Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jóẹ́lì 2:1-32

2  “Ẹ fun ìwo ní Síónì,+ ẹ̀yin ènìyàn, kí ẹ sì kígbe+ ogun ní òkè ńlá+ mímọ́ mi. Kí ṣìbáṣìbo+ bá gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ náà; nítorí ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀,+ nítorí ó sún mọ́lé!  Ọjọ́ òkùnkùn àti ìṣúdùdù+ ni, ọjọ́ àwọsánmà àti ìṣúdùdù tí ó nípọn, gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ ọ̀yẹ̀ tí ó tàn ká orí àwọn òkè ńlá.+ “Àwọn ènìyàn kan wà tí ó pọ̀ níye, tí ó sì jẹ́ alágbára ńlá;+ ọ̀kan bí irú rẹ̀ ni a kò tíì mú kí ó wà láti ìgbà tí ó ti kọjá tipẹ́tipẹ́,+ lẹ́yìn rẹ̀, kì yóò sì tún sí ìkankan títí dé àwọn ọdún ìran dé ìran.  Iná ti jẹ run+ níwájú rẹ̀, ọwọ́ iná sì ń jó run+ lẹ́yìn rẹ̀. Bí ọgbà Édẹ́nì ni ilẹ̀ rí ní iwájú rẹ̀;+ ṣùgbọ́n lẹ́yìn rẹ̀, ó jẹ́ aginjù tí ó di ahoro, kò sì sí nǹkan kan nínú rẹ̀ tí ó yè bọ́.  “Ìrísí rẹ̀ dà bí ìrísí àwọn ẹṣin, àti bí àwọn ẹṣin ogun ni bí wọ́n ti ń sáré.+  Bí ìró àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin lórí àwọn òkè ńlá ni wọ́n ń tọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri,+ bí ìró iná ajófòfò tí ń jẹ àgékù pòròpórò+ run. Ó dà bí àwọn ènìyàn alágbára ńlá, tí ó tẹ́ ìtẹ́gun.+  Nítorí rẹ̀, àwọn ènìyàn yóò jẹ ìrora mímúná.+ Ní ti gbogbo ojú, dájúdájú, wọn yóò ràn koko fún ìdààmú.+  “Wọ́n sáré+ bí àwọn ọkùnrin alágbára. Wọ́n gun ògiri gẹ́gẹ́ bí àwọn ọkùnrin ogun. Wọ́n sì ń lọ, olúkúlùkù ní ọ̀nà tirẹ̀, wọn kò sì yí ipa ọ̀nà wọn padà.+  Wọn kò sì ti ara wọn. Gẹ́gẹ́ bí abarapá ọkùnrin ní ipa ọ̀nà rẹ̀, wọ́n ń lọ ṣáá; ká ní àwọn kan lára wọn ṣubú sáàárín àwọn ohun ọṣẹ́ pàápàá, àwọn yòókù kì yóò yà kúrò ní ipa ọ̀nà.  “Wọ́n rọ́ lọ sínú ìlú ńlá. Wọ́n sáré lórí ògiri. Wọ́n gòkè lọ sórí àwọn ilé. Wọ́n gba àwọn ojú fèrèsé wọlé bí olè. 10  Ilẹ̀ náà ni a ti kó ṣìbáṣìbo bá níwájú rẹ̀, ọ̀run ti mì jìgìjìgì. Àní oòrùn àti òṣùpá ti ṣókùnkùn,+ àwọn ìràwọ̀ ti fawọ́ mímọ́lẹ̀ wọn sẹ́yìn.+ 11  Jèhófà alára yóò sì fọ ohùn+ rẹ̀ níwájú ẹgbẹ́ ológun+ rẹ̀ dájúdájú, nítorí ibùdó rẹ̀ pọ̀ níye gan-an.+ Nítorí alágbára ńlá ni ẹni tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ; nítorí pé ọjọ́ Jèhófà tóbi,+ ó sì jẹ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù gan-an, ta sì ni ó lè dúró lábẹ́ rẹ̀?”+ 12  “Àti nísinsìnyí pẹ̀lú,” ni àsọjáde Jèhófà, “ẹ padà sọ́dọ̀ mi pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà+ yín, àti pẹ̀lú ààwẹ̀+ gbígbà àti pẹ̀lú ẹkún sísun àti pẹ̀lú ìpohùnréré ẹkún.+ 13  Kí ẹ sì fa ọkàn-àyà+ yín ya, kì í sì í ṣe ẹ̀wù+ yín; ẹ sì padà wá sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run yín, nítorí ó jẹ́ olóore ọ̀fẹ́ àti aláàánú,+ ó ń lọ́ra láti bínú,+ ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́,+ dájúdájú, òun yóò sì pèrò dà ní ti ìyọnu àjálù+ náà. 14  Ta ní mọ̀ bóyá òun yóò yí padà, tí yóò sì pèrò dà+ ní ti tòótọ́, tí yóò sì jẹ́ kí ìbùkún+ ṣẹ́ kù lẹ́yìn rẹ̀, ọrẹ ẹbọ ọkà àti ọrẹ ẹbọ ohun mímu fún Jèhófà Ọlọ́run yín? 15  “Ẹ fun ìwo ní Síónì, ẹ̀yin ènìyàn.+ Ẹ sọ àkókò ààwẹ̀+ gbígbà di mímọ́. Ẹ pe àpéjọ+ ọ̀wọ̀. 16  Ẹ kó àwọn ènìyàn náà jọpọ̀. Ẹ sọ ìjọ+ di mímọ́. Ẹ kó àwọn àgbààgbà jọpọ̀. Ẹ kó àwọn ọmọdé àti àwọn tí ń mu ọmú jọpọ̀.+ Kí ọkọ ìyàwó jáde kúrò ní inú yàrá rẹ̀ inú lọ́hùn-ún, àti ìyàwó kúrò ní inú ìyẹ̀wù ìgbà ìgbéyàwó rẹ̀. 17  “Kí àwọn àlùfáà, àwọn òjíṣẹ́ Jèhófà, sunkún láàárín gọ̀bì àti pẹpẹ,+ kí wọ́n sì wí pé, ‘Jèhófà, káàánú àwọn ènìyàn rẹ, má sì sọ ogún rẹ di ẹ̀gàn,+ tí àwọn orílẹ̀-èdè yóò fi máa ṣàkóso lórí wọn. Èé ṣe tí wọn yóò fi wí láàárín àwọn ènìyàn pé: “Ibo ni Ọlọ́run wọ́n wà?”’+ 18  Jèhófà yóò sì kún fún ìtara fún ilẹ̀ rẹ̀,+ yóò sì fi ìyọ́nú hàn sí àwọn ènìyàn rẹ̀.+ 19  Jèhófà yóò sì dáhùn, yóò sì wí fún àwọn ènìyàn rẹ̀ pé, ‘Kíyè sí i, èmi yóò fi ọkà àti wáìnì tuntun àti òróró ránṣẹ́ sí yín, yóò sì tẹ́ yín lọ́rùn dájúdájú;+ èmi kì yóò sì tún ṣe yín ní ẹ̀gàn mọ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.+ 20  Èmi yóò sì mú ará àríwá+ jìnnà réré kúrò lọ́dọ̀ yín, èmi yóò sì fọ́n ọn ká sí ilẹ̀ aláìlómi àti ahoro ní ti tòótọ́, pẹ̀lú ojú rẹ̀ sí òkun ìlà-oòrùn+ àti apá ẹ̀yìn rẹ̀ sí òkun ìwọ̀-oòrùn.+ Àyán tí ń jáde láti ara rẹ̀ yóò sì gòkè dájúdájú, òórùn burúkú tí ń jáde láti ara rẹ̀ yóò sì máa gòkè ṣáá;+ nítorí pé Òun yóò ṣe ohun ńlá ní ti tòótọ́ nínú ohun tí Òun ń ṣe.’ 21  “Má bẹ̀rù, ìwọ ilẹ̀. Kún fún ìdùnnú, kí o sì máa yọ̀; nítorí Jèhófà yóò ṣe ohun ńlá nínú ohun tí Ó ń ṣe ní ti tòótọ́.+ 22  Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ẹranko inú pápá+ gbalasa, nítorí àwọn ilẹ̀ ìjẹko tí ó wà ní aginjù yóò hu ewéko tútù+ dájúdájú. Nítorí igi yóò mú èso+ rẹ̀ jáde. Igi ọ̀pọ̀tọ́ àti àjàrà yóò sì fúnni ní ìmí+ wọn. 23  Àti ẹ̀yin, ọmọ Síónì, ẹ kún fún ìdùnnú, kí ẹ sì máa yọ̀ nínú Jèhófà Ọlọ́run+ yín; nítorí yóò fún yín ní òjò ìgbà ìkórè ní ìwọ̀n+ tí ó tọ́ dájúdájú, yóò sì rọ eji wọwọ lé yín lórí, òjò ìgbà ìkórè àti òjò ìgbà ìrúwé, gẹ́gẹ́ bí ti àkọ́kọ́.+ 24  Àwọn ilẹ̀ ìpakà yóò sì kún fún ọkà tí a fọ̀ mọ́, àwọn ẹkù ìfúntí yóò sì kún àkúnwọ́sílẹ̀ pẹ̀lú wáìnì tuntun àti òróró.+ 25  Dájúdájú, èmi yóò sì san àsanfidípò fún yín nítorí àwọn ọdún tí eéṣú, eéṣú tí kò tíì gúnyẹ̀ẹ́ tí ń rákò, àti aáyán àti kòkòrò wùkúwùkú ti jẹ, ẹgbẹ́ ológun mi ńlá tí mo rán sáàárín yín.+ 26  Dájúdájú, ẹ ó jẹun, ní jíjẹ àjẹyó,+ ẹ ó sì yin orúkọ Jèhófà Ọlọ́run+ yín dájúdájú, ẹni tí ó ti ṣe ohun àgbàyanu+ tí ó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ fún yín; ojú kì yóò sì ti àwọn ènìyàn mi fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ 27  Dájúdájú, ẹ ó sì ní láti mọ̀ pé mo wà láàárín Ísírẹ́lì,+ àti pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín, kò sì sí òmíràn.+ Ojú kì yóò sì ti àwọn ènìyàn mi fún àkókò tí ó lọ kánrin. 28  “Lẹ́yìn ìyẹn, yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, èmi yóò tú ẹ̀mí+ mi jáde sára gbogbo onírúurú ẹran ara,+ àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin+ yín yóò sì máa sọ tẹ́lẹ̀ dájúdájú. Ní ti àwọn àgbà ọkùnrin yín, wọn yóò máa lá àlá. Ní ti àwọn ọ̀dọ́kùnrin yín, wọn yóò máa rí ìran. 29  Èmi yóò sì tú ẹ̀mí mi jáde àní sára àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti sára àwọn ìránṣẹ́bìnrin pàápàá ní ọjọ́ wọnnì.+ 30  “Ṣe ni èmi yóò fúnni ní àwọn àmì àgbàyanu ní ọ̀run+ àti lórí ilẹ̀ ayé, ẹ̀jẹ̀ àti iná àti àwọn ìṣùpọ̀ èéfín+ adúró-bí-ọwọ̀n. 31  A óò yí oòrùn padà di òkùnkùn,+ a ó sì yí òṣùpá padà di ẹ̀jẹ̀,+ kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà tó dé.+ 32  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni yóò yè bọ́;+ nítorí pé àwọn tí ó sá àsálà+ yóò wà ní Òkè Ńlá Síónì àti ní Jerúsálẹ́mù, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti sọ, àti lára àwọn olùlàájá, àwọn tí Jèhófà ń pè.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé