Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jòhánù 7:53–8:59

* Àwọn ìwé àfọwọ́kọ náà אBSys fo ẹsẹ 53 dé orí 8, ẹsẹ 11, èyí tí ó kà (pẹ̀lú àwọn àyídà díẹ̀ nínú onírúurú àwọn ọ̀rọ̀ ìwé àti ẹ̀dà ìtúmọ̀ tí a kọ ní èdè Gíríìkì) báyìí: 53  Nítorí náà wọ́n lọ, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀. 8  Ṣùgbọ́n Jésù lọ sí Òkè Ńlá Ólífì.  Ní àfẹ̀mọ́jú, bí ó ti wù kí ó rí, ó tún wá sí tẹ́ńpìlì, gbogbo ènìyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì jókòó, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn.  Wàyí o, àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn Farisí mú obìnrin kan wá tí a ká mọ́ ìdí panṣágà, àti pé, lẹ́yìn mímú un dúró ní àárín wọn,  wọ́n wí fún un pé: “Olùkọ́, obìnrin yìí ni a ká mọ́ ẹnu ṣíṣe panṣágà.  Nínú Òfin, Mósè lànà sílẹ̀ fún wa pé kí a sọ irú àwọn obìnrin bẹ́ẹ̀ ní òkúta. Ní ti gidi, kí ni ìwọ wí?”  Ní tòótọ́, wọ́n ń sọ èyí láti dán an wò, kí wọ́n lè rí ohun kan láti fi fẹ̀sùn kàn án. Ṣùgbọ́n Jésù bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ìka rẹ̀ kọ̀wé sí ilẹ̀.  Nígbà tí wọ́n tẹpẹlẹ mọ́ bíbéèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ó nà ró, ó sì wí fún wọn pé: “Kí ọ̀kan lára yín tí ó jẹ́ aláìlẹ́ṣẹ̀ jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láti sọ ọ́ ní òkúta.”  Àti pé ní bíbẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i, ó ń bá a nìṣó ní kíkọ̀wé sí ilẹ̀.  Ṣùgbọ́n àwọn tí wọ́n gbọ́ èyí bẹ̀rẹ̀ sí jáde lọ, ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn àgbà ọkùnrin, a sì fi òun nìkan sílẹ̀, àti obìnrin tí ó wà ní àárín wọn. 10  Ní nínàró, Jésù wí fún un pé: “Obìnrin yìí, àwọn dà? Ṣé ẹnì kankan kò dá ọ lẹ́bi ni?” 11  Ó wí pé: “Kò sí ẹnì kankan, sà.” Jésù wí pé: “Bẹ́ẹ̀ náà ni èmi kò dá ọ lẹ́bi. Máa bá ọ̀nà rẹ lọ; láti ìsinsìnyí, lọ má ṣe fi ẹ̀ṣẹ̀ dídá ṣe ìwà hù mọ́.” 12  Nítorí náà, Jésù tún bá wọn sọ̀rọ̀, ó wí pé: “Èmi ni ìmọ́lẹ̀+ ayé. Ẹni tí ó bá ń tọ̀ mí lẹ́yìn kì yóò rìn nínú òkùnkùn+ lọ́nàkọnà, ṣùgbọ́n yóò ní ìmọ́lẹ̀ ìyè.” 13  Nítorí bẹ́ẹ̀, àwọn Farisí wí fún un pé: “Ìwọ ń jẹ́rìí nípa ara rẹ; ẹ̀rí rẹ kì í ṣe òótọ́.” 14  Ní ìdáhùn, Jésù wí fún wọn pé: “Àní bí èmi tilẹ̀ ń jẹ́rìí nípa ara mi, òótọ́ ni ẹ̀rí+ mi, nítorí mo mọ ibi tí mo ti wá àti ibi tí mo ń lọ.+ Ṣùgbọ́n ẹ kò mọ ibi tí mo ti wá àti ibi tí mo ń lọ. 15  Ẹ ń ṣèdájọ́ lọ́nà ti ẹran ara;+ èmi kì í ṣèdájọ́ ènìyàn kankan rárá.+ 16  Síbẹ̀, bí mo bá ṣèdájọ́, ìdájọ́ mi kún fún òtítọ́, nítorí èmi kò wà ní èmi nìkan, ṣùgbọ́n Baba tí ó rán mi wà pẹ̀lú mi.+ 17  Pẹ̀lúpẹ̀lù, nínú Òfin ẹ̀yin fúnra yín, a kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Òótọ́ ni ẹ̀rí ènìyàn méjì.’+ 18  Ọ̀kan ni èmi tí ń jẹ́rìí nípa ara mi, Baba tí ó rán mi sì ń jẹ́rìí nípa mi.”+ 19  Nítorí náà, wọ́n ń bá a lọ ní sísọ fún un pé: “Ibo ni Baba rẹ wà?” Jésù dáhùn pé: “Ẹ kò mọ yálà èmi tàbí Baba mi.+ Ká ní ẹ mọ̀ mí ni, ẹ̀ bá mọ Baba mi pẹ̀lú.”+ 20  Àsọjáde wọ̀nyí ni ó sọ ní ibi ìṣúra+ bí ó ti ń kọ́ni ní tẹ́ńpìlì. Ṣùgbọ́n kò sí ẹnì kankan tí ó gbá a mú,+ nítorí pé wákàtí+ rẹ̀ kò tíì dé. 21  Nítorí bẹ́ẹ̀, ó tún wí fún wọn pé: “Èmi ń lọ, ẹ ó sì wá+ mi, síbẹ̀ ẹ ó kú sínú ẹ̀ṣẹ̀ yín.+ Ibi tí èmi ń lọ ni ẹ kò lè wá.” 22  Nítorí náà, àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Kì yóò pa ara rẹ̀, àbí yóò ṣe bẹ́ẹ̀ ni? Nítorí tí ó sọ pé, ‘Ibi tí èmi ń lọ ni ẹ kò lè wá.’”+ 23  Nítorí náà, ó ń bá a lọ ní sísọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin wá láti àwọn ilẹ̀ àkóso ìsàlẹ̀; èmi wá láti àwọn ilẹ̀ àkóso òkè.+ Ẹ̀yin wá láti inú ayé yìí;+ èmi kò wá láti inú ayé yìí.+ 24  Nítorí náà, mo wí fún yin, Ẹ óò kú sínú ẹ̀ṣẹ̀ yín.+ Nítorí bí ẹ kò bá gbà gbọ́ pé èmi ni ẹni náà, ẹ óò kú sínú ẹ̀ṣẹ̀ yín.”+ 25  Nítorí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún un pé: “Ta ni ọ́?” Jésù wí fún wọn pé: “Èé ṣe tí mo tilẹ̀ fi ń bá yín sọ̀rọ̀ rárá? 26  Mo ní ohun púpọ̀ láti sọ nípa yín àti láti ṣe ìdájọ́ lé lórí. Kí a sọ bí ọ̀ràn ti rí, olóòótọ́ ni ẹni tí ó rán mi, àwọn ohun náà tí mo sì gbọ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni mo ń sọ nínú ayé.”+ 27  Wọn kò mòye pé ó ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa Baba. 28  Nítorí náà, Jésù wí pé: “Láti ìgbà tí ẹ bá ti gbé+ Ọmọ ènìyàn+ sókè, nígbà náà ni ẹ ó mọ̀ pé èmi ni ẹni náà,+ àti pé èmi kò ṣe nǹkan kan ní àdáṣe ti ara mi;+ ṣùgbọ́n gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba ti kọ́ mi ni mo ń sọ nǹkan wọ̀nyí.+ 29  Ẹni tí ó rán mi sì wà pẹ̀lú mi; kò pa mí tì ní èmi nìkan, nítorí pé nígbà gbogbo ni mo ń ṣe ohun tí ó wù ú.”+ 30  Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.+ 31  Nítorí náà, Jésù ń bá a lọ ní sísọ fún àwọn Júù tí wọ́n ti gbà á gbọ́ pé: “Bí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi,+ ọmọ ẹ̀yìn mi ni ẹ̀yin jẹ́ ní ti tòótọ́, 32  ẹ ó sì mọ òtítọ́,+ òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.”+ 33  Wọ́n fún un lésì pé: “Ọmọ Ábúráhámù ni wá,+ àwa kò sì ṣe ẹrú fún ẹnikẹ́ni rí.+ Èé ti rí tí o fi wí pé, ‘Ẹ ó di òmìnira’?” 34  Jésù dá wọn lóhùn pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Olúkúlùkù ẹni tí ń dá ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀.+ 35  Síwájú sí i, ẹrú kì í dúró nínú agbo ilé títí láé; ọmọ ni ń dúró títí láé.+ 36  Nítorí náà, bí Ọmọ bá dá yín sílẹ̀ lómìnira, ẹ ó di òmìnira ní ti gidi.+ 37  Mo mọ̀ pé ọmọ Ábúráhámù ni yín; ṣùgbọ́n ẹ ń wá ọ̀nà láti pa mí,+ nítorí pé ọ̀rọ̀ mi kò ní ìtẹ̀síwájú kankan láàárín yín.+ 38  Àwọn ohun tí mo ti rí lọ́dọ̀ Baba+ mi ni mo ń sọ;+ ẹ̀yin, nítorí náà, ń ṣe àwọn ohun tí ẹ ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ baba yín.” 39  Ní ìdáhùn, wọ́n wí fún un pé: “Ábúráhámù ni baba wa.”+ Jésù wí fún wọn pé: “Bí ẹ̀yin bá jẹ́ ọmọ Ábúráhámù,+ ẹ ṣe àwọn iṣẹ́ Ábúráhámù. 40  Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, ẹ ń wá ọ̀nà láti pa mí, ẹni tí ó ti sọ òtítọ́ tí mo gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run fún yín.+ Ábúráhámù kò ṣe èyí.+ 41  Iṣẹ́ baba yín ni ẹ ń ṣe.” Wọ́n wí fún un pé: “A kò bí wa láti inú àgbèrè; Baba+ kan ni àwa ní, Ọlọ́run.” 42  Jésù wí fún wọn pé: “Bí ó bá jẹ́ pé Ọlọ́run ni Baba yín, ẹ̀yin ì bá nífẹ̀ẹ́ mi,+ nítorí pé láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni mo ti jáde wá, mo sì wà níhìn-ín.+ Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò wá rárá ní ìdánúṣe ara mi, ṣùgbọ́n Ẹni yẹn ni ó rán mi jáde.+ 43  Èé ṣe tí ẹ kò mọ ohun tí mo ń sọ? Nítorí pé ẹ kò lè fetí sí ọ̀rọ̀ mi.+ 44  Láti ọ̀dọ̀ Èṣù baba yín ni ẹ ti wá,+ ẹ sì ń fẹ́ láti ṣe àwọn ìfẹ́-ọkàn baba yín.+ Apànìyàn ni ẹni yẹn nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀,+ kò sì dúró ṣinṣin nínú òtítọ́, nítorí pé òtítọ́ kò sí nínú rẹ̀. Nígbà tí ó bá ń pa irọ́, ó ń sọ̀rọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìtẹ̀sí-ọkàn ara rẹ̀, nítorí pé òpùrọ́ ni àti baba irọ́.+ 45  Ní ìdà-kejì, nítorí pé èmi ń sọ òtítọ́, ẹ kò gbà mí gbọ́.+ 46  Ta ni nínú yín tí ó dá mi lẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀?+ Bí mo bá ń sọ òtítọ́, èé ṣe tí ẹ kò gbà mí gbọ́? 47  Ẹni tí ó bá ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ń fetí sí àwọn àsọjáde Ọlọ́run.+ Ìdí nìyí tí ẹ kò fi fetí sílẹ̀, nítorí pé ẹ kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.”+ 48  Ní ìdáhùn, àwọn Júù wí fún un pé: “Àwa kò ha sọ lọ́nà títọ́ pé, Ará Samáríà+ ni ọ́ àti pé o ní ẹ̀mí èṣù?”+ 49  Jésù dáhùn pé: “Èmi kò ní ẹ̀mí èṣù, ṣùgbọ́n mo ń bọlá fún Baba mi,+ ẹ sì ń tàbùkù sí mi. 50  Ṣùgbọ́n èmi kì í wá ògo fún ara mi;+ Ẹnì kan wà tí ó ń wá, tí ó sì ń dájọ́.+ 51  Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Bí ẹnikẹ́ni bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kì yóò rí ikú láé.”+ 52  Àwọn Júù wí fún un pé: “Wàyí o, àwa mọ̀ pé o ní ẹ̀mí èṣù.+ Ábúráhámù kú,+ àti àwọn wòlíì pẹ̀lú;+ ṣùgbọ́n ìwọ wí pé, ‘Bí ẹnikẹ́ni bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kì yóò tọ́ ikú wò+ láé.’ 53  Ìwọ kò tóbi ju+ baba wa Ábúráhámù, ẹni tí ó kú, àbí o tóbi jù ú? Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn wòlíì kú.+ Ta ni o fi ara rẹ pè?” 54  Jésù dáhùn pé: “Bí mo bá ń ṣe ara mi lógo, ògo mi kò jẹ́ nǹkan kan. Baba mi ni ó ń ṣe mí lógo,+ ẹni tí ẹ sọ pé ó jẹ́ Ọlọ́run yín; 55  síbẹ̀síbẹ̀, ẹ kò tíì mọ̀ ọ́n.+ Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n.+ Bí mo bá sì sọ pé n kò mọ̀ ọ́n, èmi yóò dà bí yín, òpùrọ́. Ṣùgbọ́n mo mọ̀ ọ́n, mo sì ń pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́.+ 56  Ábúráhámù baba yín yọ̀ gidigidi nínú ìfojúsọ́nà fún rírí ọjọ́ mi,+ ó sì rí i, ó sì yọ̀.”+ 57  Nítorí náà, àwọn Júù wí fún un pé: “Ìwọ kò tíì tó ẹni àádọ́ta ọdún, síbẹ̀ o ti rí Ábúráhámù?” 58  Jésù wí fún wọn pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Kí Ábúráhámù tó wà, èmi ti wà.”+ 59  Nítorí náà, wọ́n ṣa òkúta láti fi sọ̀kò lù ú;+ ṣùgbọ́n Jésù fara pa mọ́, ó sì jáde kúrò ní tẹ́ńpìlì.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé