Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jóòbù 15:1-35

15  Élífásì ará Témánì sì bẹ̀rẹ̀ sí dáhùn, ó sì wí pé:   “Ọlọ́gbọ́n yóò ha fi ìmọ̀ òfìfo dáhùn,+ Tàbí yóò ha fi ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn kún ara rẹ̀ níkùn?+   Wíwulẹ̀ fi ọ̀rọ̀ báni wí kì yóò wúlò, Àwọn àsọjáde lásán nìkan kì yóò ṣàǹfààní.   Bí ó ti wù kí ó rí, ìwọ fúnra rẹ mú kí ìbẹ̀rù níwájú Ọlọ́run ṣaláìní ipá kankan, Ìwọ sì dín àgbéyẹ̀wò èyíkéyìí kù níwájú Ọlọ́run.   Nítorí pé ìṣìnà rẹ kọ́ ẹnu rẹ lẹ́kọ̀ọ́, O sì yan ahọ́n àwọn afọgbọ́nhùwà.   Ẹnu ara rẹ ni ó pè ọ́ ní ẹni burúkú, kì í sì í ṣe èmi; Ètè ara rẹ sì dáhùn lòdì sí ọ.+   Ṣé ìwọ ni ènìyàn àkọ́kọ́ gan-an tí a máa bí,+ Tàbí a ha ti bí ọ pẹ̀lú ìrora ìrọbí ṣáájú àwọn òkè kéékèèké?+   Ìwọ ha fetí sí ọ̀rọ̀ àṣírí Ọlọ́run,+ Ìwọ ha sì fi ọgbọ́n mọ sọ́dọ̀ ara rẹ?   Kí ni ìwọ mọ̀ ní ti gidi, tí àwa kò mọ̀?+ Kí ni ìwọ lóye, tí kò sí lọ́dọ̀ wa pẹ̀lú? 10  Orí ewú àti àgbàlagbà wà pẹ̀lú wa,+ Ẹni tí ó pọ̀ ju baba rẹ lọ ní ọjọ́ orí. 11  Ìtùnú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kò ha tó fún ọ, Tàbí ọ̀rọ̀ tí a fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá ọ sọ? 12  Èé ṣe tí ọkàn-àyà rẹ fi gbé ọ lọ, Èé sì ti ṣe tí ojú rẹ fi ń kọ mànà? 13  Nítorí tí ìwọ yí ẹ̀mí rẹ padà lòdì sí Ọlọ́run fúnra rẹ̀, Ìwọ sì ti mú kí ọ̀rọ̀ jáde lọ láti ẹnu rẹ. 14  Kí ni ẹni kíkú jẹ́ tí yóò fi mọ́,+ Tàbí tí ẹnikẹ́ni tí obìnrin bí yóò fi jàre? 15  Wò ó! Kò ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀,+ Àní àwọn ọ̀run kò mọ́ ní ti gidi ní ojú rẹ̀.+ 16  Áńbọ̀sìbọ́sí ìgbà tí ènìyàn jẹ́ ẹni ìṣe-họ́ọ̀-sí àti ẹni ìbàjẹ́,+ Ènìyàn tí ń mu àìṣòdodo bí ẹni mu omi! 17  Èmi yóò polongo rẹ̀ fún ọ. Fetí sí mi!+ Àní èyí ni mo ti rí, nítorí náà, jẹ́ kí n ròyìn rẹ̀, 18  Èyí tí àwọn ọlọ́gbọ́n+ máa ń sọ Tí wọn kò sì fi pa mọ́, ní ti pé ó wá láti ọ̀dọ̀ baba wọn. 19  Àwọn nìkan ni a fún ní ilẹ̀, Kò sì sí àjèjì kankan tí ó gba àárín wọn kọjá. 20  Ẹni burúkú ń joró ní gbogbo ọjọ́ rẹ̀, Àní iye àwọn ọdún tí a fi pa mọ́ de afìkà-gboni-mọ́lẹ̀. 21  Ìró àwọn ohun akún-fún-ìbẹ̀rùbojo ń bẹ ní etí rẹ̀; Nígbà àlàáfíà, afiniṣèjẹ alára a dé bá a.+ 22  Kò gbà gbọ́ pé òun yóò padà wá láti inú òkùnkùn,+ A sì fi í pa mọ́ de idà. 23  Ó ń fẹsẹ̀ palẹ̀ kiri ní wíwá oúnjẹ—ibo ni ó wà?+ Ó mọ̀ dáadáa pé ọjọ́ òkùnkùn+ wà ní àrọ́wọ́tó òun. 24  Wàhálà àti làásìgbò ń kó ìpayà bá a;+ Wọ́n borí rẹ̀ bí ọba tí ó múra tán fún ìfipákọluni. 25  Nítorí pé ó na ọwọ́ ara rẹ̀ lòdì sí Ọlọ́run tìkára rẹ̀, Ó sì ń gbìyànjú láti fi àjùlọ han Olódùmarè;+ 26  Nítorí pé ó ń fi ọrùn líle sáré lòdì sí i, Pẹ̀lú ọ̀ṣọ́ òǹtẹ̀ nínípọn ti àwọn apata rẹ̀; 27  Nítorí pé ọ̀rá rẹ̀ ni ó fi bo ojú ara rẹ̀, Ó sì fi ọ̀rá sí abẹ́nú ara rẹ̀,+ 28  Ó wulẹ̀ ń gbé inú àwọn ìlú ńlá tí a ó pa rẹ́; Inú àwọn ilé tí àwọn ènìyàn kì yóò máa gbé títí lọ, Èyí tí ó dájú pé ó forí lé dídi òkìtì òkúta. 29  Òun kì yóò di ọlọ́rọ̀, ọlà rẹ̀ kì yóò sì ga gègèrè, Bẹ́ẹ̀ ni kì yóò tan ohun tí wọ́n kó jọ ká ilẹ̀ ayé.+ 30  Òun kì yóò yà kúrò nínú òkùnkùn; Ọwọ́ iná ni yóò gbẹ ẹ̀ka igi rẹ̀ dànù, Yóò sì yà sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan nípa ẹ̀fúùfù òjijì ẹnu Rẹ̀.+ 31  Kí ó má ṣe ní ìgbàgbọ́ nínú ohun àìníláárí, ní mímú un ṣáko lọ, Nítorí pé ohun aláìníláárí lásán-làsàn ni yóò rí gbà ní pàṣípààrọ̀; 32  Ṣáájú ọjọ́ rẹ̀ ni a óò mú un ṣẹ. Ọ̀mùnú rẹ̀ gan-an kì yóò sì gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ dájúdájú.+ 33  Òun yóò gbọn èso àjàrà rẹ̀ aláìpọ́n dànù bí àjàrà, Yóò sì já ìtànná rẹ̀ sọ nù bí igi ólífì. 34  Nítorí pé àpéjọ àwọn apẹ̀yìndà jẹ́ aláìlè-méso-jáde,+ Iná ni yóò sì jẹ àwọn àgọ́ àbẹ̀tẹ́lẹ̀.+ 35  Lílóyún ìjàngbọ̀n àti bíbí ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́ ń bẹ,+ Àní ikùn wọ́n sì ń múra ẹ̀tàn sílẹ̀.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé