Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jòhánù 5:1-47

5  Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, àjọyọ̀+ kan tí í ṣe ti àwọn Júù wà, Jésù sì gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù.  Wàyí o, ní Jerúsálẹ́mù, ní ibodè àgùntàn,+ odò adágún kan wà tí a fún ní orúkọ náà Bẹtisátà ní èdè Hébérù, ó ní ìloro márùn-ún.  Inú ìwọ̀nyí ni ògìdìgbó àwọn aláìsàn, afọ́jú, arọ àti àwọn tí ẹ̀yà ara wọ́n ti rọ, dùbúlẹ̀ sí.  ——  Ṣùgbọ́n ọkùnrin kan wà níbẹ̀ tí ó ti wà nínú àìsàn rẹ̀ fún ọdún méjìdínlógójì.  Ní rírí ọkùnrin yìí ní ìdùbúlẹ̀, àti ní mímọ̀ pé ó ti wà lẹ́nu àìsàn fún ìgbà pípẹ́,+ Jésù wí fún un pé: “Ìwọ ha fẹ́ láti di alára dídá bí?”+  Ọkùnrin aláìsàn náà dá a lóhùn pé: “Ọ̀gá, èmi kò ní ènìyàn kan tí yóò gbé mi sínú odò adágún náà nígbà tí omi bá dà rú; ṣùgbọ́n bí èmi bá ti ń bọ̀, ẹlòmíràn yóò ti sọ kalẹ̀ ṣáájú mi.”  Jésù wí fún un pé: “Dìde, gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn.”+  Pẹlu èyíinì, ọkùnrin náà di alára dídá lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sì gbé àkéte rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rìn. Wàyí o, ní ọjọ́ yẹn, ó jẹ́ sábáàtì.+ 10  Nítorí náà, àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún ọkùnrin tí a wòsàn pé: “Sábáàtì nìyí, kò sì bófin mu+ fún ọ láti gbé àkéte náà.” 11  Ṣùgbọ́n ó dá wọn lóhùn pé: “Ẹni náà gan-an tí ó sọ mí di alára dídá wí fún mi pé, ‘Gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn.’” 12  Wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ta ni ẹni tí ó sọ fún ọ pé, ‘Gbé e, kí o sì máa rìn’?” 13  Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí a mú lára dá kò mọ ẹni tí ó jẹ́, nítorí pé Jésù ti yí sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, nítorí ogunlọ́gọ̀ wà níbẹ̀. 14  Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jésù rí i nínú tẹ́ńpìlì, ó sì wí fún un pé: “Wò ó, ìwọ ti di alára dídá. Má ṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́, kí ohun tí ó burú jù má bàa ṣẹlẹ̀ sí ọ.” 15  Ọkùnrin náà lọ, ó sì sọ fún àwọn Júù pé Jésù ni ó sọ òun di alára dídá. 16  Nípa bẹ́ẹ̀, ní tìtorí èyí, àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí ṣe inúnibíni+ sí Jésù, nítorí pé ó ń ṣe nǹkan wọ̀nyí lákòókò Sábáàtì. 17  Ṣùgbọ́n ó dá wọn lóhùn pé: “Baba mi ti ń bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́ títí di ìsinsìnyí, èmi náà sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́.”+ 18  Ní tìtorí èyí, ní tòótọ́, àwọn Júù túbọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí wá ọ̀nà láti pa á,+ nítorí pé kì í ṣe pé ó ń ba Sábáàtì jẹ́ nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún ń pe Ọlọ́run ní Baba+ tòun, ní mímú ara rẹ̀ bá Ọlọ́run dọ́gba.+ 19  Nítorí náà, ní ìdáhùn, Jésù ń bá a lọ láti sọ fún wọn pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ọmọ kò lè ṣe ẹyọ ohun kan ní àdáṣe ti ara rẹ̀, bí kò ṣe kìkì ohun tí ó rí tí Baba ń ṣe.+ Nítorí ohun yòówù tí Ẹni yẹn ń ṣe, nǹkan wọ̀nyí ni Ọmọ ń ṣe pẹ̀lú lọ́nà kan náà. 20  Nítorí pé Baba ní ìfẹ́ni fún Ọmọ,+ ó sì fi gbogbo ohun tí òun fúnra rẹ̀ ń ṣe hàn án, yóò sì fi àwọn iṣẹ́ tí wọ́n tóbi ju ìwọ̀nyí hàn án, kí ẹnu lè yà yín.+ 21  Nítorí gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba ti ń gbé àwọn òkú dìde, tí ó sì ń sọ wọ́n di ààyè,+ bẹ́ẹ̀ náà ni Ọmọ ń sọ àwọn tí ó bá fẹ́ di ààyè.+ 22  Nítorí Baba kì í ṣèdájọ́ ẹnikẹ́ni rárá, ṣùgbọ́n ó ti fi gbogbo ìdájọ́ ṣíṣe lé Ọmọ lọ́wọ́,+ 23  kí gbogbo ènìyàn lè máa bọlá fún Ọmọ+ gan-an gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń bọlá fún Baba. Ẹni tí kò bá bọlá fún Ọmọ kò bọlá fún Baba tí ó rán an.+ 24  Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún yin, Ẹni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí ó sì gba ẹni tí ó rán mi gbọ́, ní ìyè àìnípẹ̀kun,+ kò sì wá sínú ìdájọ́, ṣùgbọ́n ó ti ré kọjá láti inú ikú sínú ìyè.+ 25  “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Wákàtí náà ń bọ̀, nísinsìnyí sì ni, nígbà tí àwọn òkú+ yóò gbọ́ ohùn+ Ọmọ Ọlọ́run, àwọn tí wọ́n sì kọbi ara sí i yóò yè.+ 26  Nítorí gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba ti ní ìyè nínú ara rẹ̀,+ bẹ́ẹ̀ náà ni ó ti yọ̀ǹda fún Ọmọ láti ní ìyè nínú ara rẹ̀.+ 27  Ó sì ti fún un ní ọlá àṣẹ láti ṣe ìdájọ́,+ nítorí pé Ọmọ ènìyàn+ ni òun jẹ́. 28  Kí ẹnu má yà yín sí èyí, nítorí pé wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí+ yóò gbọ́ ohùn rẹ̀, 29  wọn yóò sì jáde wá, àwọn tí wọ́n ṣe ohun rere sí àjíǹde ìyè,+ àwọn tí wọ́n sọ ohun búburú dàṣà sí àjíǹde ìdájọ́.+ 30  Èmi kò lè ṣe ẹyọ ohun kan ní àdáṣe ti ara mi; gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti ń gbọ́ ni mo ń ṣèdájọ́; òdodo sì ni ìdájọ́ tí mo ń ṣe,+ nítorí pé kì í ṣe ìfẹ́ ara mi ni mo ń wá, bí kò ṣe ìfẹ́+ ẹni tí ó rán mi. 31  “Bí èmi nìkan ṣoṣo bá jẹ́rìí+ nípa ara mi, ẹ̀rí mi kì í ṣe òótọ́.+ 32  Ẹlòmíràn wà tí ń jẹ́rìí nípa mi, mo sì mọ̀ pé òótọ́ ni ẹ̀rí tí ó ń jẹ́+ nípa mi. 33  Ẹ ti rán àwọn ènìyàn lọ bá Jòhánù, ó sì ti jẹ́rìí sí òtítọ́.+ 34  Bí ó ti wù kí ó rí, èmi kò tẹ́wọ́ gba ẹ̀rí láti ọ̀dọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n mo sọ nǹkan wọ̀nyí kí a lè gbà yín là.+ 35  Ọkùnrin yẹn jẹ́ fìtílà tí ń jó, tí ó sì ń tàn, fún àkókò kúkúrú, ẹ sì ń fẹ́ láti yọ̀ gidigidi nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀.+ 36  Ṣùgbọ́n èmi ní ẹ̀rí tí ó tóbi ju ti Jòhánù lọ, nítorí pé àwọn iṣẹ́ náà gan-an tí Baba mi yàn lé mi lọ́wọ́ láti ṣe ní àṣeparí, àwọn iṣẹ́ náà tìkára wọn tí èmi ń ṣe,+ ń jẹ́rìí nípa mi pé Baba ni ó rán mi wá. 37  Pẹ̀lúpẹ̀lù, Baba tí ó rán mi ti fúnra rẹ̀ jẹ́rìí nípa mi.+ Ẹ kò tíì gbọ́ ohùn rẹ̀ nígbà kankan rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò tíì rí ìrísí rẹ̀;+ 38  ẹ kò sì ní ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti dúró nínú yín, nítorí pé ẹni tí ó rán wá ni ẹ kò gbà gbọ́. 39  “Ẹ ń wá inú àwọn Ìwé Mímọ́+ kiri, nítorí ẹ rò pé nípasẹ̀ wọn ẹ óò ní ìyè àìnípẹ̀kun; ìwọ̀nyí gan-an sì ni ó ń jẹ́rìí nípa mi.+ 40  Síbẹ̀síbẹ̀, ẹ kò fẹ́ wá sọ́dọ̀ mi kí ẹ lè ní ìyè.+ 41  Èmi kì í tẹ́wọ́ gba ògo láti ọ̀dọ̀ ènìyàn,+ 42  ṣùgbọ́n èmi mọ̀ dunjú pé ẹ kò ní ìfẹ́ fún Ọlọ́run nínú yín.+ 43  Mo wá ní orúkọ Baba mi,+ ṣùgbọ́n ẹ kò gbà mí; bí ẹlòmíràn bá dé ní orúkọ ara rẹ̀, ẹ ó gba ẹni yẹn. 44  Báwo ni ẹ ṣe lè gbà gbọ́, nígbà tí ẹ ń tẹ́wọ́ gba ògo+ láti ọ̀dọ̀ ara yín, tí ẹ kì í sì í wá ògo tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kan ṣoṣo náà wá?+ 45  Ẹ má rò pé èmi yóò fẹ̀sùn kàn yín níwájú Baba; ẹnì kan wà tí ń fẹ̀sùn kàn yín, Mósè, nínú ẹni tí ẹ ti fi ìrètí yín sí. 46  Ní ti tòótọ́, bí ẹ bá gba Mósè+ gbọ́ ni, ẹ̀yin ì bá gbà mí gbọ́, nítorí pé ẹni yẹn kọ̀wé nípa mi.+ 47  Ṣùgbọ́n bí ẹ kò bá gba àwọn ìwé ẹni yẹn gbọ́,+ báwo ni ẹ ó ṣe gba àwọn àsọjáde mi gbọ́?”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé