Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jòhánù 20:1-31

20  Ní ọjọ́ kìíní+ ọ̀sẹ̀, Màríà Magidalénì wá síbi ibojì ìrántí náà ní kùtùkùtù, nígbà tí òkùnkùn ṣì ṣú síbẹ̀, ó sì rí òkúta náà tí a ti gbé kúrò ní ibojì ìrántí náà.+  Nítorí náà, ó sáré, ó sì wá sọ́dọ̀ Símónì Pétérù àti sọ́dọ̀ ọmọ ẹ̀yìn kejì,+ ẹni tí Jésù ní ìfẹ́ni fún, ó sì wí fún wọn pé: “Wọ́n ti gbé Olúwa jáde kúrò ní ibojì ìrántí,+ àwa kò sì mọ ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.”  Nígbà náà ni Pétérù+ àti ọmọ ẹ̀yìn kejì jáde lọ, wọ́n sì gbéra, ó di ibojì ìrántí náà.  Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn méjèèjì jùmọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí sáré; ṣùgbọ́n ọmọ ẹ̀yìn kejì ya Pétérù sílẹ̀ pẹ̀lú eré sísá tí ó pọ̀ jù, òun ni ó sì kọ́kọ́ dé ibojì ìrántí náà.  Àti pé, ní bíbẹ̀rẹ̀ síwájú, ó rí àwọn ọ̀já ìdìkú nílẹ̀,+ síbẹ̀ kò wọlé.  Lẹ́yìn náà ni Símónì Pétérù pẹ̀lú dé tẹ̀ lé e, ó sì wọnú ibojì ìrántí náà. Ó sì rí àwọn ọ̀já ìdìkú náà nílẹ̀,+  pẹ̀lúpẹ̀lù, aṣọ tí ó ti wà ní orí rẹ̀ kò sí nílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀já ìdìkú náà ṣùgbọ́n a ká a jọ sọ́tọ̀ ní ibì kan.  Nítorí náà, ní àkókò yẹn, ọmọ ẹ̀yìn kejì tí ó kọ́kọ́ dé ibojì ìrántí náà pẹ̀lú wọlé, ó sì rí i, ó sì gbà gbọ́.  Nítorí wọn kò tíì fi òye mọ ìwé mímọ́ pé ó gbọ́dọ̀ dìde kúrò nínú òkú.+ 10  Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà padà sí ilé wọn. 11  Bí ó ti wù kí ó rí, Màríà ń bá a nìṣó ní dídúró lóde nítòsí ibojì ìrántí náà, ó ń sunkún. Nígbà náà, bí ó ti ń sunkún, ó bẹ̀rẹ̀ síwájú láti wo inú ibojì ìrántí náà, 12  ó sì rí áńgẹ́lì+ méjì tí ó wọ ẹ̀wù funfun tí wọ́n jókòó, ọ̀kan ní orí àti ọ̀kan ní ẹsẹ̀ níbi tí òkú Jésù ti wà. 13  Wọ́n sì wí fún un pé: “Obìnrin yìí, èé ṣe tí ìwọ fi ń sunkún?” Ó wí fún wọn pé: “Wọ́n ti gbé Olúwa mi lọ, èmi kò sì mọ ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.” 14  Lẹ́yìn sísọ nǹkan wọ̀nyí, ó yíjú padà, ó sì rí Jésù ní ìdúró, ṣùgbọ́n kò fi òye mọ̀ pé Jésù ni.+ 15  Jésù wí fún un pé: “Obìnrin yìí, èé ṣe tí ìwọ fi ń sunkún? Ta ni ìwọ ń wá?”+ Ní lílérò pé olùṣọ́gbà ni, ó wí fún un pé: “Ọ̀gá, bí o bá ti gbé e lọ, sọ ibi tí o tẹ́ ẹ sí fún mi, èmi yóò sì gbé e lọ.” 16  Jésù wí fún un pé: “Màríà!”+ Ní yíyíjúpadà, ó wí fún un, ní èdè Hébérù pé: “Rábónì!”+ (èyí tí ó túmọ̀ sí “Olùkọ́!”) 17  Jésù wí fún un pé: “Dẹ́kun dídìrọ̀ mọ́ mi. Nítorí èmi kò tíì gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba. Ṣùgbọ́n mú ọ̀nà rẹ pọ̀n lọ sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin mi,+ kí o sì wí fún wọn pé, ‘Èmi ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba mi+ àti Baba yín àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run mi+ àti Ọlọ́run yín.’”+ 18  Màríà Magidalénì wá, ó sì mú ìhìn náà wá fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn pé: “Mo ti rí Olúwa!” àti pé ó sọ nǹkan wọ̀nyí fún òun.+ 19  Nítorí náà, nígbà tí àkókò ti lọ ní ọjọ́ yẹn, ní ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀,+ àti pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti àwọn ilẹ̀kùn ibi tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn wà pa, nítorí ìbẹ̀rù+ àwọn Júù, Jésù wá,+ ó dúró ní àárín wọn, ó sì wí fún wọn pé: “Àlàáfíà fún yín o.”+ 20  Lẹ́yìn tí ó sì sọ èyí, ó fi àwọn ọwọ́ rẹ̀ àti ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ hàn wọ́n.+ Nígbà náà ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn yọ̀+ fún rírí Olúwa. 21  Nítorí náà, Jésù tún wí fún wọn pé: “Àlàáfíà fún yín o. Gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba ti rán mi jáde,+ ni èmi pẹ̀lú ń rán yín.”+ 22  Lẹ́yìn tí ó sì sọ èyí, ó fẹ́ atẹ́gùn sí wọn, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ gba ẹ̀mí mímọ́.+ 23  Bí ẹ bá dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ji ènìyàn èyíkéyìí,+ wọ́n wà ní èyí tí a dárí jì wọ́n; bí ẹ bá dá àwọn ti ènìyàn èyíkéyìí dúró, wọ́n wà ní dídádúró síbẹ̀.”+ 24  Ṣùgbọ́n Tọ́másì,+ ọ̀kan lára àwọn méjìlá, tí a ń pè ní Ìbejì, kò sí pẹ̀lú wọn nígbà tí Jésù wá. 25  Nítorí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù a sọ fún un pé: “Àwa ti rí Olúwa!” Ṣùgbọ́n ó sọ fún wọn pé: “Láìjẹ́ pé mo rí àpá àwọn ìṣó ní ọwọ́, rẹ̀ kí n sì ki ìka mi bọ àpá àwọn ìṣó náà, kí n sì ki ọwọ́ mi bọ ẹ̀gbẹ́ rẹ̀,+ èmi kì yóò gbà gbọ́.”+ 26  Tóò, ọjọ́ mẹ́jọ lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tún wà nínú ilé, àti Tọ́másì pẹ̀lú wọn. Jésù wá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ilẹ̀kùn wà ní títì pa, ó sì dúró ní àárín wọn, ó sì wí pé: “Àlàáfíà fún yín o.”+ 27  Lẹ́yìn náà, ó wí fún Tọ́másì pé: “Fi ìka rẹ síhìn-ín, sì wo àwọn ọwọ́ mi, sì mú ọwọ́ rẹ,+ kí o sì kì í bọ ẹ̀gbẹ́ mi, kí o sì dẹ́kun jíjẹ́ aláìgbàgbọ́ ṣùgbọ́n di onígbàgbọ́.” 28  Ní ìdáhùn, Tọ́másì wí fún un pé: “Olúwa mi àti Ọlọ́run mi!”+ 29  Jésù wí fún un pé: “Ṣé nítorí pé ìwọ rí mi ni o fi gbà gbọ́? Aláyọ̀ ni àwọn tí kò rí, síbẹ̀ tí wọ́n gbà gbọ́.”+ 30  Dájúdájú, Jésù ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì mìíràn pẹ̀lú níwájú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, tí a kò kọ sílẹ̀ sínú àkájọ ìwé yìí.+ 31  Ṣùgbọ́n ìwọ̀nyí ni a ti kọ sílẹ̀+ kí ẹ lè gbà gbọ́ pé Jésù ni Kristi Ọmọ Ọlọ́run, àti pé, nítorí gbígbàgbọ́,+ kí ẹ lè ní ìyè nípasẹ̀ orúkọ rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé