Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jòhánù 2:1-25

2  Wàyí o, ní ọjọ́ kẹta, àsè ìgbéyàwó kan ṣẹlẹ̀ ní Kánà+ ti Gálílì, ìyá+ Jésù sì wà níbẹ̀.  Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ni a ké sí síbi àsè ìgbéyàwó náà pẹ̀lú.  Nígbà tí wáìnì kò tó, ìyá+ Jésù wí fún un pé: “Wọn kò ní wáìnì kankan.”  Ṣùgbọ́n Jésù wí fún un pé: “Kí ní pa tèmi tìrẹ pọ̀, obìnrin?+ Wákàtí mi kò tíì dé síbẹ̀.”+  Ìyá rẹ̀ wí fún àwọn tí ń ṣe ìránṣẹ́ pé: “Ohun yòówù tí ó bá sọ fún yín, ẹ ṣe é.”+  Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí, ìṣà omi mẹ́fà tí a fi òkúta ṣe ni ó fìdí kalẹ̀ níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ìlànà àfilélẹ̀ ìwẹ̀mọ́gaara+ àwọn Júù ti béèrè, ọ̀kọ̀ọ̀kan lè gba òṣùwọ̀n ohun olómi méjì tàbí mẹ́ta.  Jésù wí fún wọn pé: “Ẹ fi omi kún àwọn ìṣà omi náà.” Wọ́n sì fi omi kún wọn dé ẹnu.  Ó sì wí fún wọn pé: “Ẹ bu díẹ̀ jáde nísinsìnyí, kí ẹ sì gbé e tọ olùdarí àsè lọ.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé e lọ.  Wàyí o, nígbà tí olùdarí àsè tọ́ omi tí a ti sọ di wáìnì+ wò, ṣùgbọ́n tí kò mọ orísun rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tí ń ṣe ìránṣẹ́ tí ó ti bu omi náà jáde mọ̀, olùdarí àsè náà pe ọkọ ìyàwó, 10  ó sì wí fún un pé: “Olúkúlùkù ènìyàn mìíràn a kọ́kọ́ gbé wáìnì àtàtà jáde,+ nígbà tí àwọn ènìyàn bá sì ti mutíyó tán, yóò sì kan gbàrọgùdù. Ìwọ ti fi wáìnì àtàtà pa mọ́ títí di ìsinsìnyí.” 11  Jésù ṣe èyí ní Kánà ti Gálílì gẹ́gẹ́ bí ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àwọn iṣẹ́ àmì rẹ̀, ó sì mú ògo+ rẹ̀ hàn kedere; àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. 12  Lẹ́yìn èyí, òun àti ìyá àti àwọn arákùnrin+ rẹ̀ àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ kalẹ̀ lọ sí Kápánáúmù,+ ṣùgbọ́n wọn kò dúró níbẹ̀ fún ọjọ́ púpọ̀. 13  Wàyí o, ìrékọjá+ àwọn Júù ti sún mọ́lé, Jésù sì gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù.+ 14  Nínú tẹ́ńpìlì, ó rí àwọn tí ń ta màlúù àti àgùntàn àti àdàbà+ àti àwọn onípàṣípààrọ̀ owó lórí ìjókòó wọn. 15  Nítorí náà, lẹ́yìn fífi àwọn ìjàrá ṣe pàṣán, ó lé gbogbo àwọn tí wọ́n ní àgùntàn àti màlúù jáde kúrò nínú tẹ́ńpìlì, ó sì da ẹyọ owó àwọn olùpààrọ̀ owó sílẹ̀, ó sì sojú àwọn tábìlì wọn dé.+ 16  Ó sì wí fún àwọn tí ń ta àwọn àdàbà náà pé: “Ẹ kó nǹkan wọ̀nyí kúrò níhìn-ín! Ẹ dẹ́kun sísọ ilé+ Baba mi di ilé ọjà títà!”+ 17  Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rántí pé a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: “Ìtara fún ilé rẹ yóò jẹ mí run.”+ 18  Nítorí náà, ní ìdáhùn, àwọn Júù wí fún un pé: “Àmì+ wo ni ìwọ ní láti fi hàn wá, níwọ̀n bí o ti ń ṣe nǹkan wọ̀nyí?” 19  Ní ìdáhùn, Jésù wí fún wọn pé: “Ẹ wó tẹ́ńpìlì yìí lulẹ̀,+ ní ọjọ́ mẹ́ta, ṣe ni èmi yóò sì gbé e dìde.” 20  Nítorí náà, àwọn Júù wí pé: “Ọdún mẹ́rìndínláàádọ́ta ni a fi kọ́ tẹ́ńpìlì yìí, ìwọ yóò ha sì gbé e dìde ní ọjọ́ mẹ́ta?” 21  Ṣùgbọ́n ó ń sọ̀rọ̀ nípa tẹ́ńpìlì+ ara rẹ̀. 22  Àmọ́ ṣá o, nígbà tí a gbé e dìde kúrò nínú òkú, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rántí+ pé ó ti máa ń sọ èyí; wọ́n sì gba Ìwé Mímọ́ gbọ́ àti àsọjáde tí Jésù sọ. 23  Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù nígbà ìrékọjá, nígbà àjọyọ̀ rẹ̀,+ ọ̀pọ̀ ènìyàn ní ìgbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀,+ ní rírí àwọn iṣẹ́ àmì rẹ̀ tí ó ń ṣe.+ 24  Ṣùgbọ́n Jésù tìkára rẹ̀ kò fi ara rẹ̀ sí ìkáwọ́+ wọn, nítorí mímọ̀ tí ó mọ gbogbo wọn 25  àti nítorí pé kò nílò pé kí ẹnikẹ́ni jẹ́rìí nípa ènìyàn, nítorí pé òun tìkára rẹ̀ mọ ohun tí ó wà nínú ènìyàn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé