Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jóòbù 19:1-29

19  Jóòbù sì bẹ̀rẹ̀ sí dáhùn, ó sì wí pé:   “Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ ó máa sún ọkàn mi bínú,+Tí ẹ ó sì máa fi ọ̀rọ̀ fọ́ mi sí wẹ́wẹ́?+   Ìgbà mẹ́wàá yìí ni ẹ ń bá a lọ láti bá mi wí lọ́nà mímúná;Ojú kò tì yín pé ẹ ń bá mi lò lọ́nà líle bẹ́ẹ̀.+   Kí a tilẹ̀ gbà pé mo ti ṣe àṣìṣe,+Ara mi ni àṣìṣe mi yóò wà.   Ní tòótọ́, bí ẹ bá gbé àgbéré ńláǹlà sí mi,+Tí ẹ sì fi ẹ̀gàn mi hàn pé ó bẹ́tọ̀ọ́ mu sí mi,+   Kí ẹ mọ̀ nígbà náà pé Ọlọ́run tìkára rẹ̀ ti ṣì mí lọ́nà,Àwọ̀n ìṣọdẹ rẹ̀ ni ó sì fi ká mi mọ́.+   Wò ó! Mo ń ké jáde ṣáá pé, ‘Ìwà ipá!’ ṣùgbọ́n n kò rí ìdáhùn;+Mo ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ ṣáá, ṣùgbọ́n kò sí ìdájọ́ òdodo.+   Àní ipa ọ̀nà mi ni ó ti fi ògiri òkúta+ dí, èmi kò sì lè kọjá;Ó sì fi òkùnkùn sí àwọn òpópónà mi.+   Ògo mi ni ó ti bọ́ kúrò lára mi,+Ó sì ṣí adé orí mi kúrò. 10  Ó bì mí wó ní ìhà gbogbo, mo sì lọ;Ó sì fa ìrètí mi tu bí igi. 11  Ìbínú rẹ̀ pẹ̀lú gbóná sí mi,+Ó sì ń kà mí sí elénìní ara rẹ̀. 12  Nínú ìsopọ̀ṣọ̀kan, ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun rẹ̀ wá, wọ́n sì mọ ọ̀nà wọn sókè lòdì sí mi,+Wọ́n sì dó yí àgọ́ mi ká. 13  Àwọn arákùnrin tèmi ni ó ti mú jìnnà réré sí mi,+Àní àwọn tí ó mọ̀ mí tilẹ̀ ti yà kúrò lọ́dọ̀ mi. 14  Àwọn ojúlùmọ̀ mi tímọ́tímọ́ ti kásẹ̀ nílẹ̀,+Àwọn tí mo sì mọ̀ ti gbàgbé mi, 15  Àwọn tí ń ṣe àtìpó nínú ilé mi;+ àti àwọn ẹrúbìnrin mi pàápàá kà mí sí àjèjì;Mo di ọmọ ilẹ̀ òkèèrè pátápátá ní ojú wọn. 16  Mo pe ìránṣẹ́ mi, ṣùgbọ́n kò dáhùn.Pẹ̀lú ẹnu ara mi ni mo fi taratara bẹ̀bẹ̀ fún ìyọ́nú lọ́dọ̀ rẹ̀. 17  Àní èémí mi ti di ohun ìkórìíra tẹ̀gbintẹ̀gbin sí aya mi,+Mo sì ti di òórùn burúkú sí àwọn ọmọ ikùn ìyá mi. 18  Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin ti kọ̀ mí;+Kí n kàn dìde lásán, wọn a sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ sí mi. 19  Gbogbo ènìyàn inú àwùjọ mi tímọ́tímọ́ ṣe họ́ọ̀ sí mi,+Àwọn tí mo sì nífẹ̀ẹ́ ti kẹ̀yìn sí mi.+ 20  Ní ti tòótọ́, egungun mi ti lẹ̀ mọ́ awọ ara mi àti ẹran ara mi,Ṣínńṣín, bí awọ eyín mi ni mo sì fi yè bọ́.+ 21  Ẹ fi ojú rere díẹ̀ hàn sí mi, ẹ fi ojú rere díẹ̀ hàn sí mi, ẹ̀yin alábàákẹ́gbẹ́ mi,+Nítorí pé ọwọ́ Ọlọ́run ti kàn mí.+ 22  Èé ṣe tí ẹ fi ń ṣe inúnibíni sí mi bí Ọlọ́run ti ṣe,+Tí ẹ kò sì ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ẹran ara mi gan-an? 23  Ì bá ṣe pé a kọ ọ̀rọ̀ mi sílẹ̀ nísinsìnyí!Ì bá ṣe pé a tilẹ̀ ṣàkọọ́lẹ̀ rẹ̀ sínú ìwé! 24  Pẹ̀lú kálàmù irin+ àti pẹ̀lú òjé,Ì bá ṣe pé títí láé ni a gbẹ́ wọn sára àpáta! 25  Èmi alára sì mọ̀ dáadáa pé olùtúnniràpadà+ mi ń bẹ láàyè,Àti pé, ní bíbọ̀ lẹ́yìn mi, òun yóò dìde sókè+ lórí ekuru. 26  Àti lẹ́yìn awọ ara mi, èyí tí wọ́n ti bó kúrò,—èyí!Bí ẹran ara mi tilẹ̀ joro, èmi yóò rí Ọlọ́run, 27  Ẹni tí èmi yóò tilẹ̀ rí fúnra mi,+Ẹni tí ojú mi gan-an yóò sì rí dájúdájú, ṣùgbọ́n kì í ṣe àjèjì.Àwọn kíndìnrín mi ti kọṣẹ́ ní inú mi lọ́hùn-ún. 28  Nítorí tí ẹ sọ pé, ‘Èé ṣe tí a fi ń ṣe inúnibíni+ sí i?’Nígbà tí a rí gbòǹgbò ọ̀ràn náà gan-an nínú mi. 29  Kí jìnnìjìnnì bá yín nítorí idà,+Nítorí pé idà túmọ̀ sí ìhónú lòdì sí àwọn ìṣìnà,Kí ẹ lè mọ̀ pé onídàájọ́ ń bẹ.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé