Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jóòbù 16:1-22

16  Jóòbù sì bẹ̀rẹ̀ sí dáhùn, ó sì wí pé:   “Mo ti gbọ́ ọpọ̀ nǹkan báwọ̀nyí.Olùtùnú tí ń dani láàmú ni gbogbo yín!+   Òpin ha wà fún àwọn ọ̀rọ̀ òfìfo?+Tàbí kí ní ń kan ọ́ lára, tí ìwọ fi dáhùn?   Èmi pẹ̀lú lè sọ̀rọ̀ dáadáa bí tiyín.Ì bá ṣe pé ọkàn yín wà ní ibi tí ọkàn mi wà,Ọ̀rọ̀ mi yóò ha múná ṣámúṣámú lòdì sí yín,+Èmi yóò ha sì mi orí mi sí yín?+   Èmi ì bá fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi fún yín lókun,+Ìtùnú ètè mi ì bá sì dá dúró—.   Bí mo bá sọ̀rọ̀, ìrora mi ni a kò dá dúró,+Bí mo bá sì ṣíwọ́ ṣíṣe bẹ́ẹ̀, kí ni ó lọ kúrò lọ́dọ̀ mi?   Kìkì pé nísinsìnyí, ó ti tán mi lókun;+Ó ti sọ gbogbo àwọn tí ó péjọ tì mí di ahoro.   Ìwọ pẹ̀lú gbá mi mú. Ó ti di ẹlẹ́rìí,+Tí rírù tí mo rù fi dìde sí mi. Ó ń jẹ́rìí ní ojú mi.   Àní ìbínú rẹ̀ ti fà mí ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, ó sì ń ṣe kèéta+ sí mi.Ní ti gidi, ó ń wa eyín pọ̀ sí mi.+Elénìní mi ń fẹjú mọ́ mi.+ 10  Wọ́n ti la ẹnu wọn gbàù sí mi,+Tẹ̀gàntẹ̀gàn ni wọ́n gbá mi ní ẹ̀rẹ̀kẹ́,Wọ́n wọ́ ara wọn jọpọ̀ lòdì sí mi ní iye púpọ̀.+ 11  Ọlọ́run fi mí lé àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin lọ́wọ́,Ó sì jù mí lógèdèǹgbé sọ́wọ́ àwọn ẹni burúkú.+ 12  Mo ti wá wà ní ìdẹ̀rùn, ṣùgbọ́n ó tẹ̀ síwájú láti gbọ̀n mí jìgìjìgì;+Ó sì rá mi mú ní ẹ̀yìn ọrùn, ó sì tẹ̀ síwájú láti fọ́ mi túútúú,Ó sì gbé mi kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àfojúsùn fún ara rẹ̀. 13  Àwọn tafàtafà rẹ̀+ pagbo yí mi ká;Ó la àwọn kíndìnrín mi+ sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, kò sì ní ìyọ́nú;Ó da àpò òróòró mi sórí ilẹ̀yílẹ̀. 14  Ó ń dá mi lu pẹ̀lú àlàfo tẹ̀ lé àlàfo;Ó sáré sí mi bí alágbára ńlá.+ 15  Aṣọ àpò ìdọ̀họ+ ni mo rán pọ̀ láti fi bo awọ ara mi,Mo sì ti ìwo mi bọ inú ekuru pàápàá.+ 16  Àní ojú mi ti di pípọ́n láti inú ẹkún sísun,+Ibú òjìji sì wà ní ìpéǹpéjú mi,+ 17  Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ìwà ipá ní àtẹ́lẹwọ́ mi,Àdúrà mi sì mọ́ gaara.+ 18  Ìwọ ilẹ̀, má bo ẹ̀jẹ̀ mi!+Má sì jẹ́ kí àyè kankan wà fún igbe ẹkún mi! 19  Pẹ̀lúpẹ̀lù nísinsìnyí, wò ó! ẹni tí ń jẹ́rìí nípa mi ń bẹ ní ọ̀run,Ẹlẹ́rìí mi sì ń bẹ ní ibi gíga.+ 20  Àwọn alábàákẹ́gbẹ́ mi jẹ́ agbọ̀rọ̀sọ lòdì sí mi;+Ojú mi ń wo Ọlọ́run láìlèsùn.+ 21  Ìpinnu náà ni a ó sì ṣe láàárín abarapá ọkùnrin àti Ọlọ́run.Bákan náà, bí i láàárín ọmọ ènìyàn àti ọmọnìkejì rẹ̀.+ 22  Nítorí pé kìkì ọdún díẹ̀ sí i ni yóò dé,Ipa ọ̀nà tí èmi kì yóò sì gbà padà ni èmi yóò gbà lọ.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé