Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jòhánù 14:1-31

14  “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn-àyà yín dààmú.+ Ẹ lo ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run,+ ẹ lo ìgbàgbọ́ nínú mi pẹ̀lú.+  Nínú ilé Baba mi, ọ̀pọ̀ ibùjókòó ni ń bẹ.+ Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, èmi ì bá ti sọ fún yín, nítorí pé mo ń bá ọ̀nà mi lọ láti pèsè ibì kan sílẹ̀ fún yín.  Pẹ̀lúpẹ̀lù, bí mo bá bá ọ̀nà mi lọ, tí mo sì pèsè ibì kan+ sílẹ̀ fún yín, èmi tún ń bọ̀ wá,+ èmi yóò sì gbà yín sí ilé sọ́dọ̀ ara mi,+ pé níbi tí mo bá wà kí ẹ̀yin pẹ̀lú lè wà níbẹ̀.+  Ibi tí èmi sì ń lọ, ẹ mọ ọ̀nà ibẹ̀.”  Tọ́másì+ wí fún un pé: “Olúwa, àwa kò mọ ibi tí ìwọ ń lọ.+ Báwo ni a ṣe mọ ọ̀nà ibẹ̀?”  Jésù wí fún un pé: “Èmi ni ọ̀nà+ àti òtítọ́+ àti ìyè.+ Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.+  Ká ní ẹ ti mọ̀ mí ni, ẹ̀ bá ti mọ Baba mi pẹ̀lú; láti ìṣẹ́jú yìí lọ, ẹ mọ̀ ọ́n, ẹ sì ti rí i.”+  Fílípì wí fún un pé: “Olúwa, fi Baba hàn wá, ó sì tó fún wa.”  Jésù wí fún un pé: “Èmi ha ti wà pẹ̀lú yín fún àkókò gígùn tó bẹ́ẹ̀, síbẹ̀, Fílípì, ìwọ kò sì tíì mọ̀ mí? Ẹni tí ó ti rí mi ti rí Baba+ pẹ̀lú. Èé ti rí tí ìwọ fi wí pé, ‘Fi Baba hàn wá’?+ 10  Ìwọ kò ha gbà gbọ́ pé èmi wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Baba àti pé Baba wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi?+ Àwọn nǹkan tí mo ń sọ fún yín ni èmi kò sọ láti inú àpilẹ̀ṣe ti ara mi; ṣùgbọ́n Baba tí ó dúró ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi ni ó ń ṣe àwọn iṣẹ́ rẹ̀.+ 11  Ẹ gbà mí gbọ́ pé èmi wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Baba àti pé Baba wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ gbà gbọ́ ní tìtorí àwọn iṣẹ́ náà tìkára wọn.+ 12  Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, ẹni yẹn pẹ̀lú yóò ṣe àwọn iṣẹ́ tí èmi ń ṣe; yóò sì ṣe àwọn iṣẹ́ tí ó tóbi ju+ ìwọ̀nyí, nítorí pé mo ń bá ọ̀nà mi lọ sọ́dọ̀ Baba.+ 13  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ohun yòówù kí ó jẹ́ tí ẹ bá béèrè ní orúkọ mi, èmi yóò ṣe èyí dájúdájú, kí a lè yin Baba lógo ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Ọmọ.+ 14  Bí ẹ bá béèrè ohunkóhun ní orúkọ mi, èmi yóò ṣe é dájúdájú. 15  “Bí ẹ bá nífẹ̀ẹ́ mi, ẹ ó pa àwọn àṣẹ mi mọ́;+ 16  dájúdájú, èmi yóò sì béèrè lọ́wọ́ Baba, yóò sì fún yín ní olùrànlọ́wọ́ mìíràn láti wà pẹ̀lú yín títí láé,+ 17  ẹ̀mí òtítọ́ náà,+ èyí tí ayé kò lè gbà,+ nítorí pé kò rí i bẹ́ẹ̀ ni kò mọ̀ ọ́n. Ẹ̀yin mọ̀ ọ́n, nítorí ó wà pẹ̀lú yín, ó sì wà nínú yín.+ 18  Èmi kì yóò fi yín sílẹ̀ ní ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀.+ Èmi ń bọ̀ lọ́dọ̀ yín. 19  Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ayé kì yóò sì rí mi mọ́,+ ṣùgbọ́n ẹ óò rí mi,+ nítorí pé mo wà láàyè, ẹ ó sì wà láàyè.+ 20  Ní ọjọ́ yẹn, ẹ ó mọ̀ pé mo wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Baba mi, ẹ sì wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi, èmi sì wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú yín.+ 21  Ẹni tí ó bá ní àwọn àṣẹ mi, tí ó sì ń pa wọ́n mọ́, ẹni yẹn ni ó nífẹ̀ẹ́ mi.+ Ẹ̀wẹ̀, ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ mi ni Baba mi yóò nífẹ̀ẹ́, ṣe ni èmi yóò sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, èmi yóò sì fi ara mi hàn fún un kedere.” 22  Júdásì,+ kì í ṣe Ísíkáríótù, wí fún un pé: “Olúwa, kí ni ó ṣẹlẹ̀ tí ìwọ fi ń pète-pèrò láti fi ara rẹ hàn wá kedere, tí kì í sì í ṣe fún ayé?”+ 23  Ní ìdáhùn, Jésù wí fún un pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ mi, yóò pa ọ̀rọ̀ mi mọ́,+ Baba mi yóò sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, àwa yóò sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, àwa yóò sì fi ọ̀dọ̀ rẹ̀ ṣe ibùjókòó wa.+ 24  Ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ mi, kò pa àwọn ọ̀rọ̀ mi mọ́; ọ̀rọ̀ tí ẹ sì ń gbọ́ kì í ṣe tèmi, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti Baba tí ó rán mi.+ 25  “Nígbà tí èmi ṣì wà pẹ̀lú yín ni mo ti sọ nǹkan wọ̀nyí fún yín. 26  Ṣùgbọ́n olùrànlọ́wọ́ náà, ẹ̀mí mímọ́, èyí tí Baba yóò rán ní orúkọ mi, èyíinì ni yóò kọ́ yín ní ohun gbogbo, tí yóò sì mú gbogbo ohun tí mo ti sọ fún yín padà wá sí ìrántí yín.+ 27  Mo fi àlàáfíà sílẹ̀ fún yín, mo fi àlàáfíà mi fún yín.+ Èmi kò fi í fún yín lọ́nà tí ayé gbà ń fi í fúnni. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn-àyà yín dààmú tàbí kí ó kó sókè nítorí ìbẹ̀rù. 28  Ẹ gbọ́ tí mo sọ fún yín pé, Èmi ń lọ, èmi sì ń padà bọ̀ sọ́dọ̀ yín. Bí ẹ bá nífẹ̀ẹ́ mi, ẹ ó yọ̀ pé mo ń bá ọ̀nà mi lọ sọ́dọ̀ Baba, nítorí pé Baba tóbi jù+ mí lọ. 29  Nítorí náà, nísinsìnyí mo ti sọ fún yín kí ó tó ṣẹlẹ̀,+ kí ó bàa lè jẹ́ pé, nígbà tí ó bá wá ṣẹlẹ̀, kí ẹ lè gbà gbọ́. 30  Èmi kì yóò bá yín sọ̀rọ̀ púpọ̀ mọ́, nítorí olùṣàkóso+ ayé ń bọ̀. Kò sì ní ìdìmú kankan lórí mi,+ 31  ṣùgbọ́n, nítorí kí ayé lè mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ Baba, àní gẹ́gẹ́ bí Baba ti fi àṣẹ+ fún mi láti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni mo ń ṣe. Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a lọ kúrò ní ìhín.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé