Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jòhánù 12:1-50

12  Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, ní ọjọ́ mẹ́fà ṣáájú ìrékọjá, Jésù dé sí Bẹ́tánì,+ níbi tí Lásárù,+ ẹni tí Jésù ti gbé dìde kúrò nínú òkú wà.  Nítorí náà, wọ́n se àsè oúnjẹ alẹ́ fún un níbẹ̀, Màtá+ sì ń ṣèránṣẹ́,+ ṣùgbọ́n Lásárù jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí ó rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì pẹ̀lú rẹ̀.+  Nítorí náà, Màríà mú ìwọ̀n pọ́n-ùn kan òróró onílọ́fínńdà, ojúlówó náádì,+ olówó iyebíye gan-an, ó sì fi pa ẹsẹ̀ Jésù, ó sì fi irun rẹ̀ nu ẹsẹ̀ rẹ̀ gbẹ.+ Ilé náà wá kún fún ìtasánsán òróró onílọ́fínńdà náà.  Ṣùgbọ́n Júdásì Ísíkáríótù,+ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, tí ó máa tó dà á, wí pé:  “Èé ṣe tí a kò ta òróró onílọ́fínńdà+ yìí ní ọ̀ọ́dúnrún owó dínárì, kí a sì fi fún àwọn òtòṣì?”+  Àmọ́ ṣá o, ó sọ èyí, kì í ṣe nítorí pé ó ń ṣàníyàn nípa àwọn òtòṣì, bí kò ṣe nítorí pé olè+ ni, àti pé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni àpótí owó+ wà, a sì máa kó àwọn owó tí a fi sínú rẹ̀ lọ.  Nítorí náà, Jésù wí pé: “Jọ̀wọ́ rẹ̀ jẹ́ẹ́, kí ó lè pa ààtò àkíyèsí yìí mọ́ nítorí ọjọ́ ìsìnkú mi.+  Nítorí ẹ̀yin ní àwọn òtòṣì+ nígbà gbogbo pẹ̀lú yín, ṣùgbọ́n èmi ni ẹ kì yóò ní nígbà gbogbo.”  Nítorí náà, ogunlọ́gọ̀ ńlá àwọn Júù wá mọ̀ pé ó wà níbẹ̀, wọ́n sì wá, kì í ṣe ní tìtorí Jésù nìkan, ṣùgbọ́n láti rí Lásárù pẹ̀lú, ẹni tí ó gbé dìde kúrò nínú òkú.+ 10  Àwọn olórí àlùfáà gbìmọ̀ pọ̀ nísinsìnyí láti pa Lásárù pẹ̀lú,+ 11  nítorí pé ní tìtorí rẹ̀, ọ̀pọ̀ lára àwọn Júù ń lọ sí ibẹ̀, wọ́n sì ń ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù.+ 12  Ní ọjọ́ kejì, ogunlọ́gọ̀ ńlá tí ó ti wá sí àjọyọ̀ náà, ní gbígbọ́ pé Jésù ń bọ̀ ní Jerúsálẹ́mù, 13  mú àwọn imọ̀ ọ̀pẹ,+ wọ́n sì jáde lọ pàdé rẹ̀. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kígbe+ pé: “Gbà là, àwa bẹ̀ ọ́!+ Alábùkún ni ẹni tí ń bọ̀ ní orúkọ Jèhófà,+ àní ọba+ Ísírẹ́lì!” 14  Ṣùgbọ́n nígbà tí Jésù ti rí ẹgbọrọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan,+ ó jókòó lórí rẹ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: 15  “Má bẹ̀rù, ọmọbìnrin Síónì. Wò ó! Ọba rẹ ń bọ̀,+ ó jókòó lórí agódóńgbó.”+ 16  Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kò fiyè sí ní àkọ́kọ́,+ ṣùgbọ́n nígbà tí Jésù di ẹni tí a ṣe lógo,+ nígbà náà ni wọ́n rántí pé a ti kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí nípa rẹ̀ àti pé wọ́n ṣe nǹkan wọ̀nyí sí i.+ 17  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ogunlọ́gọ̀ tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tí ó pe Lásárù+ jáde ní ibojì ìrántí, tí ó sì gbé e dìde kúrò nínú òkú ń bá a nìṣó ní jíjẹ́rìí.+ 18  Ní tìtorí èyí, ogunlọ́gọ̀ náà, nítorí wọ́n gbọ́ pé ó ti ṣe iṣẹ́ àmì yìí,+ pàdé rẹ̀ pẹ̀lú. 19  Nítorí náà, àwọn Farisí+ sọ láàárín ara wọn pé: “Ẹ ṣàkíyèsí pé ẹ kò ṣe àṣeyọrí kankan rárá. Wò ó! Ayé ti wọ́ tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.”+ 20  Wàyí o, àwọn Gíríìkì+ kan wà lára àwọn tí wọ́n gòkè wá láti jọ́sìn níbi àjọyọ̀ náà. 21  Nítorí náà, àwọn wọ̀nyí tọ Fílípì+ wá, ẹni tí ó wá láti Bẹtisáídà ti Gálílì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, pé: “Ọ̀gá, a fẹ́ rí Jésù.”+ 22  Fílípì wá, ó sì sọ fún Áńdérù. Áńdérù àti Fílípì wá, wọ́n sì sọ fún Jésù. 23  Ṣùgbọ́n Jésù dá wọn lóhùn, pé: “Wákàtí náà ti dé tí a ó ṣe Ọmọ ènìyàn lógo.+ 24  Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Láìjẹ́ pé hóró àlìkámà bọ́ sínú ilẹ̀, kí ó sì kú, ó ṣì wà ní ẹyọ hóró kan ṣoṣo; ṣùgbọ́n bí ó bá kú,+ nígbà náà ni yóò so èso púpọ̀. 25  Ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ni fún ọkàn rẹ̀ ń pa á run, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá kórìíra ọkàn+ rẹ̀ nínú ayé yìí, yóò fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ fún ìyè àìnípẹ̀kun.+ 26  Bí ẹnikẹ́ni yóò bá ṣe ìránṣẹ́ fún mi, kí ó tọ̀ mí lẹ́yìn, níbi tí mo bá sì wà, ibẹ̀ ni òjíṣẹ́ mi yóò wà pẹ̀lú.+ Bí ẹnikẹ́ni yóò bá ṣèránṣẹ́ fún mi, Baba yóò bọlá fún un.+ 27  Wàyí o, ọkàn mi dààmú,+ kí ni èmi yóò sì sọ? Baba, gbà mí là kúrò nínú wákàtí yìí.+ Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìdí nìyí tí mo fi wá sí wákàtí yìí. 28  Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo.” Nítorí náà, ohùn+ kan jáde wá láti ọ̀run pé: “Èmi ti ṣe é lógo, èmi yóò sì tún ṣe é lógo+ dájúdájú.” 29  Nítorí bẹ́ẹ̀, ogunlọ́gọ̀ tí ó dúró yí ká, tí ó sì gbọ́, bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé ààrá ti sán. Àwọn mìíràn bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Áńgẹ́lì kan ti bá a sọ̀rọ̀.” 30  Ní ìdáhùn, Jésù wí pé: “Ohùn yìí dún, kì í ṣe nítorí tèmi, bí kò ṣe nítorí tiyín.+ 31  Nísinsìnyí ni ṣíṣèdájọ́ ayé yìí; nísinsìnyí, olùṣàkóso ayé yìí+ ni a óò lé jáde.+ 32  Síbẹ̀, bí a bá gbé mi sókè kúrò ní ilẹ̀ ayé,+ ṣe ni èmi yóò fa onírúurú ènìyàn gbogbo sọ́dọ̀ mi.”+ 33  Èyí ni ó ń sọ ní ti gidi láti fi tọ́ka sí irú ikú tí ó máa tó kú.+ 34  Nítorí náà, ogunlọ́gọ̀ náà dá a lóhùn pé: “Àwa gbọ́ láti inú Òfin pé Kristi wà títí láé;+ èé sì ti rí tí o fi wí pé Ọmọ ènìyàn ni a gbọ́dọ̀ gbé sókè?+ Ta ni Ọmọ ènìyàn yìí?”+ 35  Nítorí náà, Jésù wí fún wọn pé: “Ìmọ́lẹ̀ yóò wà láàárín yín fún ìgbà díẹ̀ sí i. Ẹ rìn nígbà tí ẹ ní ìmọ́lẹ̀ náà, kí òkùnkùn+ má bàa borí yín; ẹni tí ó bá sì ń rìn nínú òkùnkùn kò mọ ibi tí òun ń lọ.+ 36  Nígbà tí ẹ ní ìmọ́lẹ̀ náà, ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú ìmọ́lẹ̀ náà, láti lè di ọmọ ìmọ́lẹ̀.”+ Jésù sọ nǹkan wọ̀nyí, ó sì lọ, ó sì fara pa mọ́ fún wọn. 37  Ṣùgbọ́n bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì níwájú wọn, wọn kì í ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, 38  tí ọ̀rọ̀ Aísáyà wòlíì fi ṣẹ tí ó wí pé: “Jèhófà, ta ni ó ti lo ìgbàgbọ́ nínú ohun tí a gbọ́?+ Ní ti apá Jèhófà, ta sì ni a ti ṣí i payá fún?”+ 39  Ìdí tí wọn kò fi lè gbà gbọ́ ni pé Aísáyà tún wí pé: 40  “Ó ti fọ́ ojú wọn, ó sì ti sé ọkàn-àyà wọn le,+ kí wọ́n má bàa fi ojú wọn rí, kí wọ́n sì fi ọkàn-àyà wọn mòye, kí wọ́n sì yí padà, kí n sì mú wọn lára dá.”+ 41  Aísáyà sọ nǹkan wọ̀nyí nítorí ó rí ògo rẹ̀,+ ó sì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. 42  Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀pọ̀ lára àwọn olùṣàkóso pàápàá ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀+ ní ti gidi, ṣùgbọ́n nítorí àwọn Farisí wọn kì í jẹ́wọ́ rẹ̀, kí a má bàa lé wọn jáde kúrò nínú sínágọ́gù;+ 43  nítorí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ògo ènìyàn ju ògo Ọlọ́run pàápàá.+ 44  Bí ó ti wù kí ó rí, Jésù ké jáde ó sì wí pé: “Ẹni tí ó bá ní ìgbàgbọ́ nínú mi, kò ní ìgbàgbọ́ nínú èmi nìkan, ṣùgbọ́n nínú ẹni tí ó rán mi pẹ̀lú;+ 45  ẹni tí ó bá sì rí mi, rí ẹni tí ó rán mi pẹ̀lú.+ 46  Èmi ti wá gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ sínú ayé,+ kí olúkúlùkù ẹni tí ń ní ìgbàgbọ́ nínú mi má bàa wà nínú òkùnkùn.+ 47  Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ àwọn àsọjáde mi, tí kò sì pa wọ́n mọ́, èmi kò dá a lẹ́jọ́; nítorí pé kò wá láti dá ayé lẹ́jọ́,+ bí kò ṣe láti gba ayé là.+ 48  Ẹni tí ó bá ṣàìkà mí sí, tí kò sì gba àwọn àsọjáde mi, ní ẹnì kan láti dá a lẹ́jọ́. Ọ̀rọ̀+ tí mo ti sọ ni yóò dá a lẹ́jọ́ ní ọjọ́ ìkẹyìn; 49  nítorí pé èmi kò sọ̀rọ̀ láti inú agbára ìsúnniṣe ti ara mi, ṣùgbọ́n Baba fúnra rẹ̀ tí ó rán mi ti fún mi ní àṣẹ kan ní ti ohun tí èmi yóò wí àti ohun tí èmi yóò sọ.+ 50  Pẹ̀lúpẹ̀lù, mo mọ̀ pé àṣẹ rẹ̀ túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun.+ Nítorí náà, àwọn ohun tí mo ń sọ, gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba ti sọ wọ́n fún mi, bẹ́ẹ̀ ni mo ń sọ wọ́n.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé