga?+ 23  Ẹni yìí gan-an yóò kú nígbà tí ó ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ànító,+Nígbà tí ó bá wà láìní àníyàn, tí ó sì wà ní ìdẹ̀rùn gbáà; 24  Nígbà tí itan rẹ̀ kún fún ọ̀rá,Àní tí mùdùnmúdùn egungun rẹ̀ sì wà ní rírin. 25  Ẹlòmíràn yìí yóò sì kú nínú ìkorò ọkàn,Nígbà tí kò tíì jẹ àwọn nǹkan rere.+ 26  Wọn yóò jùmọ̀ dùbúlẹ̀ nínú ekuru,+Ìdin yóò sì bò wọ́n lórí.+ 27  Wò ó! Mo mọ ìrònú yín dáadáaÀti ìpètepèrò tí ẹ ó fi hu ìwà ipá sí mi.+ 28  Nítorí tí ẹ sọ pé, ‘Ibo ni ilé ọ̀tọ̀kùlú wà,Ibo sì ni àgọ́, àní ibùgbé àwọn ẹni burúkú wà?’+ 29  Ṣé ẹ̀yin kò béèrè lọ́wọ́ àwọn tí ń rin ìrìn àjò ní àwọn ojú ọ̀nà ni?Ẹ kò ha sì fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn àmì wọn pàápàá, 30  Pé a ń dá aṣebi sí ni ọjọ́ àjálù,+Àti pé a ń dá a nídè ní ọjọ́ ìbínú kíkan? 31  Ta ni yóò sọ fún un nípa ọ̀nà rẹ̀ ní ìṣojú rẹ̀?+Ta sì ni yóò san ohun tí òun fúnra rẹ̀ ti ṣe fún un?+ 32  Ní tirẹ̀, a óò mú un wá sí itẹ́ òkú,+A ó sì máa ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ibojì. 33  Ògúlùtu tí ó wà ní àfonífojì olójú ọ̀gbàrá yóò dùn lẹ́nu rẹ̀ dájúdájú,+Yóò sì wọ́ gbogbo aráyé tẹ̀ lé e lẹ́yìn,+Àwọn tí ó ṣáájú rẹ̀ kò sì níye. 34  Nítorí náà, ẹ wo bi ìgbìyànjú yín láti tù mí nínú ti já sí asán tó,+Àní àwọn èsì yín ṣì wà gẹ́gẹ́ bí ìwà àìṣòótọ́!”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé