Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jóòbù 2:1-13

2  Lẹ́yìn náà, ó wá di ọjọ́ tí àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́ wọlé láti mú ìdúró wọn níwájú Jèhófà, Sátánì pẹ̀lú sì wọlé sáàárín wọn gan-an láti mú ìdúró rẹ̀ níwájú Jèhófà.+  Nígbà náà ni Jèhófà wí fún Sátánì pé: “Ibo gan-an ni ìwọ ti wá?” Látàrí ìyẹn, Sátánì dá Jèhófà lóhùn, ó sì wí pé: “Láti ẹnu lílọ káàkiri ní ilẹ̀ ayé àti rírìn káàkiri nínú rẹ̀.”+  Jèhófà sì ń bá a lọ láti sọ fún Sátánì pé: “Ìwọ ha ti fi ọkàn-àyà rẹ sí ìránṣẹ́ mi Jóòbù,+ pé kò sí ẹnì kankan tí ó dà bí rẹ̀ ní ilẹ̀ ayé, ọkùnrin aláìlẹ́bi àti adúróṣánṣán,+ tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run,+ tí ó sì ń yà kúrò nínú ohun búburú?+ Àní ó ṣì di ìwà títọ́+ rẹ̀ mú ṣinṣin, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o ru mí lọ́kàn sókè+ sí i, láti gbé e mì láìnídìí.”+  Ṣùgbọ́n Sátánì+ dá Jèhófà lóhùn, ó sì wí pé: “Awọ fún awọ, ohun gbogbo tí ènìyàn bá sì ní ni yóò fi fúnni nítorí ọkàn rẹ̀.+  Fún ìyípadà, jọ̀wọ́, na ọwọ́ rẹ, kí o sì fi kan egungun rẹ̀ àti ẹran ara rẹ̀, kí o sì rí i bóyá kì yóò bú ọ ní ojú rẹ gan-an.”+  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Jèhófà sọ fún Sátánì pé: “Òun nìyẹn ní ọwọ́ rẹ! Kìkì pé kí o ṣọ́ra fún ọkàn rẹ̀!”  Nítorí náà, Sátánì jáde kúrò níwájú Jèhófà,+ ó sì fi oówo afòòró-ẹ̀mí+ kọlu Jóòbù láti àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀.  Ó sì tẹ̀ síwájú láti mú àpáàdì láti máa fi họ ara rẹ̀; ó sì jókòó sínú eérú.+  Níkẹyìn, aya rẹ̀ wí fún un pé: “Ìwọ ha ṣì di ìwà títọ́ rẹ mú ṣinṣin?+ Bú Ọlọ́run, kí o sì kú!” 10  Ṣùgbọ́n ó wí fún un pé: “Bí ọ̀kan nínú àwọn òpònú+ obìnrin ṣe ń sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ sọ̀rọ̀. Àwa ha lè gba kìkì ohun rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ kí a má sì gba ohun búburú pẹ̀lú?”+ Nínú gbogbo èyí, Jóòbù kò fi ètè rẹ̀ dẹ́ṣẹ̀.+ 11  Àwọn alábàákẹ́gbẹ́ Jóòbù mẹ́ta sì wá gbọ́ gbogbo ìyọnu àjálù yìí tí ó ti dé bá a, wọ́n sì wá, olúkúlùkù láti ipò rẹ̀, Élífásì+ ará Témánì àti Bílídádì ọmọ Ṣúáhì+ àti Sófárì ọmọ Náámà.+ Nítorí náà, wọ́n pàdé pọ̀ nípasẹ̀ àdéhùn,+ láti wá bá a kẹ́dùn, kí wọ́n sì tù ú nínú.+ 12  Nígbà tí wọ́n gbé ojú sókè láti ibi jíjìnnàréré, nígbà náà, wọn kò dá a mọ̀. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sunkún, olúkúlùkù sì gbọn aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ tí kò lápá ya,+ wọ́n sì fọ́n ekuru sí ojú ọ̀run sí ara wọn lórí.+ 13  Wọ́n sì jókòó+ sórí ilẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ fún ọ̀sán méje àti òru méje, kò sì sí ẹnì kankan tí ó bá a sọ ọ̀rọ̀ kan, nítorí wọ́n rí i pé ìrora+ náà pọ̀ gidigidi.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé