Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jòhánù 4:1-54

4  Wàyí o, nígbà tí Olúwa mọ̀ pé àwọn Farisí ti gbọ́ pé Jésù ń sọ àwọn púpọ̀ di ọmọ ẹ̀yìn, tí ó sì ń batisí+ púpọ̀ sí i ju Jòhánù—  bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ní tòótọ́, Jésù fúnra rẹ̀ kò batisí rárá ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe bẹ́ẹ̀—  ó fi Jùdíà sílẹ̀, ó sì tún lọ sí Gálílì.  Ṣùgbọ́n ó pọn dandan fún un láti gba Samáríà+ kọjá.  Nípa bẹ́ẹ̀, ó dé ìlú ńlá kan ní Samáríà tí a ń pè ní Síkárì nítòsí pápá tí Jékọ́bù fi fún Jósẹ́fù ọmọkùnrin rẹ̀.+  Ní ti tòótọ́, ìsun omi+ Jékọ́bù wà níbẹ̀. Wàyí o, Jésù, tí ó ti rẹ̀ láti inú ìrìn àjò náà, jókòó níbi ìsun omi náà gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti wà. Wákàtí náà jẹ́ nǹkan bí ìkẹfà.  Obìnrin ará Samáríà kan wá fa omi. Jésù wí fún un pé: “Fún mi mu.”  (Nítorí pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ti lọ sínú ìlú ńlá láti ra àwọn èlò oúnjẹ.)  Nítorí náà, obìnrin ará Samáríà náà wí fún un pé: “Èé ti rí tí ìwọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Júù ni ọ́, fi ń béèrè omi mímu lọ́wọ́ mi, nígbà tí mo jẹ́ obìnrin ará Samáríà?” (Nítorí pé àwọn Júù kì í ní ìbálò kankan pẹ̀lú àwọn ará Samáríà.)+ 10  Ní ìdáhùn, Jésù wí fún un pé: “Ká ní o ti mọ ẹ̀bùn+ ọ̀fẹ́ Ọlọ́run ni àti ẹni+ tí ó sọ fún ọ pé, ‘Fún mi mu,’ ìwọ ì bá ti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ì bá sì ti fún ọ ní omi ààyè.”+ 11  Ó wí fún un pé: “Ọ̀gá, ìwọ kò tilẹ̀ ní korobá fún fífa omi, kànga náà sì jìn. Láti orísun wo ni ìwọ ti wá rí omi ààyè yìí? 12  Ìwọ kò tóbi ju+ baba ńlá wa Jékọ́bù, ẹni tí ó fún wa ní kànga náà tí òun fúnra rẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ẹran ilé rẹ̀ mu nínú rẹ̀, àbí?” 13  Ní ìdáhùn Jésù wí fún un pé: “Gbogbo ẹni tí ó bá ń mu láti inú omi yìí, òùngbẹ yóò tún gbẹ ẹ́. 14  Dájúdájú, ẹnì yòówù tí ó bá ń mu láti inú omi tí èmi yóò fi fún un, òùngbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ láé,+ ṣùgbọ́n omi tí èmi yóò fi fún un yóò di ìsun omi+ nínú rẹ̀ tí ń tú yàà sókè láti fi ìyè àìnípẹ̀kun fúnni.”+ 15  Obìnrin náà wí fún un pé: “Ọ̀gá, fún mi ní omi yìí, kí òùngbẹ má bàa gbẹ mí, kí n má sì máa wá sí ibí yìí láti fa omi.” 16  Ó wí fún un pé: “Lọ, pe ọkọ rẹ, kí ẹ sì wá sí ibí yìí.” 17  Ní ìdáhùn, obìnrin náà wí pé: “Èmi kò ní ọkọ.” Jésù wí fún un pé: “Ìwọ wí dáadáa pé, ‘Ọkọ, èmi kò ní.’ 18  Nítorí pé ìwọ ti ní ọkọ márùn-ún rí, ọkùnrin tí o sì ní nísinsìnyí kì í ṣe ọkọ rẹ. Èyí ni ìwọ ti sọ ní òtítọ́.” 19  Obìnrin náà wí fún un pé: “Ọ̀gá, mo róye pé wòlíì ni ọ́.+ 20  Àwọn baba ńlá wa jọ́sìn ní òkè ńlá yìí;+ ṣùgbọ́n ẹ̀yin sọ pé Jerúsálẹ́mù ni ibi tí ó yẹ kí àwọn ènìyàn ti máa jọ́sìn.”+ 21  Jésù wí fún un pé: “Gbà mí gbọ́, obìnrin yìí, Wákàtí náà ń bọ̀ nígbà tí kì í ṣe ní òkè ńlá yìí tàbí ní Jerúsálẹ́mù+ ni ẹ ó ti máa jọ́sìn+ Baba. 22  Ẹ̀yin ń jọ́sìn ohun tí ẹ kò mọ̀;+ àwa ń jọ́sìn ohun tí àwa mọ̀, nítorí pé ìgbàlà pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn Júù.+ 23  Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, wákàtí náà ń bọ̀, nísinsìnyí sì ni, nígbà tí àwọn olùjọsìn tòótọ́ yóò máa jọ́sìn Baba ní ẹ̀mí+ àti òtítọ́,+ nítorí pé, ní tòótọ́, irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Baba ń wá láti máa jọ́sìn òun.+ 24  Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí,+ àwọn tí ń jọ́sìn rẹ̀ sì gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn ní ẹ̀mí àti òtítọ́.”+ 25  Obìnrin náà wí fún un pé: “Mo mọ̀ pé Mèsáyà+ ń bọ̀, ẹni tí a ń pè ní Kristi.+ Nígbàkigbà tí ẹni yẹn bá dé, yóò polongo ohun gbogbo fún wa ní gbangba.” 26  Jésù wí fún un pé: “Èmi tí ń bá ọ sọ̀rọ̀ ni ẹni náà.”+ 27  Wàyí o, lórí kókó yìí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ dé, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe kàyéfì nítorí pé ó ń bá obìnrin sọ̀rọ̀. Àmọ́ ṣá o, kò sí ẹnì kan tí ó sọ pé: “Kí ni o ń wá?” tàbí, “Èé ṣe tí o fi ń bá a sọ̀rọ̀?” 28  Nítorí náà, obìnrin náà fi ìṣà omi rẹ̀ sílẹ̀, ó sì wọ ìlú ńlá lọ, ó sì sọ fún àwọn ènìyàn pé: 29  “Ẹ máa bọ̀ níhìn-ín, ẹ wá wo ọkùnrin kan tí ó sọ gbogbo ohun tí mo ti ṣe fún mi. Àfàìmọ̀ bí kì í bá ṣe èyí ni Kristi náà,+ àbí?” 30  Wọ́n jáde láti ìlú ńlá náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wá sọ́dọ̀ rẹ̀. 31  Láàárín àkókò yìí, àwọn ọmọ ẹ̀yìn ń rọ̀ ọ́, pé: “Rábì,+ jẹun.” 32  Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé: “Mo ní oúnjẹ láti jẹ tí ẹ kò mọ̀ nípa rẹ̀.” 33  Nítorí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì pé: “Ẹnì kankan kò gbé ohunkóhun wá fún un láti jẹ, àbí?” 34  Jésù wí fún wọn pé: “Oúnjẹ+ mi ni fún mi láti ṣe ìfẹ́+ ẹni tí ó rán mi àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀.+ 35  Ẹ kò ha sọ pé ó ṣì ku oṣù mẹ́rin kí ìkórè tó dé? Wò ó! Mo wí fún yín: Ẹ gbé ojú yín sókè, kí ẹ sì wo àwọn pápá, pé wọ́n ti funfun fún kíkórè.+ Nísinsìnyí, 36  akárúgbìn ń gba owó ọ̀yà, ó sì ń kó èso jọ fún ìyè àìnípẹ̀kun,+ kí afúnrúgbìn+ àti akárúgbìn bàa lè yọ̀ pa pọ̀.+ 37  Ní tòótọ́, nínú ọ̀ràn yìí, òótọ́ ni àsọjáde náà pé, Ẹnì kan ni afúnrúgbìn, ẹlòmíràn sì ni akárúgbìn. 38  Mo rán yín lọ láti kárúgbìn ohun tí ẹ kò ṣe òpò kankan lé lórí. Àwọn ẹlòmíràn ti ṣe òpò,+ ẹ sì ti bọ́ sínú àǹfààní òpò wọn.” 39  Wàyí o, ọ̀pọ̀ nínú àwọn ará Samáríà láti ìlú ńlá yẹn ní ìgbàgbọ́+ nínú rẹ̀ ní tìtorí ọ̀rọ̀ obìnrin náà ẹni tí ó sọ ní jíjẹ́rìí pé: “Ó sọ gbogbo ohun tí mo ti ṣe fún mi.”+ 40  Nítorí náà, nígbà tí àwọn ará Samáríà wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀ ẹ́ pé kí ó dúró lọ́dọ̀ wọn; ó sì dúró níbẹ̀ fún ọjọ́ méjì.+ 41  Nítorí náà, púpọ̀ sí i gbà gbọ́ ní tìtorí ohun tí ó sọ,+ 42  wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún obìnrin náà pé: “Kì í tún ṣe ní tìtorí ọ̀rọ̀ rẹ ni àwa fi gbà gbọ́ mọ́; nítorí pé àwa tìkára wa ti gbọ́,+ a sì mọ̀ pé [ọkùnrin] yìí dájúdájú ni olùgbàlà+ ayé.” 43  Lẹ́yìn ọjọ́ méjì náà, ó fi ibẹ̀ sílẹ̀ lọ sí Gálílì.+ 44  Bí ó ti wù kí ó rí, Jésù fúnra rẹ̀ jẹ́rìí pé wòlíì kì í ní ọlá ní ilẹ̀ ìbílẹ̀ tirẹ̀.+ 45  Nítorí náà, nígbà tí ó dé Gálílì, àwọn ará Gálílì gbà á, nítorí pé wọ́n ti rí gbogbo ohun tí ó ṣe ní Jerúsálẹ́mù nígbà àjọyọ̀,+ nítorí pé àwọn pẹ̀lú lọ sí àjọyọ̀ náà.+ 46  Nípa bẹ́ẹ̀, ó tún wá sí Kánà+ ti Gálílì, níbi tí ó ti sọ omi di wáìnì.+ Wàyí o, ẹmẹ̀wà ọba kan wà tí ọmọkùnrin rẹ̀ ń ṣàìsàn ní Kápánáúmù.+ 47  Nígbà tí [ọkùnrin] yìí gbọ́ pé Jésù ti jáde kúrò ní Jùdíà wá sí Gálílì, ó lọ bá a, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀ ẹ́ pé kí ó sọ kalẹ̀ wá, kí ó sì mú ọmọkùnrin òun lára dá, nítorí ó wà ní ọ̀gẹ́gẹ́rẹ́ ikú. 48  Bí ó ti wù kí ó rí, Jésù wí fún un pé: “Láìjẹ́ pé ẹ rí àwọn iṣẹ́ àmì+ àti iṣẹ́ àgbàyanu,+ ẹ kì yóò gbà gbọ́ lọ́nàkọnà.” 49  Ẹmẹ̀wà ọba náà wí fún un pé: “Olúwa, sọ kalẹ̀ wá kí ọmọ mi kékeré tó kú.” 50  Jésù wí fún un pé: “Máa bá ọ̀nà rẹ lọ;+ ọmọkùnrin rẹ yè.”+ Ọkùnrin náà gba ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún un gbọ́, ó sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ. 51  Ṣùgbọ́n nísinsìnyí bí ó ti ń sọ kalẹ̀ lọ ní ọ̀nà rẹ̀, àwọn ẹrú rẹ̀ pàdé rẹ̀ láti sọ pé ọmọdékùnrin rẹ̀ wà láàyè.+ 52  Nítorí náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìwádìí lọ́wọ́ wọn nípa wákàtí tí ara rẹ̀ yá. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, wọ́n wí fún un pé: “Lánàá, ní wákàtí keje ni ibà+ náà fi í sílẹ̀.” 53  Nípa bẹ́ẹ̀, baba náà mọ̀ pé ó jẹ́ ní wákàtí náà gan-an+ tí Jésù sọ fún un pé: “Ọmọkùnrin rẹ yè.” Òun àti gbogbo agbo ilé rẹ̀ sì gbà gbọ́.+ 54  Lẹ́ẹ̀kan sí i, èyí ni iṣẹ́ àmì kejì+ tí Jésù ṣe nígbà tí ó jáde láti Jùdíà wá sí Gálílì.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé