Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jóòbù 10:1-22

10  “Dájúdájú, ọkàn mi kórìíra ìgbésí ayé mi tẹ̀gbintẹ̀gbin.+ Èmi yóò tú ìdàníyàn nípa ara mi jáde. Èmi yóò sọ̀rọ̀ nínú ìkorò ọkàn mi!   Èmi yóò sọ fún Ọlọ́run pé, ‘Má pè mí ní ẹni burúkú. Jẹ́ kí n mọ ìdí tí o fi ń bá mi fà á.   Ó ha jẹ́ ohun tí ó dára pé kí o ṣe àìtọ́,+ Pé kí o kọ àmújáde iṣẹ́ àṣekára ọwọ́ rẹ sílẹ̀,+ Pé kí o sì máa tàn yanran ní ti gidi lórí ìmọ̀ràn àwọn ẹni burúkú?   Ìwọ ha ní ojú+ ẹlẹ́ran ara, Tàbí kẹ̀, ṣé bí ẹni kíkú ṣe ń wo nǹkan ni ìwọ ń wo nǹkan ni?+   Àwọn ọjọ́ rẹ ha dà bí àwọn ọjọ́ ẹni kíkú,+ Tàbí àwọn ọdún rẹ ha dà bí àwọn ọjọ́ abarapá ọkùnrin,   Tí ìwọ yóò fi gbìyànjú láti wá ìṣìnà mi rí, Tí ìwọ yóò sì máa wá ẹ̀ṣẹ̀ mi kiri?+   Èyí, láìka mímọ̀ tí ìwọ mọ̀ pé èmi kò jẹ̀bi,+ Kò sì sí ẹni tí ń dáni nídè kúrò ní ọwọ́ rẹ?+   Ọwọ́ rẹ ni ó mọ mí jáde tí wọ́n fi dá mi+ Látòkè délẹ̀ yíká-yíká, síbẹ̀ ìwọ yóò sì gbé mi mì.   Jọ̀wọ́, rántí pé láti inú amọ̀+ ni ìwọ ti mọ mí, Ìwọ yóò sì mú kí n padà sínú ekuru.+ 10  Ìwọ kò ha tẹ̀ síwájú láti dà mí jáde gẹ́gẹ́ bí wàrà Àti gẹ́gẹ́ bí wàràkàṣì láti mú mi dì?+ 11  Ìwọ sì tẹ̀ síwájú láti fi awọ àti ẹran wọ̀ mí, Ó sì fi egungun àti àwọn fọ́nrán iṣan hun mí pọ̀.+ 12  Ìyè àti inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ni ìwọ ti mú ṣiṣẹ́ nípa mi;+ Àbójútó rẹ+ sì ti ṣọ́ ẹ̀mí mi. 13  Nǹkan wọ̀nyí ni ìwọ sì ti fi pa mọ́ nínú ọkàn-àyà rẹ. Èmi mọ̀ dáadáa pé nǹkan wọ̀nyí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ. 14  Bí mo bá ti dẹ́ṣẹ̀, tí ìwọ sì ń ṣọ́ mi,+ Tí ìwọ kò sì kà mí sí aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ nínú ìṣìnà mi;+ 15  Bí mo bá jẹ̀bi ní ti gidi, ó mà ṣe fún mi o!+ Bí mo bá sì jàre ní ti gidi, èmi kò ní gbé orí mi sókè,+ Ẹni tí ó kún fún àbùkù, tí a sì fi ìṣẹ́ni-níṣẹ̀ẹ́ pá lórí.+ 16  Bí ó bá sì hùwà lọ́nà ìrera,+ ìwọ yóò ṣọdẹ mi bí ẹgbọrọ kìnnìún,+ Ìwọ yóò sì tún fi ara rẹ hàn lọ́nà ìyanu nínú ọ̀ràn mi. 17  Ìwọ yóò mú àwọn ẹlẹ́rìí rẹ tuntun wá sí iwájú mi, Ìwọ yóò sì mú ìbínú rẹ sí mi pọ̀ sí i; Ìnira lé ìnira ń bẹ lọ́dọ̀ mi. 18  Nítorí náà, èé ṣe tí ìwọ fi mú mi jáde láti inú ilé ọlẹ̀?+ Èmi ì bá ti gbẹ́mìí mì, àní tí ojú kankan kì bá ti rí mi, 19  Èmi ì bá ti dà bí ẹni tí kò sí rí; À bá ti mú mi làti inú ikùn lọ sí ibi ìsìnkú.’ 20  Àwọn ọjọ́ mi kò ha kéré níye?+ Kí ó dẹ́kun, Kí ó yí ojú rẹ̀ kúrò lára mi, kí n lè túra ká+ díẹ̀ 21  Kí n tó lọ—èmi kì yóò sì padà wá+ Sí ilẹ̀ òkùnkùn àti ibú òjìji,+ 22  Sí ilẹ̀ òkùnkùn ṣíṣú bí ìṣúdùdù, ti ibú òjìji Àti rúgúdù, níbi tí ìmọ́lẹ̀ kì í ti í tàn yanran ju ìṣúdùdù.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé