Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jóòbù 14:1-22

14  “Ènìyàn, tí obìnrin bí,+ Ọlọ́jọ́ kúkúrú ni,+ ó sì kún fún ṣìbáṣìbo.+   Ó jáde wá bí ìtànná, a sì ké e kúrò,+ Ó sì fẹsẹ̀ fẹ bí òjìji,+ kò sì sí mọ́.   Bẹ́ẹ̀ ni, ẹni yìí ni ìwọ tẹjú mọ́, Ìwọ sì mú mi wá sínú ìdájọ́+ pẹ̀lú ara rẹ.   Ta ní lè mú ẹni tí ó mọ́ jáde láti inú ẹni tí kò mọ́?+ Kò sí ẹnì kankan.   Bí a bá ti pinnu àwọn ọjọ́ rẹ̀,+ Iye oṣù rẹ̀ ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ; Ìwọ ti pa àṣẹ àgbékalẹ̀ fún un, kí ó má bàa lọ ré kọjá rẹ̀.   Yí ojú rẹ kúrò lára rẹ̀, kí ó bàa lè sinmi,+ Títí òun yóò fi ní ìdùnnú ní ọjọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí lébìrà tí a háyà ti ń ní ìdùnnú.   Nítorí pé ìrètí wà fún igi pàápàá. Bí a bá gé e lulẹ̀, àní yóò tún hù,+ Ẹ̀ka igi rẹ̀ kì yóò sì kásẹ̀ nílẹ̀.   Bí gbòǹgbò rẹ̀ bá di ogbó nínú ilẹ̀, Tí kùkùté rẹ̀ sì kú nínú ekuru,   Nígbà tí ó bá gbọ́ ìtasánsán omi, yóò hù,+ Yóò sì mú ẹ̀tun bí ọ̀gbìn tuntun wá dájúdájú.+ 10  Ṣùgbọ́n abarapá ọkùnrin kú, ó sì wà nílẹ̀ láìlè gbéra sọ; Ará ayé sì gbẹ́mìí mì, ibo ni ó sì wà?+ 11  Omi ń dàwátì nínú òkun, Odò sì ń fà, ó sì ń gbẹ táútáú.+ 12  Ènìyàn pẹ̀lú yóò dùbúlẹ̀, kì yóò sì dìde.+ Títí ọ̀run kì yóò fi sí mọ́, wọn kì yóò jí,+ Bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò ta wọ́n jí kúrò lójú oorun wọn.+ 13  Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fi mí pa mọ́ sínú Ṣìọ́ọ̀lù,+ Pé ìwọ yóò pa mí mọ́ ní ìkọ̀kọ̀ títí ìbínú rẹ yóò fi yí padà, Pé ìwọ yóò yan àkókò kan kalẹ̀+ fún mi, kí o sì rántí mi!+ 14  Bí abarapá ènìyàn bá kú, ó ha tún lè wà láàyè bí?+ Jálẹ̀ gbogbo ọjọ́ òpò tí mo ní láti ṣe lápàpàǹdodo ni èmi yóò fi dúró,+ Títí ìtura mi yóò fi dé.+ 15  Ìwọ yóò pè, èmi fúnra mi yóò sì dá ọ lóhùn.+ Ìwọ yóò ṣe àfẹ́rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. 16  Nítorí pé nísinsìnyí, ìwọ ń ka àwọn ìṣísẹ̀ mi pàápàá;+ Ìwọ kò ṣọ́ nǹkan mìíràn bí kò ṣe ẹ̀ṣẹ̀ mi.+ 17  A fi èdìdì di ìdìtẹ̀ mi sínú àpò,+ Ìwọ sì fi àtè lẹ ìṣìnà mi. 18  Bí ó ti wù kí ó rí, òkè ńlá, tí ń ṣubú lọ, yóò pòórá, Àní àpáta sì ni a óò ṣí kúrò ní ipò rẹ̀. 19  Dájúdájú, omi a máa yinrin òkúta pàápàá; Ìtújáde rẹ̀ a máa gbá ekuru ilẹ̀ lọ. Bí o ṣe pa àní ìrètí ẹni kíkú run nìyẹn. 20  Ìwọ borí rẹ̀ títí láé, tí ó fi jẹ́ pé ó lọ;+ Ìwọ ń ba ojú rẹ̀ jẹ́, tí ó fi jẹ́ pé o rán an lọ. 21  Àwọn ọmọ rẹ̀ ni a bọlá fún, ṣùgbọ́n òun kò mọ̀;+ Wọ́n sì di aláìjámọ́ pàtàkì; ṣùgbọ́n kò ronú nípa wọn. 22  Kìkì pé ẹran ara rẹ̀ yóò máa ro ó nígbà tí ó ṣì wà lára rẹ̀, Ọkàn rẹ̀ yóò sì máa ṣọ̀fọ̀ nígbà tí ó ṣì wà nínú rẹ̀.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé