Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jóòbù 18:1-21

18  Bílídádì ọmọ Ṣúáhì sì bẹ̀rẹ̀ sí dáhùn, ó sì wí pé:   “Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin yóò máa fi òpin sí ọ̀rọ̀? Ó yẹ kí ẹ lóye pé, nígbà tí ó bá yá, àwa lè sọ̀rọ̀.   Èé ṣe tí a ó fi fi wá pe ẹranko,+ Tí a ó sì kà wá sí aláìmọ́ ní ojú yín?   Ó ń fa ọkàn ara rẹ̀ ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ nínú ìbínú rẹ̀. A ó ha pa ilẹ̀ ayé tì nítorí rẹ, Tàbí kí àpáta ṣí kúrò ní ipò rẹ̀?   Ìmọ́lẹ̀ àwọn ẹni burúkú pẹ̀lú ni a óò fẹ́ pa,+ Ìtapàrà iná rẹ̀ kì yóò sì tàn.   Àní ìmọ́lẹ̀ yóò ṣókùnkùn dájúdájú nínú àgọ́ rẹ̀,+ A ó sì fẹ́ fìtílà rẹ̀ pa nínú rẹ̀.   Àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ olókun inú yóò di híhá. Àní ìmọ̀ràn rẹ̀ yóò gbé e sọ nù.+   Nítorí ẹsẹ̀ ara rẹ̀ ni yóò mú un wọnú àwọ̀n ní tòótọ́, Yóò sì rìn lórí àsokọ́ra bí àwọ̀n.+   Pańpẹ́ yóò gbá a mú ní gìgísẹ̀;+ Ìdẹkùn+ yóò mú un. 10  Okùn ni a fi pa mọ́ sílẹ̀ dè é, Ohun èlò múnimúni ni a sì fi sí ipa ọ̀nà rẹ̀ dè é. 11  Dájúdájú, ìpayà òjijì yóò mú un ta gìrì nítorí jìnnìjìnnì ní gbogbo àyíká,+ Ní tòótọ́, yóò sì máa lépa rẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀. 12  Ìyàn yóò han okun inú rẹ̀ léèmọ̀, Àjálù+ sì múra tán láti mú un ta gẹ̀ẹ́gẹ̀ẹ́. 13  Yóò jẹ abala awọ ara rẹ̀; Àkọ́bí ikú ni yóò jẹ apá kan ara rẹ̀. 14  Ìgbọ́kànlé rẹ̀ ni a óò já kúrò nínú àgọ́ rẹ̀,+ Yóò sì sọ́gọ rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ ọba ìpayà. 15  Ohun tí kì í ṣe tirẹ̀ yóò máa gbé inú àgọ́ rẹ̀; Imí ọjọ́+ ni a óò fọ́n káàkiri sára ibi gbígbé rẹ̀. 16  Àní gbòǹgbò rẹ̀ yóò gbẹ dànù lábẹ́,+ Àti pé, lókè, ẹ̀tun rẹ̀ yóò rọ. 17  Àní mímẹ́nukàn án yóò ṣègbé dájúdájú kúrò ní ilẹ̀ ayé,+ Kì yóò sì ní orúkọ ní ojú pópó. 18  Wọ́n yóò tì í jáde kúrò nínú ìmọ́lẹ̀ sínú òkùnkùn, Wọn yóò sì lé e kúrò ní ilẹ̀ eléso. 19  Kì yóò ní ìran àtẹ̀lé àti àtọmọdọ́mọ láàárín àwọn ènìyàn rẹ̀,+ Kì yóò sì sí olùlàájá ní ibi tí ó ti ń ṣe àtìpó. 20  Àwọn ènìyàn tí ó wà ní Ìwọ̀-Oòrùn yóò wo ọjọ́ rẹ̀ sùn-ùn pẹ̀lú kàyéfì ní tòótọ́, Ó sì dájú pé ìgbọ̀njìnnìjìnnì yóò gbá àwọn ènìyàn tí ó wà ní Ìlà-Oòrùn pàápàá mú. 21  Kìkì pé ìwọ̀nyí ni àgọ́ oníwà àìtọ́, Èyí sì ni ipò ẹni tí kò mọ Ọlọ́run.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé