Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jòhánù 17:1-26

17  Jésù sọ nǹkan wọ̀nyí, àti pé, ní gbígbé ojú rẹ̀ sókè sí ọ̀run,+ ó wí pé: “Baba, wákàtí náà ti dé; ṣe ọmọ rẹ lógo, kí ọmọ rẹ lè ṣe ọ́ lógo,+  gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti fún un ní ọlá àṣẹ lórí gbogbo ẹran ara,+ pé, ní ti gbogbo iye àwọn tí ìwọ ti fi fún un,+ kí ó lè fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun.+  Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun,+ gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀+ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́+ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.+  Mo ti yìn ọ́ lógo+ ní ilẹ̀ ayé, ní píparí iṣẹ́ tí ìwọ ti fún mi láti ṣe.+  Nítorí náà, nísinsìnyí ìwọ, Baba, ṣe mí lógo lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara rẹ pẹ̀lú ògo tí mo ti ní lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ kí ayé tó wà.+  “Mo ti fi orúkọ rẹ hàn kedere fún àwọn ènìyàn tí ìwọ fi fún mi láti inú ayé.+ Tìrẹ ni wọ́n ti jẹ́, ìwọ sì fi wọ́n fún mi, wọ́n sì ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́.  Wọ́n ti wá mọ̀ nísinsìnyí pé gbogbo ohun tí ìwọ fi fún mi jẹ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ;  nítorí pé àwọn àsọjáde tí ìwọ fi fún mi ni mo ti fi fún wọn,+ wọ́n sì ti gbà wọ́n, wọ́n sì ti wá mọ̀ dájúdájú pé mo jáde wá gẹ́gẹ́ bí aṣojú rẹ,+ wọ́n sì ti gbà gbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi jáde.+  Mo ṣe ìbéèrè nípa wọn; èmi ko ṣe ìbéèrè nípa ayé,+ bí kò ṣe nípa àwọn tí ìwọ ti fi fún mi; nítorí pé tìrẹ ni wọ́n jẹ́, 10  gbogbo nǹkan tèmi sì jẹ́ tìrẹ, tìrẹ sì jẹ́ tèmi,+ a sì ti ṣe mí lógo láàárín wọn. 11  “Pẹ̀lúpẹ̀lù, èmi kò sí ní ayé mọ́, ṣùgbọ́n wọ́n wà ní ayé,+ èmi sì ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ. Baba mímọ́, máa ṣọ́ wọn+ ní tìtorí orúkọ rẹ, èyí tí ìwọ ti fi fún mi, kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan gan-an gẹ́gẹ́ bí àwa ti jẹ́.+ 12  Nígbà tí mo wà pẹ̀lú wọn, mo ti máa ń ṣọ́ wọn+ ní tìtorí orúkọ rẹ, èyí tí ìwọ ti fi fún mi; mo sì ti pa wọ́n mọ́, kò sì sí ọ̀kan lára wọn tí ó pa run+ àyàfi ọmọ ìparun,+ kí a lè mú ìwé mímọ́ ṣẹ.+ 13  Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, mo ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ, mo sì ń sọ nǹkan wọ̀nyí ní ayé kí wọ́n lè ní ìdùnnú mi nínú ara wọn dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.+ 14  Mo ti fi ọ̀rọ̀ rẹ fún wọn, ṣùgbọ́n ayé ti kórìíra+ wọn, nítorí pé wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé.+ 15  “Èmi kò béèrè pé kí o mú wọn kúrò ní ayé, bí kò ṣe láti máa ṣọ́ wọn nítorí ẹni burúkú náà.+ 16  Wọn kì í ṣe apá kan ayé,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé.+ 17  Sọ wọ́n di mímọ́+ nípasẹ̀ òtítọ́;+ òtítọ́ ni ọ̀rọ̀+ rẹ. 18  Gan-an gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti rán mi jáde sínú ayé, èmi pẹ̀lú rán wọn jáde sínú ayé.+ 19  Mo sì ń sọ ara mi di mímọ́ nítorí wọn, kí a lè sọ àwọn náà di mímọ́+ nípasẹ̀ òtítọ́. 20  “Èmi kò ṣe ìbéèrè nípa àwọn wọ̀nyí nìkan, ṣùgbọ́n nípa àwọn tí yóò ní ìgbàgbọ́ nínú mi pẹ̀lú nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn;+ 21  kí gbogbo wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ìwọ, Baba, ti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi, tí èmi sì wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ,+ kí àwọn náà lè wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú wa,+ kí ayé lè gbà gbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi jáde.+ 22  Pẹ̀lúpẹ̀lù, mo ti fún wọn ní ògo tí ìwọ ti fi fún mi, kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan gan-an gẹ́gẹ́ bí àwa ti jẹ́ ọ̀kan.+ 23  Èmi nínú ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú wọn àti ìwọ nínú ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi, kí a lè ṣe wọ́n pé ní ọ̀kan,+ kí ayé lè ní ìmọ̀ pé ìwọ ni ó rán mi jáde àti pé ìwọ nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti nífẹ̀ẹ́ mi. 24  Baba, ní ti ohun tí ìwọ ti fi fún mi, mo dàníyàn pé, níbi tí mo bá wà, kí àwọn náà lè wà pẹ̀lú mi,+ láti lè rí ògo mi tí ìwọ ti fi fún mi, nítorí pé ìwọ nífẹ̀ẹ́ mi ṣáájú ìgbà pípilẹ̀+ ayé.+ 25  Baba olódodo,+ ní tòótọ́, ayé kò tíì wá mọ̀ ọ́;+ ṣùgbọ́n mo ti wá mọ̀ ọ́, àwọn wọ̀nyí sì ti wá mọ̀ pé ìwọ ni ó rán mi jáde.+ 26  Mo sì ti sọ orúkọ rẹ di mímọ̀+ fún wọn, ṣe ni èmi yóò sì sọ ọ́ di mímọ̀, kí ìfẹ́ tí ìwọ fi nífẹ̀ẹ́ mi lè wà nínú wọn àti èmi ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú wọn.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé