Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jòhánù 6:1-71

6  Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jésù lọ sí òdì-kejì òkun Gálílì, tàbí Tìbéríà.+  Ṣùgbọ́n ogunlọ́gọ̀ ńlá ń tẹ̀ lé e ṣáá, nítorí pé wọ́n ń rí àwọn iṣẹ́ àmì tí ó ń ṣe lára àwọn tí ń ṣàmódi.+  Nítorí náà, Jésù gòkè lọ sí òkè ńlá kan,+ ibẹ̀ ni ó sì jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀.  Wàyí o, ìrékọjá,+ àjọyọ̀ àwọn Júù, sún mọ́lé.  Nítorí náà, nígbà tí Jésù gbé ojú rẹ̀ sókè, tí ó sì ṣàkíyèsí pé ogunlọ́gọ̀ ńlá ń bọ̀ lọ́dọ̀ òun, ó wí fún Fílípì pé: “Ibo ni a ó ti ra ìṣù búrẹ́dì fún àwọn wọ̀nyí láti jẹ?”+  Bí ó ti wù kí ó rí, ó ń sọ èyí láti dán an wò, nítorí òun fúnra rẹ̀ mọ ohun tí òun máa tó ṣe.  Fílípì dá a lóhùn pé: “Àwọn ìṣù búrẹ́dì tí iye owó rẹ̀ tó igba owó dínárì kò tó fún wọn, tí olúkúlùkù fi lè rí díẹ̀ gbà.”+  Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, Áńdérù arákùnrin Símónì Pétérù, wí fún un pé:  “Ọmọdékùnrin kan nìyí tí ó ní ìṣù ọkà báálì+ márùn-ún àti ẹja kéékèèké méjì. Ṣùgbọ́n kí ni ìwọ̀nyí jẹ́ láàárín àwọn tí wọ́n pọ̀ tó yìí?”+ 10  Jésù wí pé: “Ẹ jẹ́ kí àwọn ènìyàn náà rọ̀gbọ̀kú gẹ́gẹ́ bí nídìí oúnjẹ.”+ Wàyí o, ọ̀pọ̀ koríko wà níbẹ̀. Nítorí náà, àwọn ènìyàn náà rọ̀gbọ̀kú, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún ní iye.+ 11  Nítorí náà, Jésù mú àwọn ìṣù búrẹ́dì náà àti pé, lẹ́yìn dídúpẹ́, ó pín wọn fún àwọn tí wọ́n rọ̀gbọ̀kú, bákan náà pẹ̀lú, gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ẹja kéékèèké tí wọ́n fẹ́ ti pọ̀ tó.+ 12  Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n yó tán,+ ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ kó èébù tí ó ṣẹ́ kù jọpọ̀, kí ó má bàa sí ohun tí a fi ṣòfò.” 13  Nítorí náà, wọ́n kó wọn jọpọ̀, wọ́n sì fi èébù láti inú ìṣù ọkà báálì márùn-ún náà kún apẹ̀rẹ̀ méjìlá, èyí tí àwọn tí wọ́n ti jẹun fi sílẹ̀.+ 14  Nítorí náà, nígbà tí àwọn ènìyàn rí àwọn iṣẹ́ àmì tí ó ṣe, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Dájúdájú, èyí ni wòlíì+ tí ń bọ̀ wá sí ayé.” 15  Nítorí náà, Jésù, ní mímọ̀ pé wọ́n máa tó wá mú òun láti fi òun jẹ ọba, tún fi ibẹ̀ sílẹ̀+ lọ sí òkè ńlá ní òun nìkan. 16  Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ kalẹ̀ lọ sí òkun,+ 17  àti pé, ní wíwọ ọkọ̀ ojú omi kan, wọ́n mú ọ̀nà wọn pọ̀n ré òkun kọjá sí Kápánáúmù. Tóò, nísinsìnyí ilẹ̀ ti ṣú, Jésù kò sì tíì wá bá wọn síbẹ̀. 18  Pẹ̀lúpẹ̀lù, òkun bẹ̀rẹ̀ sí ru sókè nítorí pé ẹ̀fúùfù líle kan ń fẹ́.+ 19  Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí wọ́n ti tukọ̀ tó nǹkan bí ibùsọ̀ mẹ́ta tàbí mẹ́rin, wọ́n rí tí Jésù ń rìn lórí òkun, tí ó sì ń sún mọ́ ọkọ̀ ojú omi náà; ẹ̀rù sì bà wọ́n.+ 20  Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé: “Èmi ni; ẹ má bẹ̀rù!”+ 21  Nítorí náà, wọ́n múra tán láti gbà á sínú ọkọ̀ ojú omi, tààràtà ni ọkọ̀ ojú omi náà sì dé ilẹ̀ tí wọ́n ń gbìyànjú láti lọ.+ 22  Ní ọjọ́ kejì, ogunlọ́gọ̀ tí ó wà ní ìdúró ní ìhà kejì òkun rí i pé kò sí ọkọ̀ ojú omi kankan níbẹ̀ àyàfi èyí kékeré kan, àti pé Jésù kò bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ọkọ̀ ojú omi ṣùgbọ́n kìkì àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nìkan ni wọ́n ti lọ; 23  ṣùgbọ́n àwọn ọkọ̀ ojú omi láti Tìbéríà dé sí tòsí ibi tí wọ́n ti jẹ búrẹ́dì lẹ́yìn tí Olúwa ti dúpẹ́. 24  Nítorí náà, nígbà tí ogunlọ́gọ̀ náà rí i pé Jésù tàbí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kò sí níbẹ̀, wọ́n wọ àwọn ọkọ̀ ojú omi wọn kéékèèké, wọ́n sì wá sí Kápánáúmù láti wá+ Jésù. 25  Nítorí náà, nígbà tí wọ́n rí i ní òdì-kejì òkun, wọ́n wí fún un pé: “Rábì,+ nígbà wo ni o dé ìhín?” 26  Jésù dá wọn lóhùn, ó sì wí pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹ ń wá mi, kì í ṣe nítorí pé ẹ rí àwọn iṣẹ́ àmì, bí kò ṣe nítorí pé ẹ jẹ láti inú àwọn ìṣù búrẹ́dì náà, ẹ sì yó.+ 27  Ẹ ṣiṣẹ́, kì í ṣe fún oúnjẹ tí ń ṣègbé,+ bí kò ṣe fún oúnjẹ tí ó wà títí ìyè àìnípẹ̀kun,+ èyí tí Ọmọ ènìyàn yóò fún yín; nítorí pé lórí ẹni yìí ni Baba, àní Ọlọ́run, ti fi èdìdì ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀ sí.”+ 28  Nítorí náà, wọ́n wí fún un pé: “Kí ni àwa yóò ṣe láti ṣe àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run?” 29  Ní ìdáhùn, Jésù wí fún wọn pé: “Èyí ni iṣẹ́ Ọlọ́run, pé kí ẹ lo ìgbàgbọ́+ nínú ẹni tí Ẹni yẹn rán jáde.”+ 30  Nítorí náà, wọ́n wí fún un pé: “Kí wá ni ìwọ ń ṣe gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ àmì,+ kí a lè rí i, kí a sì gbà ọ́ gbọ́? Iṣẹ́ wo ni ìwọ ń ṣe? 31  Àwọn baba ńlá wa jẹ mánà+ ní aginjù, gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ó fún wọn ní oúnjẹ tí ó ti ọ̀run wá láti jẹ.’”+ 32  Nítorí bẹ́ẹ̀, Jésù wí fún wọn pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Mósè kò fún yín ní oúnjẹ láti ọ̀run, ṣùgbọ́n Baba mi ni ó fún yín ní oúnjẹ tòótọ́ láti ọ̀run.+ 33  Nítorí pé oúnjẹ Ọlọ́run ni ẹni tí ó sọ kalẹ̀ wá láti ọ̀run tí ó sì fi ìyè fún ayé.” 34  Nítorí náà, wọ́n wí fún un pé: “Olúwa, máa fún wa ní oúnjẹ yìí nígbà gbogbo.”+ 35  Jésù wí fún wọn pé: “Èmi ni oúnjẹ ìyè. Ẹni tí ó bá wá sọ́dọ̀ mi ni ebi kì yóò pa rárá, ẹni tí ó bá sì lo ìgbàgbọ́ nínú mi ni òùngbẹ kì yóò gbẹ láé.+ 36  Ṣùgbọ́n mo ti wí fún yín, Ẹ̀yin tilẹ̀ ti rí mi, síbẹ̀ ẹ kò sì gbà gbọ́.+ 37  Ohun gbogbo tí Baba fi fún mi yóò wá sọ́dọ̀ mi, dájúdájú, ẹni tí ó bá sì wá sọ́dọ̀ mi ni èmi kì yóò lé lọ lọ́nàkọnà;+ 38  nítorí pé èmi sọ kalẹ̀ wá láti ọ̀run,+ kì í ṣe láti ṣe ìfẹ́ mi, bí kò ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi.+ 39  Èyí ni ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi, pé kí èmi má ṣe pàdánù nǹkan kan nínú gbogbo ohun tí ó ti fi fún mi ṣùgbọ́n pé kí èmi jí i dìde+ ní ọjọ́ ìkẹyìn. 40  Nítorí èyí ni ìfẹ́ Baba mi, pé gbogbo ẹni tí ó rí Ọmọ tí ó sì lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ yóò ní ìyè àìnípẹ̀kun,+ dájúdájú, èmi yóò sì jí i dìde ní ọjọ́ ìkẹyìn.”+ 41  Nítorí náà, àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí i nítorí ó wí pé: “Èmi ni oúnjẹ tí ó sọ kalẹ̀ wá láti ọ̀run”;+ 42  wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé:+ “Jésù ọmọkùnrin Jósẹ́fù ha kọ́ yìí,+ ẹni tí àwa mọ baba àti ìyá rẹ̀? Báwo ni ó ṣe jẹ́ tí ó wá ń sọ nísinsìnyí pé, ‘Èmi ti sọ kalẹ̀ wá láti ọ̀run’?” 43  Ní ìdáhùn, Jésù wí fún wọn pé: “Ẹ dẹ́kun kíkùn láàárín ara yín. 44  Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba, tí ó rán mi, fà á;+ dájúdájú, èmi yóò sì jí i dìde ní ọjọ́ ìkẹyìn.+ 45  A kọ̀wé rẹ̀ nínú àwọn Wòlíì pé, ‘Gbogbo wọn yóò sì jẹ́ àwọn tí a kọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.’+ Gbogbo ẹni tí ó bá ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba, tí ó sì ti kẹ́kọ̀ọ́, ń wá sọ́dọ̀ mi.+ 46  Kì í ṣe pé ènìyàn kankan ti rí Baba,+ àyàfi ẹni tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run; ẹni yìí ti rí Baba.+ 47  Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹni tí ó bá gbà gbọ́ ní ìyè àìnípẹ̀kun.+ 48  “Èmi ni oúnjẹ+ ìyè. 49  Àwọn baba ńlá yín jẹ mánà+ ní aginjù, síbẹ̀ wọ́n kú. 50  Èyí ni oúnjẹ tí ó sọ kalẹ̀ wá láti ọ̀run, kí ẹnikẹ́ni lè jẹ nínú rẹ̀, kí ó má sì kú. 51  Èmi ni oúnjẹ ààyè tí ó sọ kalẹ̀ wá láti ọ̀run; bí ẹnikẹ́ni bá jẹ nínú oúnjẹ yìí, yóò wà láàyè títí láé; àti pé, ní ti tòótọ́, oúnjẹ tí èmi yóò fi fúnni ni ẹran ara+ mi nítorí ìyè ayé.”+ 52  Nítorí náà, àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn ṣàríyànjiyàn, pé: “Báwo ni [ọkùnrin] yìí ṣe lè fi ẹran ara rẹ̀ fún wa láti jẹ?” 53  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Jésù wí fún wọn pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Láìjẹ́ pé ẹ jẹ ẹran ara+ Ọmọ ènìyàn, kí ẹ sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀,+ ẹ kò ní ìyè+ kankan nínú ara yín. 54  Ẹni tí ó bá ń fi ẹran ara mi ṣe oúnjẹ jẹ, tí ó sì ń mu ẹ̀jẹ̀ mi ní ìyè àìnípẹ̀kun, èmi yóò sì jí i dìde+ ní ọjọ́ ìkẹyìn; 55  nítorí pé ẹran ara mi ni oúnjẹ tòótọ́, ẹ̀jẹ̀ mi sì ni ohun mímu tòótọ́. 56  Ẹni tí ó bá ń fi ẹran ara mi ṣe oúnjẹ jẹ, tí ó bá sì ń mu ẹ̀jẹ̀ mi dúró ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi, àti èmi ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.+ 57  Gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba alààyè+ ti rán mi jáde, tí mo sì wà láàyè nítorí Baba, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó bá ń fi mí ṣe oúnjẹ jẹ, àní ẹni yẹn yóò wà láàyè nítorí mi.+ 58  Èyí ni oúnjẹ tí ó sọ kalẹ̀ wá láti ọ̀run. Kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí àwọn baba ńlá yín jẹ, síbẹ̀ tí wọ́n sì kú. Ẹni tí ó bá ń fi oúnjẹ yìí ṣe oúnjẹ jẹ, yóò wà láàyè títí láé.”+ 59  Nǹkan wọ̀nyí ni ó sọ bí ó ti ń kọ́ni ní àpéjọ gbogbo ènìyàn ní Kápánáúmù. 60  Nítorí náà, ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, wí pé: “Ọ̀rọ̀ yìí ń múni gbọ̀n rìrì; ta ní lè fetí sí i?”+ 61  Ṣùgbọ́n Jésù, ní mímọ̀ nínú ara rẹ̀ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ń kùn nípa èyí, ó wí fún wọn pé: “Èyí ha mú yín kọsẹ̀+ bí? 62  Bí ẹ bá wá rí Ọmọ ènìyàn ń kọ́, tí ó ń gòkè lọ sí ibi tí ó wà tẹ́lẹ̀ rí?+ 63  Ẹ̀mí ni ó ń fúnni ní ìyè;+ ẹran ara kò wúlò rárá. Àwọn àsọjáde tí mo ti sọ fún yín, ẹ̀mí+ ni wọ́n, ìyè+ sì ni wọ́n. 64  Ṣùgbọ́n àwọn kan wà nínú yín tí kò gbà gbọ́.” Nítorí pé láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, Jésù mọ àwọn tí kò gbà gbọ́ àti ẹni tí yóò dà á.+ 65  Nítorí náà, ó ń bá a lọ pé: “Ìdí nìyí tí mo fi sọ fún yín pé, Kò sí ẹni tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba yọ̀ǹda fún un.”+ 66  Ní tìtorí èyí, ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sídìí àwọn nǹkan àtẹ̀yìnwá,+ wọn kò sì jẹ́ bá a rìn mọ́.+ 67  Nítorí náà, Jésù wí fún àwọn méjìlá náà pé: “Ẹ̀yin kò fẹ́ lọ pẹ̀lú, àbí?” 68  Símónì Pétérù+ dá a lóhùn pé: “Olúwa, ọ̀dọ̀ ta ni àwa yóò lọ?+ Ìwọ ni ó ní àwọn àsọjáde ìyè àìnípẹ̀kun;+ 69  àwa sì ti gbà gbọ́, a sì ti wá mọ̀ pé ìwọ ni Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run.”+ 70  Jésù dá wọn lóhùn pé: “Ẹ̀yin méjìlá ni mo yàn,+ àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Síbẹ̀, ọ̀kan nínú yín jẹ́ afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́.”+ 71  Ó ń sọ̀rọ̀, ní ti tòótọ́, nípa Júdásì ọmọkùnrin Símónì Ísíkáríótù; nítorí pé ẹni yìí ni yóò dà á,+ bí òun tilẹ̀ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn méjìlá náà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé