Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jòhánù 3:1-36

3  Wàyí o, ọkùnrin kan wà nínú àwọn Farisí, Nikodémù+ ni orúkọ rẹ̀, olùṣàkóso kan fún àwọn Júù.  Ẹni yìí wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní òru,+ ó sì wí fún un pé: “Rábì,+ àwa mọ̀ pé ìwọ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́,+ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run;+ nítorí kò sí ẹni tí ó lè ṣe iṣẹ́ àmì wọ̀nyí+ tí ìwọ ń ṣe láìjẹ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.”+  Ní ìdáhùn, Jésù wí fún un pé:+ “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, Láìjẹ́ pé a tún ẹnikẹ́ni bí,+ kò lè rí ìjọba Ọlọ́run.”+  Nikodémù wí fún un pé: “Báwo ni a ṣe lè bí ènìyàn nígbà tí ó ti dàgbà? Kò lè wọ inú ilé ọlẹ̀ ìyá rẹ̀ ní ìgbà kejì kí a sì bí i, àbí ó lè ṣe bẹ́ẹ̀?”  Jésù dáhùn pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, Láìjẹ́ pé a bí ẹnikẹ́ni láti inú omi+ àti ẹ̀mí+ kò lè wọ ìjọba Ọlọ́run.  Ohun tí a ti bí láti inú ẹran ara jẹ́ ẹran ara, ohun tí a sì ti bí láti inú ẹ̀mí jẹ́ ẹ̀mí.+  Kí ẹnu má ṣe yà ọ́ nítorí mo sọ fún ọ pé, A gbọ́dọ̀ tún yín bí.+  Ẹ̀fúùfù+ ń fẹ́ síbi tí ó wù ú, ìwọ sì ń gbọ́ ìró rẹ̀, ṣùgbọ́n ìwọ kò mọ ibi tí ó ti wá àti ibi tí ó ń lọ. Bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí a ti bí láti inú ẹ̀mí.”+  Ní ìdáhùn, Nikodémù wí fún un pé: “Báwo ní nǹkan wọ̀nyí ṣe lè ṣẹlẹ̀?” 10  Ní ìdáhùn, Jésù wí fún un pé: “Ìwọ ha jẹ́ olùkọ́ Ísírẹ́lì, síbẹ̀ tí o kò sì mọ nǹkan wọ̀nyí?+ 11  Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, Ohun tí àwa mọ̀ ni a ń sọ, ohun tí a sì ti rí ni a ń jẹ́rìí+ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ kò gba ẹ̀rí tí àwa jẹ́.+ 12  Bí mo bá ti sọ àwọn ohun ti ilẹ̀ ayé fún yín, síbẹ̀ tí ẹ kò sì gbà gbọ́, báwo ni ẹ ó ṣe gbà gbọ́ bí mo bá sọ àwọn ohun ti ọ̀run fún yín?+ 13  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, kò sí ènìyàn kankan tí ó ti gòkè re ọ̀run+ bí kò ṣe ẹni tí ó sọ kalẹ̀ láti ọ̀run,+ Ọmọ ènìyàn.+ 14  Àti pé gan-an gẹ́gẹ́ bí Mósè ti gbé ejò+ sókè ní aginjù, bẹ́ẹ̀ náà ni a gbọ́dọ̀ gbé Ọmọ ènìyàn sókè,+ 15  kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá gbà gbọ́ nínú rẹ̀ lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.+ 16  “Nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́+ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo+ fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́+ nínú rẹ̀ má bàa pa run,+ ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.+ 17  Nítorí Ọlọ́run rán Ọmọ rẹ̀ jáde sí ayé, kì í ṣe kí ó lè ṣèdájọ́+ ayé, bí kò ṣe kí a lè gba ayé là+ nípasẹ̀ rẹ̀. 18  Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ ni a kì yóò dá lẹ́jọ́.+ Ẹni tí kò bá lo ìgbàgbọ́ ni a ti dá lẹ́jọ́ ná, nítorí pé kò lo ìgbàgbọ́ nínú orúkọ Ọmọ bíbí kan ṣoṣo ti Ọlọ́run.+ 19  Wàyí o, èyí ni ìpìlẹ̀ fún ìdájọ́, pé ìmọ́lẹ̀+ ti wá sí ayé+ ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ti nífẹ̀ẹ́ òkùnkùn dípò ìmọ́lẹ̀,+ nítorí pé àwọn iṣẹ́ wọn burú. 20  Nítorí ẹni tí ó bá ń fi ohun búburú ṣe ìwà hù+ kórìíra ìmọ́lẹ̀, kì í sì í wá sínú ìmọ́lẹ̀, kí a má bàa fi ìbáwí tọ́ iṣẹ́ rẹ̀ sọ́nà.+ 21  Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe nǹkan tí ó jẹ́ òótọ́ máa ń wá sínú ìmọ́lẹ̀,+ kí a bàa lè fi àwọn iṣẹ́ rẹ̀ hàn kedere gẹ́gẹ́ bí èyí tí a ti ṣe ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Ọlọ́run.” 22  Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Jùdíà, ó sì lo àkókò díẹ̀ pẹ̀lú wọn níbẹ̀, ó sì ń batisí.+ 23  Ṣùgbọ́n Jòhánù+ pẹ̀lú ń batisí ní Áínónì nítòsí Sálímù, nítorí pé omi púpọ̀ rẹpẹtẹ+ wà níbẹ̀, àwọn ènìyàn sì ń wá ṣáá, a sì ń batisí wọn;+ 24  nítorí pé a kò tíì sọ Jòhánù sẹ́wọ̀n.+ 25  Nítorí náà, awuyewuye kan dìde níhà ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù pẹ̀lú Júù kan lórí ìwẹ̀mọ́gaara.+ 26  Nítorí náà, wọ́n wá sọ́dọ̀ Jòhánù wọ́n sì wí fún un pé: “Rábì, ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ ní òdì-kejì Jọ́dánì, ẹni tí ìwọ ti jẹ́rìí rẹ̀,+ wò ó, ẹni yìí ń batisí, gbogbo ènìyàn sì ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.”+ 27  Ní ìdáhùn, Jòhánù wí pé: “Ènìyàn kan kò lè rí ẹyọ ohun kan gbà láìjẹ́ pé a ti fi í fún un láti ọ̀run wá.+ 28  Ẹ̀yin fúnra yín jẹ́rìí mi pé mo sọ pé, Èmi kọ́ ni Kristi náà,+ ṣùgbọ́n, a ti rán mi jáde ṣáájú ẹni yẹn.+ 29  Ẹni tí ó ni ìyàwó ni ọkọ ìyàwó.+ Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó, nígbà tí ó bá dúró, tí ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ní ìdùnnú ńláǹlà ní tìtorí ohùn ọkọ ìyàwó. Nítorí náà, ìdùnnú tèmi yìí ni a ti sọ di kíkún.+ 30  Ẹni yẹn gbọ́dọ̀ máa bá a lọ ní pípọ̀ sí i, ṣùgbọ́n èmi gbọ́dọ̀ máa bá a lọ ní pípẹ̀dín.” 31  Ẹni tí ó ti òkè wá ga ju gbogbo àwọn yòókù lọ.+ Ẹni tí ó ti ilẹ̀ ayé wá, ilẹ̀ ayé ni ó ti wá, ó sì ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan ti ilẹ̀ ayé.+ Ẹni tí ó ti ọ̀run wá ga ju gbogbo àwọn yòókù lọ.+ 32  Ohun tí ó ti rí, tí ó sì ti gbọ́, nípa èyí ni ó ń jẹ́rìí,+ ṣùgbọ́n kò sí ènìyàn kankan tí ó ń tẹ́wọ́ gba ẹ̀rí rẹ̀.+ 33  Ẹni tí ó bá ti tẹ́wọ́ gba ẹ̀rí rẹ̀ ti fi èdìdì rẹ̀ sí i pé Ọlọ́run jẹ́ olóòótọ́.+ 34  Nítorí ẹni tí Ọlọ́run rán jáde ń sọ àwọn àsọjáde Ọlọ́run,+ nítorí òun kì í fi ẹ̀mí fúnni nípasẹ̀ ìdíwọ̀n.+ 35  Baba nífẹ̀ẹ́+ Ọmọ, ó sì ti fi ohun gbogbo sí ọwọ́ rẹ̀.+ 36  Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́+ nínú Ọmọ ní ìyè àìnípẹ̀kun;+ ẹni tí ó bá ń ṣàìgbọràn sí Ọmọ kì yóò rí ìyè,+ ṣùgbọ́n ìrunú Ọlọ́run wà lórí rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé