Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jòhánù 21:1-25

21  Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jésù tún fi ara rẹ̀ hàn kedere fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní òkun Tìbéríà; ṣùgbọ́n ó ṣe ìfarahàn kedere náà ní ọ̀nà yìí.  Àwọn tí wọ́n jọ wà pa pọ̀ ni Símónì Pétérù àti Tọ́másì, ẹni tí a ń pè ní Ìbejì,+ àti Nàtáníẹ́lì+ láti Kánà ti Gálílì àti àwọn ọmọkùnrin Sébédè+ àti àwọn méjì mìíràn lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀.  Símónì Pétérù wí fún wọn pé: “Mo ń lọ pẹja.” Wọ́n wí fún un pé: “Àwa náà ń bọ̀ pẹ̀lú rẹ.” Wọ́n jáde, wọ́n sì wọ ọkọ̀ ojú omi, ṣùgbọ́n ní òru yẹn, wọn kò mú nǹkan kan.+  Bí ó ti wù kí ó rí, bí ó ti ń di òwúrọ̀ gẹ́lẹ́, Jésù dúró ní etíkun, ṣùgbọ́n ṣá o, àwọn ọmọ ẹ̀yìn kò fi òye mọ̀ pé Jésù ni.+  Nígbà náà ni Jésù wí fún wọn pé: “Ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, ẹ kò ní ohunkóhun láti jẹ, àbí ẹ ní?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ó tì o!”  Ó wí fún wọn pé: “Ẹ ju àwọ̀n sí ìhà ọ̀tún ọkọ̀ ojú omi, ẹ ó sì rí díẹ̀.”+ Nígbà náà ni wọ́n jù ú, ṣùgbọ́n wọn kò lè fà á wọlé mọ́ nítorí ògìdìgbó ẹja.+  Nítorí náà, ọmọ ẹ̀yìn tí Jésù ti máa ń nífẹ̀ẹ́+ wí fún Pétérù+ pé: “Olúwa ni!” Nítorí èyí, Símónì Pétérù, ní gbígbọ́ pé Olúwa ni, ó fi ẹ̀wù àwọ̀sókè rẹ̀ di ara rẹ̀ lámùrè, nítorí pé ó wà ní ìhòòhò, ó sì bẹ́ sínú òkun.  Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù bá ọkọ̀ ojú omi kékeré náà wá, nítorí wọn kò jìnnà sí ilẹ̀, nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún ẹsẹ̀ bàtà péré ni sí ibẹ̀, wọ́n ń wọ́ àwọ̀n tí ó kún fún ẹja.  Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí wọ́n sọ̀ kalẹ̀ láti inú ọkọ̀ sórí ilẹ̀, wọ́n rí iná èédú igi+ tí ó wà nílẹ̀ níbẹ̀ àti ẹja tí ó wà lórí rẹ̀ àti búrẹ́dì. 10  Jésù wí fún wọn pé: “Ẹ mú díẹ̀ wá lára ẹja tí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ pa nísinsìnyí.” 11  Nítorí náà, Símónì Pétérù wọ ọkọ̀ lọ, ó sì fa àwọ̀n tí ó kún fún àwọn ẹja ńlá wá sí ilẹ̀, wọ́n jẹ́ ọgọ́rùn-ún kan àti àádọ́ta-lé-mẹ́ta. Ṣùgbọ́n bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n pọ̀ tó yìí, àwọ̀n náà kò bẹ́. 12  Jésù wí fún wọn pé: “Ẹ wá, ẹ jẹ oúnjẹ àárọ̀ yín.”+ Kò sí ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí ó ní ìgboyà láti ṣe ìwádìí lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ta ni ọ́?” nítorí wọ́n mọ̀ pé Olúwa ni. 13  Jésù wá, ó sì mú búrẹ́dì náà, ó sì fi í fún wọn,+ àti ẹja náà bákan náà. 14  Èyí ni ìgbà kẹta+ nísinsìnyí tí Jésù fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn lẹ́yìn tí a gbé e dìde kúrò nínú òkú. 15  Wàyí o, nígbà tí wọ́n jẹ oúnjẹ àárọ̀ tán, Jésù wí fún Símónì Pétérù pé: “Símónì ọmọkùnrin Jòhánù, ìwọ ha nífẹ̀ẹ́ mi ju ìwọ̀nyí lọ bí?”+ Ó wí fún un pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, ìwọ mọ̀ pé mo ní ìfẹ́ni fún ọ.”+ Ó wí fún un pé: “Máa bọ́ àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn mi.”+ 16  Ó tún wí fún un, ní ìgbà kejì pé: “Símónì ọmọkùnrin Jòhánù, ìwọ ha nífẹ̀ẹ́+ mi bí?” Ó wí fún un pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, ìwọ mọ̀ pé mo ní ìfẹ́ni fún ọ.” Ó wí fún un pé: “Máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn àgùntàn mi kéékèèké.”+ 17  Ó wí fún un ní ìgbà kẹta pé: “Símónì ọmọkùnrin Jòhánù, ìwọ ha ní ìfẹ́ni fún mi bí?” Ẹ̀dùn-ọkàn bá Pétérù ní ti pé ó wí fún un ní ìgbà kẹta pé: “Ìwọ ha ní ìfẹ́ni fún mi bí?” Nítorí náà, ó wí fún un pé: “Olúwa, ìwọ mọ ohun gbogbo;+ ìwọ mọ̀ pé mo ní ìfẹ́ni fún ọ.” Jésù wí fún un pé: “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi kéékèèké.+ 18  Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún ọ pé, Nígbà tí ìwọ jẹ́ ọ̀dọ́, ìwọ a máa di ara rẹ lámùrè, ìwọ a sì máa rìn káàkiri lọ sí ibi tí o fẹ́. Ṣùgbọ́n nígbà tí o bá darúgbó, ìwọ yóò na ọwọ́ rẹ, ọkùnrin mìíràn yóò dì ọ́ lámùrè,+ yóò sì gbé ọ lọ sí ibi tí ìwọ kò fẹ́.”+ 19  Èyí ni ó sọ láti fi tọ́ka sí irú ikú+ tí òun yóò fi yin Ọlọ́run lógo.+ Nítorí náà, nígbà tí ó ti sọ èyí, ó sọ fún un pé: “Máa bá a lọ ní títọ̀ mí lẹ́yìn.”+ 20  Ní yíyíjú padà, Pétérù rí ọmọ ẹ̀yìn tí Jésù ti máa ń nífẹ̀ẹ́+ tí ń tẹ̀ lé wọn, ẹni tí ó tẹ̀ sẹ́yìn lé igẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú nídìí oúnjẹ alẹ́, tí ó sì wí pé: “Olúwa, ta ni ẹni tí yóò dà ọ́?” 21  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, nígbà tí ó tajú kán rí i, Pétérù wí fún Jésù pé: “Olúwa, kí ni ọkùnrin yìí yóò ṣe?” 22  Jésù wí fún un pé: “Bí ó bá jẹ́ ìfẹ́ mi pé kí ó wà títí èmi yóò fi dé,+ kí ni ó kàn ọ́ níbẹ̀? Ìwọ máa bá a lọ ní títọ̀ mí lẹ́yìn.” 23  Nítorí náà, àsọjáde yìí jáde lọ láàárín àwọn ará, pé ọmọ ẹ̀yìn yẹn kì yóò kú. Bí ó ti wù kí ó rí, Jésù kò sọ fún un pé kì yóò kú, ṣùgbọ́n pé: “Bí ó bá jẹ́ ìfẹ́ mi pé kí ó wà+ títí èmi yóò fi dé, kí ni ó kàn ọ́ níbẹ̀?” 24  Èyí ni ọmọ ẹ̀yìn+ tí ó jẹ́rìí nípa nǹkan wọ̀nyí, tí ó sì kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí, àwa sì mọ̀ pé òótọ́ ni ẹ̀rí tí ó jẹ́.+ 25  Ní ti tòótọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan mìíràn wà pẹ̀lú tí Jésù ṣe, tí ó jẹ́ pé, bí a bá ní láti kọ̀wé kúlẹ̀kúlẹ̀ wọn ní kíkún, mo rò pé, ayé tìkára rẹ̀ kò ní lè gba àwọn àkájọ ìwé tí a bá kọ.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé