Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jóòbù 20:1-29

20  Sófárì ọmọ Náámà sì bẹ̀rẹ̀ sí fèsì, ó sì wí pé:   “Nítorí náà ni àwọn ìrònú tí ń gbé mi lọ́kàn sókè fi dá mi lóhùn,Àní ní tìtorí ìrusókè inú mi.   Mo gbọ́ ìgbani-níyànjú tí ó kún fún ìwọ̀sí sí mi;Ẹ̀mí tí kò sì ní òye tí mo ní ń fún mi lésì.   Ìwọ ha ti fìgbà gbogbo mọ nǹkan yìí gan-an,Láti ìgbà tí a ti fi ènìyàn sórí ilẹ̀ ayé,+   Pé igbe ìdùnnú àwọn ènìyàn burúkú kì í pẹ́+Àti pé ayọ̀ yíyọ̀ apẹ̀yìndà wà fún ìṣẹ́jú kan?   Bí ìtayọlọ́lá rẹ̀ tilẹ̀ ga dé ọ̀run,+Tí orí rẹ̀ gan-an sì kan àwọsánmà,   Yóò ṣègbé títí láé bí imí rẹ̀;+Àní àwọn tí ó rí i yóò sọ pé, ‘Ibo ni ó wà?’+   Yóò fò lọ bí àlá, wọn kì yóò sì rí i;A ó sì lé e lọ bí ìran òru.+   Ojú tí ó tajú kán rí i kì yóò tún ṣe bẹ́ẹ̀+ mọ́,Ipò rẹ̀ kì yóò sì tún rí i mọ́.+ 10  Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò wá ojú rere àwọn ènìyàn rírẹlẹ̀,Ọwọ́ ara rẹ̀ yóò sì dá àwọn nǹkan rẹ̀ níníyelórí padà.+ 11  Egungun rẹ̀ kún fún okun inú ti ìgbà èwe rẹ̀,Ṣùgbọ́n yóò bá a dùbúlẹ̀ nínú ekuru lásán-làsàn.+ 12  Bí ohun tí ó burú bá ládùn ní ẹnu rẹ̀,Bí ó bá jẹ́ kí ó yọ́ lábẹ́ ahọ́n rẹ̀, 13  Bí ó bá ní ìyọ́nú sí i, tí kò sì fi í sílẹ̀,Bí ó bá sì ń dá a dúró ní àárín òkè ẹnu rẹ̀, 14  Oúnjẹ rẹ̀ yóò yí padà dájúdájú nínú ìfun rẹ̀;Yóò jẹ́ òróòró ṣèbé nínú rẹ̀. 15  Ó ti gbé ọlà mì, ṣùgbọ́n yóò pọ̀ ọ́ jáde;Ọlọ́run yóò tì í jáde kúrò nínú ikùn rẹ̀ gan-an. 16  Oró ṣèbé ni yóò fà mu;Ahọ́n paramọ́lẹ̀ ni yóò pa á.+ 17  Òun kì yóò rí àwọn ipadò láé,+Àní ìṣànrẹrẹ oyin àti bọ́tà. 18  Òun yóò dá dúkìá tí ó ní padà, kì yóò sì gbé e mì;Gẹ́gẹ́ bí ọlà láti inú òwò rẹ̀, ṣùgbọ́n tí kì yóò gbádùn.+ 19  Nítorí tí ó ti ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́, ó ti fi àwọn ẹni rírẹlẹ̀ sílẹ̀;Ó ti gba ilé tí òun kò kọ́.+ 20  Nítorí ó dájú pé òun kì yóò mọ ìdẹ̀rùn nínú ikùn rẹ̀;Òun kì yóò sá àsálà nípasẹ̀ àwọn ohun tí ó ní ìfẹ́-ọkàn sí.+ 21  Kò sí nǹkan kan tí ó ṣẹ́ kù fún un láti jẹ;Ìdí nìyẹn tí wíwà tí ó wà ní àlàáfíà kì yóò fi jẹ́ fún àkókò pípẹ́ títí. 22  Nígbà tí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ rẹ̀ bá wà ní téńté rẹ̀ ni yóò máa ṣàníyàn;+Gbogbo agbára àgbákò ibi ni yóò wá kọlù ú. 23  Kí ó ṣẹlẹ̀ pé, láti kún ikùn rẹ̀,Yóò rán ìbínú rẹ̀ jíjófòfò sórí rẹ̀,+Yóò sì rọ̀jò rẹ̀ lé e lórí, sínú ìwọ́rọ́kù rẹ̀. 24  Yóò fẹsẹ̀ fẹ+ kúrò nínú ìhámọ́ra irin;Ọrun tí a fi bàbà ṣe yóò gé e wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́. 25  Ohun ọṣẹ́ yóò tilẹ̀ gba ẹ̀yìn rẹ̀ jáde lọ,Ohun ìjà dídán yinrin yóò sì gba inú òróòró rẹ̀ jáde;+Àwọn ohun adajìnnìjìnnì-boni yóò lọ gbéjà kò ó.+ 26  Gbogbo òkùnkùn ni a ó fi pa mọ́ de àwọn ohun ìṣúra rẹ̀;Iná tí ẹnì kankan kò fẹ́ ni yóò jẹ ẹ́ tán;+Nǹkan yóò burú fún olùlàájá tí ó wà nínú àgọ́ rẹ̀. 27  Ọ̀run yóò tú ìṣìnà rẹ̀ síta,+Ilẹ̀ ayé yóò sì dìtẹ̀ mọ́ ọn. 28  Ọ̀wààrà òjò ńlá yóò gbé ilé rẹ̀ lọ;Àwọn nǹkan tí a dà jáde yóò wà ní ọjọ́ ìbínú rẹ̀.+ 29  Èyí ni ìpín ènìyàn burúkú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run,+Àní ogún rẹ̀ tí a polongo láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé