Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jóòbù 11:1-20

11  Sófárì ọmọ Náámà+ sì bẹ̀rẹ̀ sí dáhùn, ó sì wí pé:   “Ògìdìgbó ọ̀rọ̀ yóò ha lọ láìgba ìdáhùn, Tàbí aṣògo lásán-làsàn yóò ha jàre?   Òfìfo ọ̀rọ̀ rẹ yóò ha pa àwọn ènìyàn lẹ́nu mọ́, Ìwọ yóò ha sì máa bá a lọ láti fini ṣẹ̀sín láìsí ẹnikẹ́ni tí yóò bá ọ wí lọ́nà mímúná?+   Pẹ̀lúpẹ̀lù, o sọ pé, ‘Ìtọ́ni mi+ mọ́ gaara, Mo sì mọ́+ ní ti gidi ní ojú rẹ.’   Síbẹ̀, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ì bá jẹ́ sọ̀rọ̀, Kí ó sì ṣí ètè rẹ̀ sí ọ!+   Nígbà náà ni òun ì bá sọ àwọn àṣírí ọgbọ́n fún ọ, Nítorí àwọn nǹkan tí ó jẹ mọ́ ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ pọ̀ lóríṣiríṣi. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ìwọ yóò mọ̀ pé Ọlọ́run yọ̀ǹda kí a gbàgbé lára ìṣìnà rẹ fún ọ.+   Ìwọ ha lè rídìí àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run,+ Tàbí ìwọ ha lè rídìí ààlà ìpẹ̀kun Olódùmarè?   Ó ga ju ọ̀run. Kí ni ìwọ lè ṣàṣeparí? Ó jìn ju Ṣìọ́ọ̀lù.+ Kí ni ìwọ lè mọ̀?   Ìwọ̀n rẹ̀ gùn ju ilẹ̀ ayé, Ó sì fẹ̀ ju òkun. 10  Bí òun bá lọ síwájú, tí ó sì fi ẹnì kan léni lọ́wọ́, Tí ó sì pe kóòtù, nígbà náà, ta ní lè dè é lọ́nà? 11  Nítorí pé àwọn aláìsọ òótọ́ ni òun fúnra rẹ̀ mọ̀ dáadáa.+ Nígbà tí ó bá rí ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, kì yóò ha sì fi ara rẹ̀ hàn ní olùfiyèsílẹ̀? 12  Abunú ènìyàn pàápàá yóò ní ète rere Gbàrà tí a bá bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà ní ènìyàn. 13  Bí ìwọ fúnra rẹ yóò bá múra ọkàn-àyà rẹ sílẹ̀ ní ti gidi, Tí o sì tẹ́ àtẹ́lẹwọ́ rẹ sí i ní ti tòótọ́,+ 14  Bí ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́ bá wà ní ọwọ́ rẹ, mú un kúrò sí ọ̀nà jíjìnréré, Má sì jẹ́ kí àìṣòdodo kankan máa gbé nínú àwọn àgọ́ rẹ. 15  Nítorí, nígbà náà ni ìwọ yóò gbé ojú rẹ sókè láìní àbùkù,+ Dájúdájú, ìwọ yóò sì fìdí múlẹ̀, ìwọ kì yóò sì bẹ̀rù. 16  Nítorí ìwọ—ìwọ yóò gbàgbé ìdààmú; Ìwọ yóò rántí rẹ̀ bí omi tí ó ti kọjá lọ. 17  Gbogbo ọjọ́ ayé rẹ+ yóò sì yọ ju ọjọ́kanrí mímọ́lẹ̀ yòò lọ; Òkùnkùn yóò dà bí òwúrọ̀.+ 18  Ó sì dájú pé ìwọ yóò ní ìgbẹ́kẹ̀lé nítorí pé ìrètí wà; Dájúdájú, ìwọ yóò sì fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wò yíká—ìwọ yóò dùbúlẹ̀ nínú ààbò.+ 19  Ní tòótọ́, ìwọ yóò na ara rẹ tàntàn, láìsí ẹnikẹ́ni tí yóò mú ọ wárìrì. Dájúdájú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn yóò sì mú kí o wà ní ipò-ọkàn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́;+ 20  Àní ojú àwọn ẹni burúkú yóò sì kọṣẹ́;+ Ibi ìsásí yóò sì ṣègbé dájúdájú kúrò lọ́dọ̀ wọn,+ Ìrètí wọn yóò sì jẹ́ ìgbẹ́mìímì ọkàn.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé