Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jòhánù 18:1-40

18  Lẹ́yìn sísọ nǹkan wọ̀nyí, Jésù jáde lọ pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní sísọdá ojú àgbàrá Kídírónì+ ti ìgbà òtútù sí ibi tí ọgbà kan wà, òun àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì wọ inú rẹ̀.+  Wàyí o, Júdásì, afinihàn rẹ̀, pẹ̀lú mọ ibẹ̀, nítorí ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù ti pàdé pọ̀ níbẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀.+  Nítorí náà, Júdásì mú àwùjọ ọmọ ogun àti àwọn onípò àṣẹ ti àwọn olórí àlùfáà àti ti àwọn Farisí, wọ́n sì wá síbẹ̀ ti àwọn ti ògùṣọ̀ àti fìtílà àti ohun ìjà.+  Nítorí náà, ní mímọ gbogbo ohun tí ń bọ̀ wá sórí rẹ̀,+ Jésù jáde lọ, ó sì wí fún wọn pé: “Ta ni ẹ ń wá?”  Wọ́n dá a lóhùn pé: “Jésù ará Násárétì ni.”+ Ó wí fún wọn pé: “Èmi ni ẹni náà.” Wàyí o, Júdásì, afinihàn+ rẹ̀, pẹ̀lú bá wọn dúró.  Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí ó wí fún wọn pé: “Èmi ni ẹni náà,” wọ́n fà sẹ́yìn,+ wọ́n sì ṣubú lulẹ̀.  Nítorí náà, ó tún béèrè lọ́wọ́ wọn pé: “Ta ni ẹ ń wá?” Wọ́n wí pé: “Jésù ará Násárétì ni.”  Jésù dáhùn pé: “Mo ti sọ fún yín pé èmi ni ẹni náà. Nítorí náà, bí ó bá jẹ́ pé èmi ni ẹ ń wá, ẹ jẹ́ kí àwọn wọ̀nyí máa lọ”;  kí a lè mú ọ̀rọ̀ náà ṣẹ, èyí tí òun sọ pé: “Lára àwọn tí ìwọ ti fi fún mi èmi kò pàdánù ẹyọ kan.”+ 10  Nígbà náà ni Símónì Pétérù, bí ó ti ní idà kan, ó fà á yọ, ó ṣá ẹrú àlùfáà àgbà, ó sì gé etí rẹ̀ ọ̀tún dànù.+ Orúkọ ẹrú náà ni Málíkọ́sì. 11  Bí ó ti wù kí ó rí, Jésù wí fún Pétérù pé: “Fi idà náà sínú àkọ̀ rẹ̀.+ Ife tí Baba ti fi fún mi, èmi kò ha ní láti mu+ ún lọ́nàkọnà bí?” 12  Nígbà náà ni àwùjọ ọmọ ogun náà àti ọ̀gágun àti àwọn onípò àṣẹ Júù gbá Jésù mú, wọ́n sì dè é, 13  wọ́n sì kọ́kọ́ fà á lọ sọ́dọ̀ Ánásì; nítorí pé òun ni baba ìyàwó Káyáfà, ẹni tí í ṣe àlùfáà àgbà ní ọdún yẹn.+ 14  Káyáfà, ní ti tòótọ́, ni ẹni tí ó gba àwọn Júù nímọ̀ràn pé ó jẹ́ fún àǹfààní wọn pé kí ọkùnrin kan kú nítorí àwọn ènìyàn.+ 15  Wàyí o, Símónì Pétérù àti ọmọ ẹ̀yìn mìíràn kan ń tẹ̀ lé Jésù.+ Ọmọ ẹ̀yìn yẹn jẹ́ ẹni mímọ̀ àlùfáà àgbà, ó sì bá Jésù wọ inú àgbàlá àlùfáà àgbà, 16  ṣùgbọ́n Pétérù dúró ní òde níbi ilẹ̀kùn.+ Nítorí náà, ọmọ ẹ̀yìn kejì náà, tí ó jẹ́ ẹni mímọ̀ àlùfáà àgbà, jáde lọ, ó sì bá olùṣọ́nà sọ̀rọ̀, ó sì mú Pétérù wọlé. 17  Nígbà náà ni ìránṣẹ́bìnrin náà, olùṣọ́nà, sọ fún Pétérù pé: “Ìwọ pẹ̀lú kì í ṣe ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn ọkùnrin yìí, àbí?” Ó wí pé: “Èmi kọ́.”+ 18  Wàyí o, àwọn ẹrú àti àwọn onípò àṣẹ dúró yí ká, bí ó ti jẹ́ pé wọ́n ti dá iná èédú igi,+ nítorí pé òtútù mú, wọ́n sì ń yáná. Pétérù pẹ̀lú bá wọn dúró, ó sì ń yáná. 19  Nítorí náà, olórí àlùfáà sì bi Jésù léèrè nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àti nípa ẹ̀kọ́ rẹ̀. 20  Jésù dá a lóhùn pé: “Mo ti bá ayé sọ̀rọ̀ ní gbangba. Nígbà gbogbo ni mo ń kọ́ni nínú sínágọ́gù àti nínú tẹ́ńpìlì,+ níbi tí gbogbo àwọn Júù ń kóra jọpọ̀ sí; èmi kò sì sọ nǹkan kan ní ìkọ̀kọ̀. 21  Èé ṣe tí ìwọ fi ń bi mí léèrè? Bi àwọn tí wọ́n ti gbọ́ ohun tí mo sọ fún wọn. Wò ó! Àwọn wọ̀nyí mọ ohun tí mo sọ.” 22  Lẹ́yìn tí ó sọ nǹkan wọ̀nyí, ọ̀kan lára àwọn onípò àṣẹ tí ó dúró nítòsí fún Jésù ní ìgbájú,+ ó sì wí pé: “Ṣé lọ́nà yẹn ni ìwọ gbà ń dá olórí àlùfáà lóhùn?” 23  Jésù dá a lóhùn pé: “Bí mo bá sọ̀rọ̀ lọ́nà àìtọ́, jẹ́rìí ní ti ohun àìtọ́ náà; ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ lọ́nà títọ́, èé ṣe tí ìwọ fi gbá mi?” 24  Nígbà náà ni Ánásì rán an lọ ní dídè sọ́dọ̀ Káyáfà àlùfáà àgbà.+ 25  Wàyí o, Símónì Pétérù dúró, ó sì ń yáná. Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé: “Ìwọ pẹ̀lú kì í ṣe ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, àbí?” Ó sẹ́, ó sì wí pé: “Èmi kọ́.”+ 26  Ọ̀kan lára àwọn ẹrú àlùfáà àgbà, bí ó ti jẹ́ ìbátan ọkùnrin tí Pétérù gé etí rẹ̀ dànù,+ wí pé: “Mo rí ọ nínú ọgbà pẹ̀lú rẹ̀, àbí èmi kò rí ọ?” 27  Bí ó ti wù kí ó rí, Pétérù tún sẹ́; lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àkùkọ kọ.+ 28  Nígbà náà ni wọ́n mú Jésù lọ láti ọ̀dọ̀ Káyáfà sí ààfin gómìnà.+ Wàyí o, kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ ni. Ṣùgbọ́n àwọn fúnra wọn kò wọ ààfin gómìnà, kí wọ́n má bàa di ẹlẹ́gbin+ ṣùgbọ́n kí wọ́n lè jẹ ìrékọjá. 29  Nítorí náà, Pílátù jáde wá bá wọn, ó sì wí pé: “Ẹ̀sùn wo ni ẹ mú wá lòdì sí ọkùnrin yìí?”+ 30  Ní ìdáhùn, wọ́n wí fún un pé: “Bí [ọkùnrin] yìí kì í bá ṣe olùṣe búburú, a kì bá ti fà á lé ọ lọ́wọ́.” 31  Nítorí bẹ́ẹ̀, Pílátù wí fún wọn pé: “Ẹ̀yin fúnra yín ẹ mú un, kí ẹ sì ṣèdájọ́ rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú òfin yín.”+ Àwọn Júù wí fún un pé: “Kò bófin mu fún wa láti pa ẹnikẹ́ni.”+ 32  Èyí jẹ́, kí a lè mú ọ̀rọ̀ Jésù ṣẹ èyí tí ó sọ láti fi tọ́ka sí irú ikú tí a yàn tẹ́lẹ̀ pé òun yóò kú.+ 33  Nítorí náà, Pílátù tún wọ ààfin gómìnà, ó sì pe Jésù, ó sì wí fún un pé: “Ìwọ ha ni ọba àwọn Júù bí?”+ 34  Jésù dáhùn pé: “Ó ha jẹ́ láti inú àpilẹ̀ṣe ti ara rẹ ni ìwọ ti sọ èyí, tàbí àwọn ẹlòmíràn ni wọ́n sọ fún ọ nípa mi?”+ 35  Pílátù dáhùn pé: “Èmi kì í ṣe Júù, àbí mo jẹ́ bẹ́ẹ̀? Orílẹ̀-èdè ìwọ fúnra rẹ àti àwọn olórí àlùfáà ni wọ́n fà ọ́ lé mi lọ́wọ́.+ Kí ni ìwọ ṣe?” 36  Jésù dáhùn+ pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí.+ Bí ìjọba mi bá jẹ́ apá kan ayé yìí, àwọn ẹmẹ̀wà mi ì bá ti jà+ kí a má bàa fà mí lé àwọn Júù lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí, ìjọba mi kì í ṣe láti orísun yìí.” 37  Nítorí náà, Pílátù wí fún un pé: “Tóò, nígbà náà, ọba ni ọ́ bí?” Jésù dáhùn pé: “Ìwọ fúnra rẹ ń sọ pé ọba ni mí.+ Nítorí èyí ni a ṣe bí mi, nítorí èyí sì ni mo ṣe wá sí ayé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́.+ Olúkúlùkù ẹni tí ó bá wà ní ìhà ọ̀dọ̀ òtítọ́+ ń fetí sí ohùn mi.”+ 38  Pílátù wí fún un pé: “Kí ni òtítọ́?” Lẹ́yìn sísọ èyí, ó tún jáde lọ bá àwọn Júù, ó sì wí fún wọn pé: “Èmi kò rí àléébù kankan nínú rẹ̀.+ 39  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ ní àṣà kan pé mo ní láti tú ọkùnrin kan sílẹ̀ fún yín nígbà ìrékọjá.+ Nítorí náà, ẹ ha fẹ́ kí n tú ọba àwọn Júù sílẹ̀ fún yín bí?” 40  Nígbà náà ni wọ́n tún kígbe, pé: “Kì í ṣe ọkùnrin yìí, bí kò ṣe Bárábà!” Wàyí o, Bárábà jẹ́ ọlọ́ṣà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé