Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jóòbù 13:1-28

13  “Wò ó! Gbogbo èyí ni ojú mi ti rí,Etí mi ti gbọ́, ó sì ronú nípa rẹ̀.   Ohun tí ẹ̀yin mọ̀ ni èmi pẹ̀lú mọ̀ dáadáa;Èmi kò rẹlẹ̀ sí yín.+   Bí ó ti wù kí ó rí, èmi, ní tèmi, yóò bá Olódùmarè fúnra rẹ̀ sọ̀rọ̀,+Èmi yóò sì ní inú dídùn sí bíbá Ọlọ́run jiyàn.   Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ẹ̀yin jẹ́ olùfi èké rẹ́ni lára;+Gbogbo yín jẹ́ oníṣègùn tí kò ní láárí.+   Ẹ̀yin ì bá kúkú dákẹ́ pátápátá,Kí ó lè jẹ́ ọgbọ́n níhà ọ̀dọ̀ yín!+   Ẹ jọ̀wọ́, ẹ gbọ́ ìjiyàn àfidáhùnpadà mi,+Ẹ sì fetí sí ẹjọ́ ètè mi.   Ẹ̀yin yóò ha sọ̀rọ̀ àìṣòdodo gbe Ọlọ́run,Ẹ̀yin yóò ha sì sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn gbè é?+   Ẹ̀yin yóò ha máa ṣe ojúsàájú sí i,+Tàbí ẹ̀yin yóò ha ṣàríyànjiyàn lábẹ́ òfin gbe Ọlọ́run tòótọ́?   Ó ha dára pé kí ó lù yín lẹ́nu gbọ́rọ̀?+Tàbí ẹ̀yin yóò ha fi í ṣeré bí ènìyàn ṣe ń fi ẹni kíkú ṣeré? 10  Òun yóò fi ìbáwí tọ́ yín sọ́nà dájúdájú+Bí ẹ bá gbìyànjú láti fi ojúsàájú hàn ní ìkọ̀kọ̀;+ 11  Iyì rẹ̀ gan-an kì yóò ha mú yín ta gìrì nítorí jìnnìjìnnì,Tí ìbẹ̀rùbojo rẹ̀ gan-an yóò sì ṣubú tẹ̀ yín?+ 12  Àwọn ọ̀rọ̀ mánigbàgbé yín jẹ́ òwe eérú;Àwọn ọ̀ṣọ́ òǹtẹ̀ apata yín sì dà bí àwọn ọ̀ṣọ́ òǹtẹ̀ apata amọ̀.+ 13  Ẹ dákẹ́ níwájú mi, kí èmi alára lè sọ̀rọ̀.Lẹ́yìn náà, kí ohun yòówù kí ó jẹ́ dé bá mi! 14  Èé ṣe tí mo fi fi eyín mi gbé ẹran ara mi,Tí mo sì fi ọkàn mi sí àtẹ́lẹwọ́ mi?+ 15  Bí yóò bá tilẹ̀ pa mí, èmi kì yóò ha dúró?+Kìkì pé èmi yóò jiyàn ní ìṣojú rẹ̀ ní ìtìlẹyìn fún àwọn ọ̀nà tèmi. 16  Òun yóò jẹ́ ìgbàlà mi pẹ̀lú,+Nítorí pé kò sí apẹ̀yìndà kankan tí yóò wọlé sí iwájú rẹ̀.+ 17  Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi yékéyéké,+Ẹ sì jẹ́ kí ìpolongo mi wà ní etí yín. 18  Ẹ jọ̀wọ́, ẹ wò ó! mo ti gbé ẹjọ́ ìdájọ́ òdodo kalẹ̀;+Èmi mọ̀ dáadáa pé èmi alára jàre. 19  Ta ni yóò bá mi fà á?+Nítorí pé bí mo bá dákẹ́ jẹ́ẹ́ nísinsìnyí, èmi yóò wulẹ̀ gbẹ́mìí mì ni! 20  Kìkì ohun méjì ni kí o má ṣe sí mi;Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, èmi kì yóò fi ara mi pa mọ́ kìkì ní tìtorí tìrẹ;+ 21  Gbé ọwọ́ rẹ jìnnà réré kúrò lára mi,Àti jìnnìjìnnì rẹ—kí ó má ṣe kó ìpayà bá mi.+ 22  Yálà kí o pè, kí èmi fúnra mi lè dáhùn;Tàbí kí n sọ̀rọ̀, kí o sì fún mi ní ìdáhùn. 23  Ọ̀nà wo ni mo gbà ní àwọn ìṣìnà àti ẹ̀ṣẹ̀?Jẹ́ kí n mọ ìdìtẹ̀ mi àti ẹ̀ṣẹ̀ mi. 24  Èé ṣe tí o fi ojú rẹ gan-an pa mọ́,+Tí o sì kà mí sí ọ̀tá rẹ?+ 25  Ìwọ yóò ha mú kí ewé lásán-làsàn tí a ń gbá kiri gbọ̀n pẹ̀pẹ̀,Tàbí kí o máa lépa àgékù pòròpórò gbígbẹ lásán-làsàn? 26  Nítorí pé ìwọ ń kọ̀wé àwọn ohun kíkorò mọ́ mi ṣáá,+O sì mú kí n ní àbájáde àwọn ìṣìnà ìgbà èwe mi.+ 27  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ìwọ ti ẹsẹ̀ mi bọ inú àbà,+O sì ń ṣọ́ gbogbo ipa ọ̀nà mi;Nítorí pé àtẹ́lẹsẹ̀ mi ni ìwọ gbé ipa ọ̀nà tìrẹ gbà. 28  Ó sì dà bí ohun jíjẹrà tí ń gbó lọ;+Bí ẹ̀wù tí òólá jẹ tán ní ti gidi.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé