Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jóòbù 12:1-25

12  Jóòbù sì bẹ̀rẹ̀ sí dáhùn, ó sì wí pé:   “Ní tòótọ́, ẹ̀yin ni àwọn ènìyàn náà, Ẹ̀yin ni ọgbọ́n yóò sì bá kú!+   Èmi pẹ̀lú ní ọkàn-àyà+ bí ẹ̀yin. Èmi kò rẹlẹ̀ sí yín,+ Ọ̀dọ̀ ta sì ni nǹkan báwọ̀nyí kò sí?   Ẹni tí ọmọnìkejì rẹ̀ ń fi rẹ́rìn-ín ni mo dà,+ Ẹni tí ń pe Ọlọ́run pé kí ó dá òun lóhùn.+ Ẹni tí a ń fi rẹ́rìn-ín ni olódodo, aláìlẹ́bi.   Aláìní àníyàn fojú tín-ín-rín àkúrun nínú ìrònú;+ A pèsè rẹ̀ sílẹ̀ fún àwọn ẹlẹ́sẹ̀ gbígbò yèpéyèpé.+   Àgọ́ àwọn afiniṣèjẹ wà láìní ìdààmú,+ Àwọn tí ń mú kí Ọlọ́run ní ìhónú sì wà ní ipò àìséwu Tí ó jẹ́ ti ẹni tí ó mú ọlọ́run kan wá ní ọwọ́ rẹ̀.+   Bí ó ti wù kí ó rí, jọ̀wọ́ béèrè lọ́wọ́ àwọn ẹran agbéléjẹ̀, wọn yóò sì fún ọ ní ìtọ́ni;+ Àti àwọn ẹ̀dá abìyẹ́lápá ojú ọ̀run pẹ̀lú, wọn yóò sì sọ fún ọ.+   Tàbí kí o fi ọkàn-ìfẹ́ hàn sí ilẹ̀ ayé, yóò sì fún ọ ní ìtọ́ni;+ Àwọn ẹja inú òkun+ yóò sì polongo rẹ̀ fún ọ.   Èwo nínú gbogbo ìwọ̀nyí ni kò mọ̀ dáadáa Pé ọwọ́ Jèhófà ni ó ṣe èyí,+ 10  Ọwọ́ ẹni tí ọkàn+ olúkúlùkù ẹni tí ó wà láàyè wà Àti ẹ̀mí gbogbo ẹran ara ènìyàn?+ 11  Etí kò ha ń dán ọ̀rọ̀ wò+ Bí òkè ẹnu+ ti ń tọ́ oúnjẹ wò? 12  Ọgbọ́n kò ha wà láàárín àwọn àgbàlagbà+ Àti òye nínú gígùn àwọn ọjọ́? 13  Ọgbọ́n àti agbára ńlá wà pẹ̀lú rẹ̀;+ Ó ní ìmọ̀ràn àti òye.+ 14  Wò ó! Ó ya lulẹ̀, kí ó má bàa sí gbígbéró;+ Ó mú kí a tì í mọ́ ènìyàn, kí a má bàa ṣí i.+ 15  Wò ó! Ó dá omi dúró, wọ́n sì gbẹ táútáú;+ Ó sì rán wọn lọ, wọ́n sì yí ilẹ̀ ayé padà.+ 16  Okun àti ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ wà pẹ̀lú rẹ̀;+ Ẹni tí ń ṣe àṣìṣe àti ẹni tí ń múni ṣáko lọ jẹ́ tirẹ̀;+ 17  Ó ń mú kí àwọn agbani-nímọ̀ràn lọ láìwọ bàtà,+ Ó sì ń mú kí àwọn onídàájọ́ di ayírí. 18  Ìdè àwọn ọba ni ó ń tú ní ti tòótọ́,+ Ó sì ń de ìgbànú mọ́ ìgbáròkó wọn. 19  Ó ń mú kí àwọn àlùfáà rìn láìwọ bàtà,+ Ó sì ń dojú àwọn tí ó ti jókòó pa dé;+ 20  Ó ń mú ọ̀rọ̀ kúrò lẹ́nu àwọn olùṣòtítọ́, Ó sì ń gba ìlóyenínú àwọn àgbààgbà lọ; 21  Ó ń da ìfojú-tín-ín-rín sára àwọn ọ̀tọ̀kùlú,+ Àmùrè àwọn alágbára ni ó sì ń sọ di dídẹ̀ ní ti tòótọ́; 22  Ó ń tú àwọn ohun ìjìnlẹ̀ síta láti inú òkùnkùn,+ Ó sì ń mú ibú òjìji jáde wá sínú ìmọ́lẹ̀; 23  Ó ń mú kí àwọn orílẹ̀-èdè di ńlá, kí ó lè pa wọ́n run;+ Ó ń tan àwọn orílẹ̀-èdè kálẹ̀, kí ó lè kó wọn lọ; 24  Ó ń mú ọkàn-àyà olórí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà kúrò, Kí ó lè mú wọn rìn gbéregbère ní ibi ṣíṣófo,+ níbi tí ọ̀nà kò sí. 25  Wọ́n ń táràrà nínú òkùnkùn,+ níbi tí ìmọ́lẹ̀ kò sí, Kí ó lè mú wọn rìn gbéregbère bí ọ̀mùtípara.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé