Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jòhánù 13:1-38

13  Wàyí o, nítorí ó mọ̀ ṣáájú àjọyọ̀ ìrékọjá náà pé wákàtí òun ti dé+ fún òun láti lọ kúrò ní ayé yìí sọ́dọ̀ Baba,+ bí Jésù ti nífẹ̀ẹ́ àwọn tirẹ̀ tí wọ́n wà ní ayé,+ ó nífẹ̀ẹ́ wọn dé òpin.  Nítorí náà, bí oúnjẹ alẹ́ ti ń lọ lọ́wọ́, níwọ̀n bí Èṣù ti fi sínú ọkàn-àyà Júdásì Ísíkáríótù,+ ọmọkùnrin Símónì, láti dà á,+  ní mímọ̀ pé Baba ti fi ohun gbogbo lé òun lọ́wọ́+ àti pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni òun ti jáde wá, ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni òun sì ń lọ,+  ó dìde nídìí oúnjẹ alẹ́, ó sì fi ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ lélẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. Àti pé, ní mímú aṣọ ìnura, ó di ara rẹ̀ lámùrè.+  Lẹ́yìn èyíinì, ó bu omi sínú bàsíà kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wẹ ẹsẹ̀+ àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sì fi aṣọ ìnura tí ó fi di ara rẹ̀ lámùrè nù wọ́n gbẹ.  Nítorí náà, ó wá sọ́dọ̀ Símónì Pétérù. Ó wí fún un pé: “Olúwa, ṣé o fẹ́ wẹ ẹsẹ̀ mi ni?”+  Ní ìdáhùn, Jésù wí fún un pé: “Ohun tí mo ń ṣe kò yé ọ nísinsìnyí, ṣùgbọ́n yóò yé ọ lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí.”+  Pétérù wí fún un pé: “Dájúdájú, ìwọ kì yóò wẹ ẹsẹ̀ mi láé.” Jésù dá a lóhùn pé: “Láìjẹ́ pé mo wẹ ẹsẹ̀ rẹ,+ ìwọ kò ní ipa kankan lọ́dọ̀ mi.”  Símónì Pétérù wí fún un pé: “Olúwa, kì í ṣe ẹsẹ̀ mi nìkan, ṣùgbọ́n ọwọ́ mi àti orí mi pẹ̀lú.” 10  Jésù wí fún un pé: “Ẹni tí ó ti wẹ̀+ kò nílò pé kí a wẹ̀ ju ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ, ṣùgbọ́n ó mọ́ látòkè délẹ̀. Ẹ̀yin sì mọ́, ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo yín.” 11  Ní tòótọ́, ó mọ ẹni tí yóò da òun.+ Ìdí nìyí tí ó fi wí pé: “Kì í ṣe gbogbo yín ni ó mọ́.” 12  Wàyí o, nígbà tí ó ti fọ ẹsẹ̀ wọn tán, tí ó sì ti gbé ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ wọ̀, tí ó sì tún fara lélẹ̀ nídìí tábìlì, ó wí fún wọn pé: “Ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tí mo ṣe fún yín? 13  Ẹ ń pè mí ní, ‘Olùkọ́,’+ àti ‘Olúwa,’+ ẹ sì sọ̀rọ̀ lọ́nà títọ́, nítorí bẹ́ẹ̀ ni mo jẹ́.+ 14  Nítorí náà, bí èmi, tí ó tilẹ̀ jẹ́ Olúwa àti Olùkọ́, bá wẹ ẹsẹ̀ yín,+ ó yẹ kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa wẹ ẹsẹ̀ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.+ 15  Nítorí mo fi àwòṣe lélẹ̀ fún yín, pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe fún yín, ni kí ẹ máa ṣe pẹ̀lú.+ 16  Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹrú kò tóbi ju ọ̀gá rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí a rán jáde kò tóbi ju ẹni tí ó rán an.+ 17  Bí ẹ bá mọ nǹkan wọ̀nyí, aláyọ̀ ni yín bí ẹ bá ń ṣe wọ́n.+ 18  Èmi kò sọ̀rọ̀ nípa gbogbo yín; mo mọ àwọn tí mo ti yàn.+ Ṣùgbọ́n ó jẹ́ kí a lè mú Ìwé Mímọ́ ṣẹ+ pé, ‘Ẹni tí ó ti ń fi oúnjẹ mi ṣe oúnjẹ jẹ, ti gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sókè sí mi.’+ 19  Láti ìṣẹ́jú yìí lọ, mo ń sọ fún yín kí ó tó ṣẹlẹ̀,+ kí ó lè jẹ́ pé nígbà tí ó bá wá ṣẹlẹ̀, kí ẹ lè gbà gbọ́ pé èmi ni ẹni náà. 20  Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹni tí ó bá gba ẹnikẹ́ni tí mo rán, gba èmi pẹ̀lú.+ Ẹ̀wẹ̀, ẹni tí ó bá gbà mí, gba ẹni tí ó rán mi pẹ̀lú.”+ 21  Lẹ́yìn sísọ nǹkan wọ̀nyí, Jésù dààmú nínú ẹ̀mí, ó sì jẹ́rìí, ó sì wí pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ọ̀kan nínú yín yóò dà mí.”+ 22  Àwọn ọmọ ẹ̀yìn bẹ̀rẹ̀ sí wo ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì, bí ó ti rú wọn lójú ní ti ẹni tí ó ń sọ nípa rẹ̀.+ 23  Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rọ̀gbọ̀kú níwájú oókan àyà Jésù, Jésù sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.+ 24  Nítorí náà, Símónì Pétérù mi orí sí ẹni yìí, ó sì wí fún un pé: “Sọ ẹni tí ó ń sọ nípa rẹ̀.” 25  Bẹ́ẹ̀ ni ẹni náà tẹ̀ sẹ́yìn lé igẹ̀ Jésù, ó sì wí fún un pé: “Olúwa, ta ni?”+ 26  Nítorí náà, Jésù dáhùn pé: “Ẹni tí èmi yóò fún ní òkèlè tí mo bá fi runbẹ̀ ni.”+ Nítorí náà, lẹ́yìn fífi òkèlè náà runbẹ̀, ó mú un, ó sì fi í fún Júdásì, ọmọkùnrin Símónì Ísíkáríótù. 27  Àti lẹ́yìn òkèlè náà, nígbà náà ni Sátánì wọ inú ẹni tí a dárúkọ kẹ́yìn.+ Nítorí náà, Jésù wí fún un pé: “Ohun tí ìwọ ń ṣe túbọ̀ ṣe é kíákíá.” 28  Àmọ́ ṣá o kò sí ọ̀kan nínú àwọn tí ó rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì tí ó mọ ète tí ó fi sọ èyí fún un. 29  Àwọn kan, ní ti tòótọ́, lérò pé, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ọwọ́ Júdásì ni àpótí owó+ wà, Jésù ń sọ fún un pé: “Ra àwọn ohun tí a nílò fún àjọyọ̀ náà,” tàbí pé kí ó fi ohun kan fún àwọn òtòṣì.+ 30  Nítorí náà, lẹ́yìn tí ó gba òkèlè náà, ó jáde lọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Òru sì ni.+ 31  Nítorí bẹ́ẹ̀, nígbà tí ó ti jáde lọ, Jésù wí pé: “Nísinsìnyí, a ṣe Ọmọ ènìyàn lógo,+ a sì ṣe Ọlọ́run lógo ní ìsopọ̀ pẹ̀lú rẹ̀. 32  Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì ṣe é lógo,+ yóò sì ṣe é lógo lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. 33  Ẹ̀yin ọmọ kéékèèké,+ ìgbà díẹ̀ sí i ni èmi yóò fi wà pẹ̀lú yín. Ẹ óò wá mi; gan-an gẹ́gẹ́ bí mo sì ti sọ fún àwọn Júù pé, ‘Ibi tí mo ń lọ, ẹ kò lè wá síbẹ̀,’+ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni mo sọ fún yín nísinsìnyí. 34  Èmi ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì; gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín,+ pé kí ẹ̀yin pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.+ 35  Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.”+ 36  Símónì Pétérù wí fún un pé: “Olúwa, ibo ni ìwọ ń lọ?” Jésù dáhùn pé: “Ibi tí mo ń lọ, ìwọ kò lè tẹ̀ lé mi nísinsìnyí, ṣùgbọ́n ìwọ yóò tẹ̀ lé mi nígbà tí ó bá yá.”+ 37  Pétérù wí fún un pé: “Olúwa, èé ṣe tí n kò lè tẹ̀ lé ọ nísinsìnyí? Dájúdájú, èmi yóò fi ọkàn mi lélẹ̀ nítorí rẹ.”+ 38  Jésù dáhùn pé: “Ìwọ yóò ha fi ọkàn rẹ lélẹ̀ nítorí mi? Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, Àkùkọ kì yóò kọ lọ́nàkọnà títí ìwọ yóò fi sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú mi ní ìgbà mẹ́ta.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé