Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jóòbù 1:1-22

1  Ọkùnrin kan báyìí wà ní ilẹ̀ Úsì+ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jóòbù;+ ọkùnrin yẹn sì jẹ́ aláìlẹ́bi+ àti adúróṣánṣán,+ ó ń bẹ̀rù Ọlọ́run,+ ó sì ń yà kúrò nínú ohun búburú.+  A sì wá bí ọmọkùnrin méje àti ọmọbìnrin mẹ́ta fún un.+  Ohun ọ̀sìn rẹ̀+ sì wá jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin àgùntàn àti ẹgbẹ̀ẹ́dógún ràkúnmí àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àdìpọ̀ méjì-méjì màlúù àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ tí ó pọ̀ gan-an; ọkùnrin yẹn sì wá jẹ́ ẹni tí ó pọ̀ jù lọ nínú gbogbo àwọn Ará Ìlà-Oòrùn.+  Àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì lọ, wọ́n sì se àkànṣe àsè+ ní ilé olúkúlùkù ní ọjọ́ tí ó yí kàn án; wọ́n ránṣẹ́, wọ́n sì ké sí arábìnrin wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta láti bá àwọn jẹ àti láti bá àwọn mu.  A sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí àwọn ọjọ́ àkànṣe àsè náà bá ti lọ ní àlọyíká, Jóòbù a ránṣẹ́, a sì sọ wọ́n di mímọ́;+ a sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, a sì rú àwọn ẹbọ sísun+ ní ìbámu pẹ̀lú iye gbogbo wọn; nítorí, Jóòbù a sọ pé, “bóyá àwọn ọmọ mi ti dẹ́ṣẹ̀, tí wọ́n sì ti bú+ Ọlọ́run nínú ọkàn-àyà wọn.”+ Bí Jóòbù ti ń ṣe nìyí nígbà gbogbo.+  Wàyí o, ó wá di ọjọ́ kan nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́+ wọlé láti mú ìdúró wọn níwájú Jèhófà,+ Sátánì+ pàápàá sì wọlé sáàárín wọn gan-an.+  Nígbà náà ni Jèhófà wí fún Sátánì pé: “Ibo ni o ti wá?” Látàrí ìyẹn, Sátánì dá Jèhófà lóhùn, ó sì wí pé: “Láti ẹnu lílọ káàkiri ní ilẹ̀ ayé+ àti rírìn káàkiri nínú rẹ̀.”+  Jèhófà sì ń bá a lọ láti sọ fún Sátánì pé: “Ìwọ ha ti fi ọkàn-àyà rẹ sí ìránṣẹ́ mi Jóòbù, pé kò sí ẹnì kankan tí ó dà bí rẹ̀ ní ilẹ̀ ayé,+ ọkùnrin aláìlẹ́bi+ àti adúróṣánṣán,+ tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run,+ tí ó sì ń yà kúrò nínú ohun búburú?”+  Látàrí ìyẹn, Sátánì dá Jèhófà lóhùn, ó sì wí pé: “Lásán ha ni Jóòbù ń bẹ̀rù Ọlọ́run bí?+ 10  Ìwọ fúnra rẹ kò ha ti ṣe ọgbà ààbò yí i ká,+ àti yí ilé rẹ̀ ká, àti yí ohun gbogbo tí ó ní ká? Ìwọ ti bù kún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀,+ àní ohun ọ̀sìn rẹ̀ ti tàn káàkiri ilẹ̀. 11  Ṣùgbọ́n, fún ìyípadà, jọ̀wọ́, na ọwọ́ rẹ, kí o sì fọwọ́ kan ohun gbogbo tí ó ní, kí o sì rí i bóyá kì yóò bú ọ ní ojú rẹ gan-an.”+ 12  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Jèhófà sọ fún Sátánì pé: “Wò ó! Ohun gbogbo tí ó ní wà ní ọwọ́ rẹ. Kìkì pé ìwọ kò gbọ́dọ̀ na ọwọ́ rẹ lòdì sí òun fúnra rẹ̀!” Nítorí náà, Sátánì jáde kúrò níwájú Jèhófà.+ 13  Wàyí o, ó wá di ọjọ́ kan nígbà tí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ń jẹun, tí wọ́n sì ń mu wáìnì ní ilé arákùnrin wọn tí í ṣe àkọ́bí.+ 14  Ońṣẹ́+ kan sì tọ Jóòbù wá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Ó ṣẹlẹ̀ pé àwọn màlúù ń túlẹ̀,+ àwọn abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì ń jẹko lẹ́bàá wọn 15  nígbà tí àwọn Sábéà+ gbé sùnmọ̀mí wá, wọ́n sì kó wọn, wọ́n sì fi ojú idà ṣá àwọn ẹmẹ̀wà balẹ̀; èmi nìkan ṣoṣo ni mo sá àsálà láti sọ fún ọ.” 16  Bí tibí ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, tọ̀hún dé, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Iná Ọlọ́run bọ́ láti ọ̀run,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jó láàárín àwọn àgùntàn àti àwọn ẹmẹ̀wà, ó sì jó wọn run; èmi nìkan ṣoṣo ni mo sá àsálà láti sọ fún ọ.”+ 17  Bí ẹni yẹn ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, òmíràn dé, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Àwọn ará Kálídíà+ pín ara wọn sí àwùjọ ọmọ ogun mẹ́ta, wọ́n sì rọ́ gììrì lu àwọn ràkúnmí, wọ́n sì kó wọn, wọ́n sì fi ojú idà ṣá àwọn ẹmẹ̀wà balẹ̀; èmi nìkan ṣoṣo ni ó sá àsálà láti sọ fún ọ.” 18  Bí onítibí ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, síbẹ̀, òmíràn dé, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Àwọn ọmọkùnrin rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ ń jẹun, wọ́n sì ń mu wáìnì+ ní ilé arákùnrin wọn tí í ṣe àkọ́bí. 19  Sì wò ó! ẹ̀fúùfù ńláǹlà+ kan wá láti ẹkùn ilẹ̀ aginjù, ó sì kọlu igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilé náà, tí ó fi wó lu àwọn ọ̀dọ́ náà, wọ́n sì kú. Èmi nìkan ṣoṣo ni ó sá àsálà láti sọ fún ọ.” 20  Jóòbù sì dìde, ó sì gbọn aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ tí kò lápá ya,+ ó sì gé irun+ orí rẹ̀ kúrò, ó sì ṣubú sílẹ̀,+ ó sì tẹrí ba+ 21  ó sì sọ pé: “Ìhòòhò ni mo jáde wá láti inú ikùn ìyá mi,+ Ìhòòhò ni èmi yóò si padà sí ibẹ̀.+ Jèhófà fúnra rẹ̀ ti fi fúnni,+ Jèhófà fúnra rẹ̀ sì ti gbà lọ.+ Kí orúkọ Jèhófà máa bá a lọ láti jẹ́ èyí tí a bù kún fún.”+ 22  Nínú gbogbo èyí, Jóòbù kò dẹ́ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ka ohunkóhun tí kò bẹ́tọ̀ọ́ mu sí Ọlọ́run lọ́rùn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé