Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jòhánù 7:1-53

7  Wàyí o, lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jésù ń bá a lọ ní rírìn kiri ní Gálílì, nítorí pé kò fẹ́ rìn kiri ní Jùdíà, nítorí tí àwọn Júù ń wá ọ̀nà láti pa+ á.  Bí ó ti wù kí ó rí, àjọyọ̀ àwọn Júù, àjọyọ̀ àwọn àgọ́ ìjọsìn,+ sún mọ́lé.  Nítorí náà, àwọn arákùnrin rẹ̀+ wí fún un pé: “Ré kọjá kúrò ní ìhín, kí o sì lọ sí Jùdíà, kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ pẹ̀lú lè rí àwọn iṣẹ́ tí o ń ṣe.  Nítorí kò sí ẹnì kankan tí ń ṣe ohunkóhun ní ìkọ̀kọ̀ nígbà tí òun fúnra rẹ̀ ń wá kí a mọ òun ní gbangba. Bí ìwọ bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, fi ara rẹ hàn kedere fún ayé.”  Ní ti tòótọ́, àwọn arákùnrin rẹ̀+ kì í lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.+  Nítorí náà, Jésù wí fún wọn pé: “Àkókò yíyẹ mi kò tíì tó,+ ṣùgbọ́n àkókò yíyẹ tiyín wà lárọ̀ọ́wọ́tó nígbà gbogbo.  Ayé kò ní ìdí kankan láti kórìíra yín, ṣùgbọ́n ó kórìíra mi, nítorí mo ń jẹ́rìí nípa rẹ̀ pé àwọn iṣẹ́ rẹ̀ burú.+  Ẹ̀yin ẹ máa gòkè lọ sí àjọyọ̀ náà; kò tíì yá mi tí èmi yóò gòkè lọ sí àjọyọ̀ yìí, nítorí àkókò yíyẹ mi+ kò tíì dé ní kíkún.”+  Nítorí náà, lẹ́yìn tí ó sọ nǹkan wọ̀nyí fún wọn, ó dúró ní Gálílì. 10  Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ ti gòkè lọ sí àjọyọ̀ náà, nígbà náà ni òun fúnra rẹ̀ pẹ̀lú gòkè lọ, kì í ṣe ní gbangba, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ní bòókẹ́lẹ́.+ 11  Nítorí náà, àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí wá+ a níbi àjọyọ̀ náà, wọ́n sì ń sọ pé: “Ibo ni ọkùnrin yẹn wà?” 12  Ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sì wà nípa rẹ̀ láàárín àwọn ogunlọ́gọ̀ náà.+ Àwọn kan a sọ pé: “Ènìyàn rere ni.” Àwọn mìíràn a sọ pé: “Òun kì í ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n ó ń ṣi àwọn ogunlọ́gọ̀ lọ́nà ni.” 13  Àmọ́ ṣá o, kò sí ẹnì kan tí ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní gbangba nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù.+ 14  Wàyí o, nígbà tí àjọyọ̀ ku ìdajì kí ó parí, Jésù gòkè lọ sínú tẹ́ńpìlì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ni.+ 15  Nítorí náà, àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí ṣe kàyéfì, pé: “Báwo ni [ọkùnrin] yìí ṣe ní ìmọ̀ ìwé,+ nígbà tí kò kẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn ilé ẹ̀kọ́?”+ 16  Jésù, ẹ̀wẹ̀, dá wọn lóhùn, ó sì wí pé: “Ohun tí mo fi ń kọ́ni kì í ṣe tèmi, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.+ 17  Bí ẹnikẹ́ni bá ní ìfẹ́-ọkàn láti ṣe ìfẹ́ Rẹ̀, yóò mọ̀ nípa ẹ̀kọ́ náà bóyá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run+ ni tàbí mo ń sọ̀rọ̀ láti inú àpilẹ̀ṣe ti ara mi. 18  Ẹni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ láti inú àpilẹ̀ṣe ti ara rẹ̀ ń wá ògo ti ara rẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni tí ń wá ògo+ ẹni tí ó rán an, ẹni yìí jẹ́ olóòótọ́, kò sì sí àìṣòdodo kankan nínú rẹ̀. 19  Mósè fún yín ní Òfin,+ àbí kò fún yín? Ṣùgbọ́n kò sí ọ̀kan nínú yín tí ń ṣègbọràn sí Òfin náà. Èé ṣe tí ẹ fi ń wá ọ̀nà láti pa mí?”+ 20  Ogunlọ́gọ̀ náà dáhùn pé: “Ìwọ ní ẹ̀mí èṣù.+ Ta ni ń wá ọ̀nà láti pa ọ́?” 21  Ní ìdáhùn, Jésù wí fún wọn pé: “Iṣẹ́ kan ni mo ṣe,+ gbogbo yín sì ń ṣe kàyéfì. 22  Fún ìdí yìí ni Mósè ṣe fi ìdádọ̀dọ́+ fún yín—kì í ṣe pé ó wá láti ọ̀dọ̀ Mósè, ṣùgbọ́n pé ó wá láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá+—ẹ sì ń dádọ̀dọ́ ọkùnrin ní sábáàtì. 23  Bí ọkùnrin bá ń gba ìdádọ̀dọ́ ní sábáàtì kí a má bàa rú òfin Mósè, ẹ ha ń bínú sí mi lọ́nà lílenípá nítorí pé mo sọ ọkùnrin kan di alára dídáṣáṣá ní sábáàtì?+ 24  Ẹ dẹ́kun ṣíṣèdájọ́ láti inú ìrísí òde, ṣùgbọ́n ẹ máa fi ìdájọ́ òdodo ṣèdájọ́.”+ 25  Nítorí náà, àwọn kan lára àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Ọkùnrin tí wọ́n ń wá ọ̀nà láti pa nìyí,+ àbí òun kọ́? 26  Síbẹ̀, wò ó! ó ń sọ̀rọ̀ ní gbangba,+ wọn kò sì sọ nǹkan kan sí i. Àwọn olùṣàkóso kò mọ̀ dájúdájú pé èyí ni Kristi náà, àbí wọ́n ti mọ̀?+ 27  Kàkà bẹ́ẹ̀, àwa mọ ibi tí ọkùnrin yìí ti wá;+ síbẹ̀, nígbà tí Kristi bá dé, kò sí ẹnì kankan tí yóò mọ ibi tí ó ti wá.”+ 28  Nítorí náà, Jésù ké jáde bí ó ti ń kọ́ni ní tẹ́ńpìlì, ó sì wí pé: “Ẹ mọ̀ mí, ẹ sì mọ ibi tí mo ti wá.+ Pẹ̀lúpẹ̀lù, èmi kò wá ní ìdánúṣe ara mi,+ ṣùgbọ́n ẹni tí ó rán mi jẹ́ ẹni gidi,+ ẹ kò sì mọ̀ ọ́n.+ 29  Èmi mọ̀ ọ́n,+ nítorí pé mo jẹ́ aṣojú láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, Ẹni yẹn ni ó sì rán mi jáde.”+ 30  Nítorí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wá ọ̀nà láti gbá a mú,+ ṣùgbọ́n kò sí ẹnì kankan tí ó gbé ọwọ́ lé e, nítorí pé wákàtí+ rẹ̀ kò tíì dé. 31  Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀pọ̀ nínú ogunlọ́gọ̀ náà ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀;+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Nígbà tí Kristi bá dé, kì yóò ṣe àwọn iṣẹ́ àmì+ tí ó ju èyí tí [ọkùnrin] yìí ti ṣe, àbí yóò ṣe bẹ́ẹ̀?” 32  Àwọn Farisí gbọ́ tí ogunlọ́gọ̀ náà ń kùn sí nǹkan wọ̀nyí nípa rẹ̀, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí sì rán àwọn onípò àṣẹ lọ láti gbá a mú.+ 33  Nítorí náà, Jésù wí pé: “Èmi ń wà pẹ̀lú yín nígbà díẹ̀ sí i kí n tó lọ sọ́dọ̀ ẹni tí ó rán mi.+ 34  Ẹ óò wá mi,+ ṣùgbọ́n ẹ kì yóò rí mi, ibi tí èmi sì wà ni ẹ kò lè wá.”+ 35  Nítorí náà, àwọn Júù wí láàárín ara wọn pé: “Ibo ni ọkùnrin yìí ń pète-pèrò láti lọ, tí a kò fi ní rí i? Kò pète-pèrò láti lọ sọ́dọ̀ àwọn Júù tí ó fọ́n ká+ sáàárín àwọn Gíríìkì, kí ó sì máa kọ́ àwọn Gíríìkì, àbí òun fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ ni? 36  Kí ni àsọjáde yìí tí ó sọ túmọ̀ sí, ‘Ẹ óò wá mi, ṣùgbọ́n ẹ kì yóò rí mi, ibi tí èmi sì wà ni ẹ kò lè wá’?” 37  Wàyí o, ní ọjọ́ tí ó kẹ́yìn, ọjọ́ ńlá àjọyọ̀ náà,+ Jésù wà ní ìdúró, ó sì ké jáde, pé: “Bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹnikẹ́ni,+ kí ó wá sọ́dọ̀ mi, kí ó sì mu. 38  Ẹni tí ó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú mi,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí, ‘Láti inú rẹ̀ lọ́hùn-ún ni àwọn ìṣàn omi ààyè yóò ti máa ṣàn jáde.’”+ 39  Bí ó ti wù kí ó rí, ó sọ èyí nípa ẹ̀mí tí àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ máa tó gbà; nítorí títí di ìgbà náà kò tíì sí ẹ̀mí kankan,+ nítorí pé a kò tíì ṣe Jésù lógo.+ 40  Nítorí náà, àwọn kan lára ogunlọ́gọ̀ tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Dájúdájú, èyí ni Wòlíì Náà.”+ 41  Àwọn mìíràn ń sọ pé: “Èyí ni Kristi náà.”+ Ṣùgbọ́n àwọn kan ń sọ pé: “Ní ti gidi, Kristi+ kì yóò jáde wá láti Gálílì, àbí yóò ṣe bẹ́ẹ̀?+ 42  Ìwé Mímọ́ kò ha ti sọ pé Kristi ń bọ̀ wá láti inú ọmọ Dáfídì,+ àti láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù+ abúlé tí Dáfídì ti wà tẹ́lẹ̀ rí?”+ 43  Nítorí náà, ìpínyà dìde nípa rẹ̀ láàárín ogunlọ́gọ̀ náà.+ 44  Àwọn kan lára wọn, bí ó ti wù kí ó rí, ń fẹ́ láti gbá a mú, ṣùgbọ́n kò sí ẹnì kankan tí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e. 45  Nítorí náà, àwọn onípò àṣẹ náà padà sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí, àwọn tí a mẹ́nu kàn kẹ́yìn yìí sì wí fún wọn pé: “Èé ṣe tí ẹ kò fi mú un wá?” 46  Àwọn onípò àṣẹ náà fèsì pé: “Ènìyàn mìíràn kò tíì sọ̀rọ̀ báyìí rí.”+ 47  Ẹ̀wẹ̀, àwọn Farisí dáhùn pé: “A kò tíì ṣi ẹ̀yin náà lọ́nà, àbí a ti ṣe bẹ́ẹ̀? 48  Kò sí ọ̀kan nínú àwọn olùṣàkóso tàbí àwọn Farisí tí ó ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, àbí ó wà?+ 49  Ṣùgbọ́n ogunlọ́gọ̀ yìí tí kò mọ Òfin jẹ́ ẹni ègún.”+ 50  Nikodémù, ẹni tí ó ti wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní ìṣáájú, tí ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú wọn, wí fún wọn pé: 51  “Òfin wa kì í ṣèdájọ́ ènìyàn láìjẹ́ pé ó ti kọ́kọ́ gbọ́+ ti ẹnu rẹ̀, kí ó sì wá mọ nǹkan tí ó ń ṣe, àbí ó ń ṣe bẹ́ẹ̀?” 52  Ní ìdáhùn, wọ́n wí fún un pé: “Ìwọ pẹ̀lú kò ti Gálílì wá, àbí ibẹ̀ ni o ti wá? Ṣe ìwádìí káàkiri, kí o sì rí i pé kò sí wòlíì+ kankan tí a óò gbé dìde láti Gálílì wá.”* * Àwọn ìwé àfọwọ́kọ náà אBSys fo ẹsẹ 53 dé orí 8, ẹsẹ 11, èyí tí ó kà (pẹ̀lú àwọn àyídà díẹ̀ nínú onírúurú àwọn ọ̀rọ̀ ìwé àti ẹ̀dà ìtúmọ̀ tí a kọ ní èdè Gíríìkì) báyìí:  53  Nítorí náà wọ́n lọ, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé