Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jòhánù 11:1-57

11  Wàyí o, ọkùnrin kan wà tí ń ṣàìsàn, Lásárù ti Bẹ́tánì, ti abúlé Màríà àti Màtá+ arábìnrin rẹ̀.  Ní ti tòótọ́, òun ni Màríà tí ó fi òróró onílọ́fínńdà+ pa Olúwa lára, tí ó sì fi irun rẹ̀ nu ẹsẹ̀ rẹ̀ gbẹ,+ ẹni tí arákùnrin rẹ̀ Lásárù ń ṣàìsàn.  Nítorí náà, àwọn arábìnrin rẹ̀ ránṣẹ́ sí i, pé: “Olúwa, wò ó! ẹni tí ìwọ ní ìfẹ́ni+ fún ń ṣàìsàn.”  Ṣùgbọ́n nígbà tí Jésù gbọ́, ó wí pé: “Ikú kọ́ ni ìgbẹ̀yìn àìsàn yìí, ṣùgbọ́n ó jẹ́ fún ògo Ọlọ́run,+ kí a lè yin Ọmọ Ọlọ́run lógo nípasẹ̀ rẹ̀.”  Wàyí o, Jésù nífẹ̀ẹ́ Màtá àti arábìnrin rẹ̀ àti Lásárù.  Àmọ́ ṣá o, nígbà tí ó gbọ́ pé ó ń ṣàìsàn, nígbà náà, ó dúró ní ti gidi fún ọjọ́ méjì ní ibi tí ó wà.  Lẹ́yìn èyí, ó wá sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn pé: “Ẹ jẹ́ kí a tún lọ sí Jùdíà.”  Àwọn ọmọ ẹ̀yìn sọ fún un pé: “Rábì,+ àìpẹ́ yìí ni àwọn ará Jùdíà ń wá ọ̀nà láti sọ ọ́ ní òkúta,+ ìwọ ha sì tún ń lọ sí ibẹ̀ bí?”  Jésù dáhùn pé: “Wákàtí méjìlá ojúmọmọ ní ń bẹ, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Bí ẹnikẹ́ni bá ń rìn ní ojúmọmọ+ kì í ta lu ohunkóhun, nítorí ó ń rí ìmọ́lẹ̀ ayé yìí. 10  Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá ń rìn ní òru,+ òun a ta lu nǹkan kan, nítorí ìmọ́lẹ̀ kò sí nínú rẹ̀.” 11  Ó sọ nǹkan wọ̀nyí, àti lẹ́yìn èyí, ó wí fún wọn pé: “Lásárù ọ̀rẹ́ wa ti lọ sinmi, ṣùgbọ́n mo ń rìnrìn àjò lọ sí ibẹ̀ láti jí i kúrò lójú oorun.”+ 12  Nítorí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn wí fún un pé: “Olúwa, bí ó bá jẹ́ pé ó lọ sinmi ni, ara rẹ̀ yóò dá.” 13  Bí ó ti wù kí ó rí, Jésù sọ̀rọ̀ nípa ikú rẹ̀. Ṣùgbọ́n wọ́n lérò pé ó ń sọ̀rọ̀ nípa sísinmi nínú oorun. 14  Nítorí náà, ní àkókò yẹn, Jésù wí fún wọn láìfọ̀rọ̀-bọpo-bọyọ̀ pé: “Lásárù ti kú,+ 15  mo sì yọ̀ ní tìtorí yín pé èmi kò sí níbẹ̀, nítorí kí ẹ lè gbà gbọ́. Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.” 16  Nítorí náà, Tọ́másì, ẹni tí a ń pè ní Ìbejì, sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ jẹ́ kí àwa pẹ̀lú lọ, kí a lè bá a kú.”+ 17  Nítorí náà, nígbà tí Jésù dé, ó rí i pé ó ti wà fún ọjọ́ mẹ́rin nísinsìnyí nínú ibojì ìrántí.+ 18  Wàyí o, Bẹ́tánì sún mọ́ Jerúsálẹ́mù tó nǹkan bí ibùsọ̀ méjì. 19  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù ti wá sọ́dọ̀ Màtá àti Màríà láti tù wọ́n nínú+ nítorí ti arákùnrin wọn. 20  Nítorí náà, nígbà tí Màtá gbọ́ pé Jésù ń bọ̀, ó lọ pàdé rẹ̀; ṣùgbọ́n Màríà+ ń bá a lọ ní jíjókòó sí ilé. 21  Nítorí náà, Màtá wí fún Jésù pé: “Olúwa, ká ní o ti wà níhìn-ín ni, arákùnrin mi kì bá kú.+ 22  Síbẹ̀, nísinsìnyí mo mọ̀ pé gbogbo nǹkan tí o bá béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run,+ Ọlọ́run yóò fún ọ.” 23  Jésù wí fún un pé: “Arákùnrin rẹ yóò dìde.”+ 24  Màtá wí fún un pé: “Mo mọ̀ pé yóò dìde nínú àjíǹde+ ní ọjọ́ ìkẹyìn.” 25  Jésù wí fún un pé: “Èmi ni àjíǹde àti ìyè.+ Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè;+ 26  àti olúkúlùkù ẹni tí ń bẹ láàyè, tí ó sì ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, kì yóò kú láé.+ Ìwọ ha gba èyí gbọ́ bí?” 27  Ó wí fún un pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa; mo ti gbà gbọ́ pé ìwọ ni Kristi Ọmọ Ọlọ́run, Ẹni tí ń bọ̀ wá sí ayé.”+ 28  Nígbà tí ó sì ti sọ èyí, ó lọ, ó sì pe Màríà arábìnrin rẹ̀, ó wí ní bòókẹ́lẹ́ pé: “Olùkọ́+ ti wà níhìn-ín, ó sì ń pè ọ́.” 29  Nígbà tí ẹni kejì yìí gbọ́ èyí, ó dìde kíákíá, ó sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. 30  Ní ti tòótọ́, Jésù kò tíì wọ abúlé náà, ṣùgbọ́n ó ṣì wà ní ibi tí Màtá ti pàdé rẹ̀. 31  Nítorí náà, àwọn Júù tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ilé,+ tí wọ́n sì ń tù ú nínú, ní rírí Màríà tí ó dìde kíákíá, tí ó sì jáde lọ, wọ́n tẹ̀ lé e, ní rírò pé ibojì ìrántí+ ni ó ń lọ láti lọ sunkún níbẹ̀. 32  Nítorí náà, nígbà tí Màríà dé ibi tí Jésù wà, tí ó sì tajú kán rí i, ó wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó wí fún un pé: “Olúwa, ká ní o ti wà níhìn-ín ni, arákùnrin mi kì bá kú.”+ 33  Nítorí náà, Jésù, nígbà tí ó rí i tí ó ń sunkún àti àwọn Júù tí wọ́n bá a wá tí wọ́n ń sunkún, ó kérora nínú ẹ̀mí, ó sì dààmú;+ 34  ó sì wí pé: “Ibo ni ẹ tẹ́ ẹ sí?” Wọ́n wí fún un pé: “Olúwa, wá wò ó.” 35  Jésù bẹ̀rẹ̀ sí da omijé.+ 36  Nítorí náà, àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Ẹ wò ó, ó mà ní ìfẹ́ni fún un o!”+ 37  Ṣùgbọ́n àwọn kan lára wọ́n wí pé: “Ṣé ọkùnrin yìí tí ó la ojú+ ọkùnrin afọ́jú náà kò lè dènà kíkú ẹni yìí ni?” 38  Nítorí bẹ́ẹ̀, lẹ́yìn tí Jésù kérora lẹ́ẹ̀kan sí i nínú ara rẹ̀, ó wá sí ibojì ìrántí náà.+ Ní ti tòótọ́, hòrò kan ni, òkúta+ kan sì wà lójú rẹ̀. 39  Jésù wí pé: “Ẹ gbé òkúta náà+ kúrò.” Màtá, arábìnrin olóògbé náà, wí fún un pé: “Olúwa, ní báyìí yóò ti máa rùn, nítorí ó di ọjọ́ mẹ́rin.” 40  Jésù wí fún un pé: “Èmi kò ha sọ fún ọ pé bí ìwọ bá gbà gbọ́, ìwọ yóò rí ògo Ọlọ́run?”+ 41  Nítorí náà, wọ́n gbé òkúta náà kúrò. Wàyí o, Jésù gbé ojú rẹ̀ sókè sí ọ̀run,+ ó sì wí pé: “Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ pé o ti gbọ́ tèmi.+ 42  Lóòótọ́, èmi mọ̀ pé ìwọ ń gbọ́ tèmi nígbà gbogbo; ṣùgbọ́n ní tìtorí ogunlọ́gọ̀+ tí ó dúró yí ká ni mo fi sọ̀rọ̀, kí wọ́n lè gbà gbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi jáde.”+ 43  Nígbà tí ó sì ti sọ nǹkan wọ̀nyí, ó ké jáde ní ohùn rara pé: “Lásárù, jáde wá!”+ 44  Ọkùnrin tí ó ti kú náà jáde wá pẹ̀lú ẹsẹ̀ àti ọwọ́ rẹ̀ tí a fi àwọn aṣọ ìdìkú dì,+ ojú rẹ̀ ni a sì fi aṣọ dì yí ká. Jésù wí fún wọn pé: “Ẹ tú u, ẹ sì jẹ́ kí ó máa lọ.” 45  Nítorí náà, ọ̀pọ̀ lára àwọn Júù tí wọ́n ti wá sọ́dọ̀ Màríà, tí wọ́n sì rí ohun tí ó ṣe, ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀;+ 46  ṣùgbọ́n àwọn kan lára wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn Farisí, wọ́n sì sọ àwọn ohun tí Jésù ṣe fún wọn.+ 47  Nítorí náà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí kó Sànhẹ́dírìn+ jọpọ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Kí ni kí a ṣe, nítorí ọkùnrin yìí ń ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì?+ 48  Bí a bá jọ̀wọ́ rẹ̀ jẹ́ẹ́ lọ́nà yìí, gbogbo wọn yóò ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀,+ àwọn ará Róòmù+ yóò wá, wọn yóò sì gba àyè wa+ àti orílẹ̀-èdè wa.” 49  Ṣùgbọ́n ẹnì kan lára wọn, Káyáfà, tí ó jẹ́ àlùfáà àgbà ní ọdún yẹn,+ wí fún wọn pé: “Ẹ kò mọ ohunkóhun rárá, 50  ẹ kò sì ronú pé ó jẹ́ fún àǹfààní yín pé kí ọkùnrin kan kú+ nítorí àwọn ènìyàn, kí gbogbo orílẹ̀-èdè má sì pa run.”+ 51  Àmọ́ ṣá o, kò sọ èyí láti inú àpilẹ̀ṣe ti ara rẹ̀; ṣùgbọ́n nítorí pé òun ni àlùfáà àgbà ní ọdún yẹn, ó sọ tẹ́lẹ̀ pé Jésù ni a ti yàn tẹ́lẹ̀ láti kú fún orílẹ̀-èdè náà, 52  kì í sì í ṣe fún orílẹ̀-èdè náà nìkan, ṣùgbọ́n kí ó bàa lè jẹ́ pé àwọn ọmọ Ọlọ́run tí ó tú ká+ káàkiri ni òun yóò lè kó jọpọ̀ ṣọ̀kan pẹ̀lú.+ 53  Nítorí náà, láti ọjọ́ yẹn lọ, wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á.+ 54  Nítorí bẹ́ẹ̀, Jésù kò rìn kiri mọ́ ní gbangba+ láàárín àwọn Júù,+ ṣùgbọ́n ó lọ kúrò níbẹ̀ sí ilẹ̀ tí ó wà nítòsí aginjù, sí ìlú ńlá tí a ń pè ní Éfúráímù,+ ibẹ̀ ni ó sì dúró pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn. 55  Wàyí o, ìrékọjá+ àwọn Júù sún mọ́lé, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì gòkè lọ láti ilẹ̀ náà sí Jerúsálẹ́mù ṣáájú ìrékọjá láti wẹ ara wọn mọ́ lọ́nà ayẹyẹ.+ 56  Nítorí náà, wọ́n lọ ń wá Jésù, wọn a sì máa sọ fún ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì bí wọ́n ti dúró káàkiri nínú tẹ́ńpìlì pé: “Kí ni èrò yín? Pé òun kì yóò wá sí àjọyọ̀ náà rárá ni bí?” 57  Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí ti pa àṣẹ ìtọ́ni pé bí ẹnikẹ́ni bá mọ ibi tí ó wà, ó ní láti sọ ọ́ di mímọ̀, kí wọ́n lè gbá a mú.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé