Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jóẹ́lì 1:1-20

1  Ọ̀rọ̀ Jèhófà tí ó tọ+ Jóẹ́lì ọmọkùnrin Pétúélì wá:  “Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin àgbà ọkùnrin, kí ẹ sì fi etí sí i, gbogbo ẹ̀yin olùgbé ilẹ̀+ náà. Èyí ha ti ṣẹlẹ̀ ní àwọn ọjọ́ yín bí, tàbí ní ọjọ́ àwọn baba ńlá yín pàápàá?+  Ẹ ṣèròyìn rẹ̀ fún àwọn ọmọ yín, àti àwọn ọmọ yín fún àwọn ọmọ wọn, àti àwọn ọmọ wọn fún ìran tí ó tẹ̀ lé e.+  Ohun tí kòkòrò wùkúwùkú ṣẹ́ kù, ni eéṣú jẹ;+ ohun tí eéṣú sì ṣẹ́ kù, ni eéṣú tí kò tíì gúnyẹ̀ẹ́, tí ń rákò jẹ; ohun tí eéṣú tí kò tíì gúnyẹ̀ẹ́, tí ń rákò ṣẹ́ kù, ni aáyán jẹ.+  “Ẹ jí, ẹ̀yin ọ̀mùtípara,+ kí ẹ sì sunkún; kí ẹ sì hu,+ gbogbo ẹ̀yin olùmu wáìnì, ní tìtorí wáìnì dídùn,+ nítorí a ti ké e kúrò ní ẹnu yín.+  Nítorí orílẹ̀-èdè kan wà tí ó gòkè wá sí ilẹ̀ mi, alágbára ńlá ni, kò sì níye.+ Eyín kìnnìún ni eyín rẹ̀,+ ó sì ní àwọn egungun páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ kìnnìún.  Ó ti sọ àjàrà mi di ohun ìyàlẹ́nu,+ ó sì ti sọ igi ọ̀pọ̀tọ́ mi di kùkùté.+ Títú ni ó tú u sí borokoto, ó sì gbé e sọnù.+ Àwọn ẹ̀ka igi rẹ̀ ti di funfun.  Pohùn réré ẹkún, gẹ́gẹ́ bí wúńdíá tí ó sán aṣọ àpò ìdọ̀họ+ ti máa ń ṣe lórí olúwa ìgbà èwe rẹ̀.  “Ọrẹ ẹbọ+ ọkà àti ọrẹ ẹbọ+ ohun mímu ni a ti ké kúrò ní ilé Jèhófà; àwọn àlùfáà, àwọn òjíṣẹ́+ Jèhófà, ti ṣọ̀fọ̀.+ 10  A ti fi pápá ṣe ìjẹ,+ ilẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣọ̀fọ̀;+ nítorí a ti fi ọkà ṣe ìjẹ, a ti mú kí wáìnì tuntun gbẹ táútáú,+ òróró ti bù ṣe.+ 11  Ojú ti àwọn àgbẹ̀;+ àwọn olùrẹ́wọ́ àjàrà hu, ní tìtorí àlìkámà àti ní tìtorí ọkà bálì; nítorí pé ìkórè pápá ti ṣègbé.+ 12  Àjàrà alára ti fi gbígbẹ hàn, àní igi ọ̀pọ̀tọ́ ti rẹ̀ dànù. Ní ti igi pómégíránétì, igi ọ̀pẹ àti igi ápù pẹ̀lú, gbogbo igi inú pápá, wọ́n ti gbẹ dànù;+ nítorí pé ayọ̀ ńláǹlà ti fi ìtìjú lọ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ aráyé.+ 13  “Ẹ di ara yín lámùrè, kí ẹ sì lu igẹ̀+ yín, ẹ̀yin àlùfáà. Ẹ hu, ẹ̀yin òjíṣẹ́ pẹpẹ.+ Ẹ wọlé, ẹ wà nínú aṣọ àpò ìdọ̀họ mọ́jú, ẹ̀yin òjíṣẹ́ Ọlọ́run mi; nítorí a ti fawọ́ ọrẹ ẹbọ ọkà àti ọrẹ ẹbọ+ ohun mímu sẹ́yìn+ ní ilé Ọlọ́run yín. 14  Ẹ sọ àkókò ààwẹ̀+ gbígbà di mímọ́. Ẹ pe àpéjọ+ ọ̀wọ̀. Ẹ kó àwọn àgbà ọkùnrin, gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ náà, jọpọ̀, sí ilé Jèhófà Ọlọ́run+ yín, kí ẹ sì kígbe sí Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́.+ 15  “Págà fún ọjọ́ náà;+ nítorí ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé,+ yóò sì dé gẹ́gẹ́ bí ìfiṣèjẹ láti ọ̀dọ̀ Ẹni tí í ṣe Olódùmarè! 16  A kò ha ti ké oúnjẹ kúrò níwájú wa gan-an; a kò ha ti ké ayọ̀ yíyọ̀ àti ìdùnnú kúrò nínú ilé Ọlọ́run wa?+ 17  Ọ̀pọ̀tọ́ gbígbẹ ti kíweje lábẹ́ ṣọ́bìrì wọn. Àwọn ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ ni a ti sọ di ahoro. Àwọn abà ni a ti ya lulẹ̀, nítorí pé ọkà ti gbẹ dànù. 18  Àwọn ẹran agbéléjẹ̀ ti mí ìmí ẹ̀dùn tó! Agbo màlúù ti rìn gbéregbère nínú ìdàrúdàpọ̀ tó! Nítorí pé kò sí pápá ìjẹko fún wọn.+ Pẹ̀lúpẹ̀lù, agbo àgùntàn ni àwọn tí a mú kí ó ru ẹ̀bi. 19  “Ìwọ, Jèhófà, ni èmi yóò ké pè;+ nítorí iná ti jẹ àwọn ilẹ̀ ìjẹko aginjù run, àní ọwọ́ iná sì ti jẹ gbogbo igi inú pápá run.+ 20  Àwọn ẹranko inú pápá pẹ̀lú ń yán hànhàn fún ọ,+ nítorí pé àwọn ipa ojú ọ̀nà omi ti gbẹ táútáú,+ iná sì ti jẹ àwọn ilẹ̀ ìjẹko aginjù run.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé