Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jòhánù 9:1-41

9  Wàyí o, bí ó ti ń kọjá lọ, ó rí ọkùnrin kan tí ó fọ́jú láti ìgbà ìbí.  Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Rábì,+ ta ni ó ṣẹ̀,+ ọkùnrin yìí ni tàbí àwọn òbí rẹ̀,+ tí a fi bí i ní afọ́jú?”  Jésù dáhùn pé: “Kì í ṣe [ọkùnrin] yìí ni ó ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe àwọn òbí rẹ̀, ṣùgbọ́n ó jẹ́ kí a lè fi àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run hàn kedere nínú ọ̀ràn rẹ̀.+  Àwa gbọ́dọ̀ ṣe àwọn iṣẹ́ ẹni tí ó rán mi nígbà tí ó ṣì jẹ́ ọ̀sán;+ òru+ ń bọ̀ nígbà tí ènìyàn kankan kò lè ṣiṣẹ́.  Níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà ní ayé, èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé.”+  Lẹ́yìn tí ó sọ nǹkan wọ̀nyí tán, ó tutọ́ sí ilẹ̀, ó sì fi itọ́ náà ṣe amọ̀, ó sì fi amọ̀ rẹ̀ sí ojú ọkùnrin náà,+  ó sì wí fún un pé: “Lọ wẹ̀+ ní odò adágún Sílóámù”+ (èyí tí a túmọ̀ sí ‘Rán jáde’). Nítorí náà, ó lọ, ó wẹ̀,+ ó sì padà wá, ó ń ríran.+  Nítorí náà, àwọn aládùúgbò àti àwọn tí wọ́n ti máa ń rí i tẹ́lẹ̀ rí pé alágbe ni bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Èyí ni ọkùnrin tí ó ti máa ń jókòó ṣagbe, àbí òun kọ́?”+  Àwọn kan a sọ pé: “Òun nìyí.” Àwọn mìíràn a sọ pé: “Kì í ṣe bẹ́ẹ̀ rárá, ṣùgbọ́n ó jọ ọ́ ni.” Ọkùnrin náà a sọ pé: “Èmi ni.” 10  Nítorí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún un pé: “Báwo wá ni ojú rẹ ṣe là?”+ 11  Ó dáhùn pé: “Ọkùnrin tí a ń pè ní Jésù ni ó ṣe amọ̀, tí ó sì fi rẹ́ ojú mi, tí ó sì wí fún mi pé, ‘Lọ sí Sílóámù,+ kí o sì wẹ̀.’ Nítorí náà, mo lọ, mo wẹ̀, mo sì ríran.” 12  Látàrí èyí, wọ́n wí fún un pé: “Ibo ni ọkùnrin náà wà?” Ó wí pé: “Èmi kò mọ̀.” 13  Wọ́n mú ọkùnrin tí ó ti fọ́jú nígbà kan rí náà fúnra rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ àwọn Farisí. 14  Ó ṣẹlẹ̀ pé Sábáàtì+ ni ọjọ́ tí Jésù ṣe amọ̀ náà, tí ó sì la ojú rẹ̀.+ 15  Nítorí náà, lọ́tẹ̀ yìí, àwọn Farisí pẹ̀lú bẹ̀rẹ̀ sí béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bí ó ṣe ríran.+ Ó wí fún wọn pé: “Ó fi amọ̀ sí ojú mi, mo wẹ̀, mo sì ríran.” 16  Nítorí náà, àwọn kan lára àwọn Farisí bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Èyí kì í ṣe ọkùnrin kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, nítorí pé kò pa Sábáàtì mọ́.”+ Àwọn mìíràn bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Báwo ni ọkùnrin kan tí ó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣe lè ṣe irú àwọn iṣẹ́ àmì+ bẹ́ẹ̀?” Nítorí náà, ìpínyà+ wà láàárín wọn. 17  Nítorí bẹ́ẹ̀, wọ́n tún sọ fún ọkùnrin afọ́jú náà pé: “Kí ni ìwọ wí nípa rẹ̀, níwọ̀n bí ó ti ó la ojú rẹ?” Ọkùnrin náà wí pé: “Wòlíì ni.”+ 18  Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn Júù kò gbà gbọ́ nípa rẹ̀ pé ó ti fọ́jú rí àti pé ó ti ń ríran, títí wọ́n fi pe àwọn òbí ọkùnrin náà tí ó ríran. 19  Wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé: “Ṣé èyí ni ọmọkùnrin yín tí ẹ sọ pé ẹ bí ní afọ́jú? Báwo wá ni ó ṣe wá ń ríran nísinsìnyí?” 20  Nígbà náà, ní ìdáhùn, àwọn òbí rẹ̀ wí pé: “Àwa mọ̀ pé ọmọkùnrin wa nìyí àti pé a bí i ní afọ́jú. 21  Ṣùgbọ́n bí ó ṣe wá ń ríran nísinsìnyí àwa kò mọ̀, tàbí ẹni tí ó là á ní ojú àwa kò mọ̀. Ẹ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Ó ti dàgbà tó. Kí ó sọ̀rọ̀ fún ara rẹ̀.” 22  Àwọn òbí rẹ̀ sọ nǹkan wọ̀nyí nítorí wọ́n ń bẹ̀rù+ àwọn Júù, nítorí àwọn Júù ti fohùn ṣọ̀kan tẹ́lẹ̀ pé, bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́wọ́ rẹ̀ ní Kristi, lílé ni wọn yóò lé e jáde kúrò nínú sínágọ́gù.+ 23  Ìdí nìyí tí àwọn òbí rẹ̀ fi wí pé: “Ó ti dàgbà tó. Ẹ bi í léèrè.” 24  Nítorí náà, ní ìgbà kejì, wọ́n pe ọkùnrin tí ó fọ́jú tẹ́lẹ̀ rí, wọ́n sì wí fún un pé: “Fi ògo fún Ọlọ́run;+ àwa mọ̀ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ọkùnrin yìí.” 25  Ẹ̀wẹ̀, ó dáhùn pé: “Bóyá ẹlẹ́ṣẹ̀ ni, èmi kò mọ̀. Ohun kan ni mo mọ̀, pé, nígbà tí ó jẹ́ pé mo fọ́jú tẹ́lẹ̀ rí, mo ń ríran nísinsìnyí.” 26  Nítorí náà, wọ́n wí fún un pé: “Kí ni ó ṣe sí ọ? Báwo ni ó ṣe la ojú rẹ?” 27  Ó dá wọn lóhùn pé: “Mo ti sọ fún yín ná, síbẹ̀ ẹ kò fetí sílẹ̀. Èé ṣe tí ẹ fi fẹ́ tún un gbọ́? Ẹ kò fẹ́ di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pẹ̀lú, àbí ẹ fẹ́ dà bẹ́ẹ̀?” 28  Látàrí èyí, wọ́n kẹ́gàn rẹ̀, wọ́n sì wí pé: “Ìwọ ni ọmọ ẹ̀yìn ọkùnrin yẹn, ṣùgbọ́n ọmọ ẹ̀yìn Mósè ni àwa. 29  Àwa mọ̀ pé Ọlọ́run ti bá Mósè sọ̀rọ̀;+ ṣùgbọ́n ní ti ọkùnrin yìí, àwa kò mọ ibi tí ó ti wá.”+ 30  Ní ìdáhùn, ọkùnrin náà wí fún wọn pé: “Dájúdájú, èyí jẹ́ ohun ìyanu,+ pé ẹ kò mọ ibi tí ó ti wá, síbẹ̀ ó la ojú mi. 31  Àwa mọ̀ pé Ọlọ́run kì í fetí sí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,+ ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀, ó máa ń fetí sí ẹni yìí.+ 32  Láti ìgbà láéláé, a kò gbọ́ ọ rí pé ẹnikẹ́ni la ojú ẹni tí a bí ní afọ́jú. 33  Bí kì í bá ṣe ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ọkùnrin yìí ti wá,+ kò ní lè ṣe nǹkan kan rárá.” 34  Ní ìdáhùn, wọ́n wí fún un pé: “Gbogbo-ẹ̀ gbògbò-ẹ̀, inú ẹ̀ṣẹ̀ ni a bí ọ sí,+ síbẹ̀ ìwọ ha ń kọ́ wa bí?” Wọ́n sì sọ ọ́ síta!+ 35  Jésù gbọ́ pé wọ́n ti sọ ọ́ síta, nígbà tí ó sì rí i, ó wí pé: “Ìwọ ha ń ní ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ+ ènìyàn bí?” 36  Ọkùnrin náà dáhùn pé: “Ta sì ni òun, sà, kí èmi lè ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀?” 37  Jésù wí fún un pé: “Ìwọ ti rí i àti pé, ní àfikún, ẹni tí ń bá ọ sọ̀rọ̀ ni ẹni yẹn.”+ 38  Nígbà náà ni ó wí pé: “Mo ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, Olúwa.” Ó sì wárí+ fún un. 39  Jésù sì wí pé: “Fún ìdájọ́+ yìí ni mo ṣe wá sí ayé yìí: kí àwọn tí kò ríran lè ríran,+ kí àwọn tí ó ríran sì lè di afọ́jú.”+ 40  Àwọn kan lára àwọn Farisí tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, wọ́n sì wí fún un pé: “Àwa pẹ̀lú kò fọ́jú,+ àbí a fọ́jú?” 41  Jésù wí fún wọn pé: “Ká ní ẹ fọ́jú ni, ẹ kì bá ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, ẹ sọ pé: ‘Àwa ríran.’+ Ẹ̀ṣẹ̀+ yín wà síbẹ̀.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé