Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jòhánù 19:1-42

19  Nítorí náà, ní àkókò yẹn, Pílátù mú Jésù, ó sì nà án lọ́rẹ́.+  Àwọn ọmọ ogun sì hun adé ẹ̀gún, wọ́n sì fi dé orí rẹ̀, wọ́n sì fi ẹ̀wù àwọ̀lékè aláwọ̀ àlùkò ṣe é ní ọ̀ṣọ́;+  wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ń sọ pé: “Kú déédéé ìwòyí o, ìwọ Ọba àwọn Júù!” Pẹ̀lúpẹ̀lù, wọn a fún un ní ìgbájú.+  Pílátù sì tún bọ́ sóde, ó sì wí fún wọn pé: “Wò ó! Mo mú un wá sóde fún yín nítorí kí ẹ lè mọ̀ pé èmi kò rí àléébù kankan nínú rẹ̀.”+  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Jésù jáde wá, ó dé adé ẹlẹ́gùn-ún, ó sì wọ ẹ̀wù àwọ̀lékè aláwọ̀ àlùkò. Ó sì wí fún wọn pé: “Wò ó! Ọkùnrin náà!”  Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn onípò àṣẹ rí i, wọ́n kígbe, pé: “Kàn án mọ́gi! Kàn án mọ́gi!”+ Pílátù wí fún wọn pé: “Ẹ̀yin fúnra yín ẹ mú un, kí ẹ sì kàn án mọ́gi, nítorí pé èmi kò rí àléébù èyíkéyìí nínú rẹ̀.”+  Àwọn Júù dá a lóhùn pé: “Àwa ní òfin kan,+ àti pé ní ìbámu pẹ̀lú òfin náà, ó yẹ kí ó kú, nítorí ó fi ara rẹ̀ ṣe ọmọ Ọlọ́run.”+  Nítorí náà, nígbà tí Pílátù gbọ́ àsọjáde yìí, ẹ̀rù túbọ̀ bà á;  ó sì tún wọ ààfin gómìnà, ó sì wí fún Jésù pé: “Ibo ni o ti wá?” Ṣùgbọ́n Jésù kò fún un ní ìdáhùn kankan.+ 10  Nítorí bẹ́ẹ̀, Pílátù wí fún un pé: “Ṣé o kò ní bá mi sọ̀rọ̀ ni?+ Ìwọ kò ha mọ̀ pé mo ní ọlá àṣẹ láti tú ọ sílẹ̀, mo sì ní ọlá àṣẹ láti kàn ọ́ mọ́gi?” 11  Jésù dá a lóhùn pé: “Ìwọ kì bá ní ọlá àṣẹ kankan rárá lòdì sí mi láìjẹ́ pé a ti yọ̀ǹda rẹ̀ fún ọ láti òkè wá.+ Ìdí nìyí tí ọkùnrin tí ó fi mí lé ọ lọ́wọ́ fi ní ẹ̀ṣẹ̀ títóbi jù.” 12  Fún ìdí yìí, Pílátù ń bá a nìṣó ní wíwá ọ̀nà láti tú u sílẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn Júù kígbe, pé: “Bí ìwọ bá tú ọkùnrin yìí sílẹ̀, ìwọ kì í ṣe ọ̀rẹ́ Késárì. Olúkúlùkù ènìyàn tí ó bá ń fi ara rẹ̀ jẹ ọba ń sọ̀rọ̀ lòdì sí Késárì.”+ 13  Nítorí náà, lẹ́yìn gbígbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, Pílátù mú Jésù wá sóde, ó sì jókòó sórí ìjókòó ìdájọ́ ní ibi tí a ń pè ní Ibi À-Fòkúta-Tẹ́, ṣùgbọ́n, ní èdè Hébérù, Gábátà. 14  Wàyí o, ó jẹ́ ìpalẹ̀mọ́+ ìrékọjá; ó jẹ́ nǹkan bí wákàtí kẹfà. Ó sì wí fún àwọn Júù pé: “Wò ó! Ọba yín!” 15  Àmọ́ ṣá o, wọ́n kígbe pé: “Mú un kúrò! Mú un kúrò! Kàn án mọ́gi!” Pílátù wí fún wọn pé: “Ṣé kí n kan ọba yín mọ́gi ni?” Àwọn olórí àlùfáà dáhùn pé: “Àwa kò ní ọba kankan bí kò ṣe Késárì.”+ 16  Nítorí náà, ní àkókò yẹn, ó fi í lé wọn lọ́wọ́ láti kàn án mọ́gi.+ Nígbà náà ni wọ́n gba Jésù sábẹ́ àbójútó wọn. 17  Àti pé, ní ríru òpó igi oró náà fúnra rẹ̀,+ ó jáde lọ+ sí ibi tí àwọn ènìyàn ń pè ní Ibi Agbárí, èyí tí a ń pè ní Gọ́gọ́tà ní èdè Hébérù;+ 18  ibẹ̀ ni wọ́n sì ti kàn án mọ́gi,+ àti ọkùnrin méjì mìíràn pẹ̀lú rẹ̀, ọ̀kan ní ìhà ìhín àti ọ̀kan ní ọ̀hún, ṣùgbọ́n Jésù ní àárín.+ 19  Pílátù kọ ọ̀rọ̀ àkọlé kan pẹ̀lú, ó sì fi sórí òpó igi oró náà. A kọ ọ́ pé: “Jésù Ará Násárétì Ọba Àwọn Júù.”+ 20  Nítorí náà, ọ̀pọ̀ lára àwọn Júù ka ọ̀rọ̀ àkọlé yìí, nítorí pé ibi tí a ti kan Jésù mọ́gi sún mọ́ ìlú ńlá náà;+ a sì kọ ọ́ ní èdè Hébérù, ní èdè Látínì, ní èdè Gíríìkì. 21  Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn olórí àlùfáà àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún Pílátù pé: “Má kọ ọ́ pé ‘Ọba Àwọn Júù,’ ṣùgbọ́n pé ó sọ pé, ‘Èmi ni Ọba Àwọn Júù.’” 22  Pílátù dáhùn pé: “Ohun tí mo ti kọ ni mo ti kọ.” 23  Wàyí o, nígbà tí àwọn ọmọ ogun ti kan Jésù mọ́gi tán, wọ́n mú ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀, wọ́n sì pín in sí apá mẹ́rin, apá kan fún ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan, àti ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ náà kò ní ojú rírán, ó jẹ́ híhun láti òkè jálẹ̀jálẹ̀ gígùn rẹ̀.+ 24  Nítorí náà, wọ́n sọ fún ara wọn pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a ya á, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a pinnu nípa kèké ṣíṣẹ́ lé e, ti ta ni yóò jẹ́.” Èyí jẹ́ nítorí kí a lè mú ìwé mímọ́ ṣẹ pé: “Wọ́n pín ẹ̀wù àwọ̀lékè mi láàárín ara wọn, wọ́n sì ṣẹ́ kèké lé aṣọ ọ̀ṣọ́ mi.”+ Nítorí náà, àwọn ọmọ ogun náà ṣe nǹkan wọ̀nyí ní ti tòótọ́. 25  Bí ó ti wù kí ó rí, lẹ́bàá òpó igi oró Jésù ni ìyá+ rẹ̀ àti arábìnrin ìyá rẹ̀ dúró; Màríà+ aya Kílópà, àti Màríà Magidalénì.+ 26  Nítorí náà, ní rírí ìyá rẹ̀ àti ọmọ ẹ̀yìn tí ó nífẹ̀ẹ́+ tí ó dúró nítòsí, Jésù sọ fún ìyá rẹ̀ pé: “Obìnrin, wò ó! Ọmọkùnrin rẹ!” 27  Lẹ́yìn náà, ó sọ fún ọmọ ẹ̀yìn náà pé: “Wò ó! Ìyá rẹ!” Láti wákàtí yẹn lọ, ọmọ ẹ̀yìn náà sì mú un lọ sí ilé ara rẹ̀. 28  Lẹ́yìn èyí, nígbà tí Jésù mọ̀ pé nísinsìnyí ohun gbogbo ni a ti ṣe parí, kí a lè ṣàṣeparí ìwé mímọ́, ó wí pé: “Òùngbẹ ń gbẹ mí.”+ 29  Ohun èlò kan fìdí kalẹ̀ níbẹ̀ tí ó kún fún wáìnì kíkan. Nítorí náà, wọ́n fi kànrìnkàn tí ó kún fún wáìnì kíkan náà sórí pòròpórò hísópù, wọ́n sì mú un wá sí ẹnu rẹ̀.+ 30  Wàyí o, nígbà tí ó ti gba wáìnì kíkan náà, Jésù wí pé: “A ti ṣe é parí!”+ àti pé, ní títẹ orí rẹ̀ ba, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́.+ 31  Nígbà náà ni àwọn Júù béèrè lọ́wọ́ Pílátù pé kí ó jẹ́ kí a ṣẹ́ ẹsẹ̀ wọn, kí a sì gbé àwọn òkú náà lọ, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ Ìpalẹ̀mọ́,+ kí àwọn òkú náà má bàa wà+ lórí òpó igi oró ní Sábáàtì (nítorí pé ọjọ́ Sábáàtì yẹn jẹ́ ọjọ́ ńlá).+ 32  Nítorí náà, àwọn ọmọ ogun wá, wọ́n sì ṣẹ́ ẹsẹ̀ ọkùnrin àkọ́kọ́ àti ti ọkùnrin kejì tí a ti kàn mọ́gi pẹ̀lú rẹ̀. 33  Ṣùgbọ́n ní dídé ọ̀dọ̀ Jésù, bí wọ́n ti rí i pé ó ti kú nísinsìnyí, wọn kò ṣẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. 34  Síbẹ̀, ọ̀kan lára àwọn ọmọ ogun náà fi ọ̀kọ̀ gún ẹ̀gbẹ́ rẹ̀,+ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹ̀jẹ̀ àti omi sì tú jáde. 35  Ẹni tí ó sì rí i ti jẹ́rìí, òótọ́ sì ni ẹ̀rí rẹ̀, ọkùnrin yẹn sì mọ̀ pé òótọ́ ni àwọn nǹkan tí òun ń sọ, kí ẹ̀yin pẹ̀lú lè gbà gbọ́.+ 36  Ní ti tòótọ́, nǹkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ nítorí kí a lè mú ìwé mímọ́ ṣẹ pé: “A kì yóò fọ́ ìkankan nínú egungun rẹ̀.”+ 37  Àti, pẹ̀lú, ìwé mímọ́ mìíràn wí pé: “Wọn yóò wo Ẹni náà tí wọ́n gún lọ́kọ̀.”+ 38  Wàyí o, lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jósẹ́fù láti Arimatíà, ẹni tí ó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù, ṣùgbọ́n ọ̀kan tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀ nítorí ìbẹ̀rù rẹ̀ fún àwọn Júù,+ béèrè lọ́wọ́ Pílátù kí òun lè gbé òkú Jésù lọ; Pílátù sì gbà á láyè.+ Nítorí náà, ó wá, ó sì gbé òkú rẹ̀ lọ.+ 39  Nikodémù pẹ̀lú, ọkùnrin tí ó wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní òru ní ìgbà àkọ́kọ́, mú àdìpọ̀ òjíá àti àwọn álóé wá, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ìwọ̀n pọ́n-ùn.+ 40  Nítorí náà, wọ́n gbé òkú Jésù, wọ́n sì fi àwọn ọ̀já ìdìkú dì í pẹ̀lú àwọn èròjà atasánsán náà,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn Júù ti ní àṣà mímúra sílẹ̀ fún ìsìnkú. 41  Ó ṣẹlẹ̀ pé, ní ibi tí a ti kàn án mọ́gi, ọgbà kan wà níbẹ̀, àti pé nínú ọgbà náà, ibojì ìrántí+ tuntun kan wà, tí a kò tíì tẹ́ ẹnì kankan sí rí. 42  Nígbà náà, ní tìtorí ìpalẹ̀mọ́+ àwọn Júù, níbẹ̀ ni wọ́n tẹ́ Jésù sí, nítorí ibojì ìrántí náà wà nítòsí.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé