Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jòhánù 1:1-51

1  Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀+ ni Ọ̀rọ̀+ náà wà, Ọ̀rọ̀ náà sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run,+ Ọ̀rọ̀ náà sì jẹ́ ọlọ́run kan.+  Ẹni yìí ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀+ wà pẹ̀lú Ọlọ́run.+  Ohun gbogbo di wíwà nípasẹ̀ rẹ̀,+ àti pé láìsí i, àní ohun kan kò di wíwà. Ohun tí ó ti di wíwà  nípasẹ̀ rẹ̀ ni ìyè,+ ìyè náà sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀+ àwọn ènìyàn.  Ìmọ́lẹ̀ náà sì ń tàn nínú òkùnkùn,+ ṣùgbọ́n òkùnkùn náà kò tíì borí rẹ̀.  Ọkùnrin kan dìde tí a rán jáde gẹ́gẹ́ bí aṣojú Ọlọ́run:+ orúkọ rẹ̀ ni Jòhánù.+  Ọkùnrin yìí wá fún ẹ̀rí,+ láti lè jẹ́rìí nípa ìmọ́lẹ̀ náà,+ kí onírúurú ènìyàn gbogbo bàa lè gbà gbọ́ nípasẹ̀ rẹ̀.+  Òun kọ́ ni ìmọ́lẹ̀ yẹn,+ ṣùgbọ́n a pète rẹ̀ láti jẹ́rìí+ nípa ìmọ́lẹ̀ yẹn.  Ìmọ́lẹ̀ tòótọ́+ tí ń fi ìmọ́lẹ̀+ fún gbogbo onírúurú ènìyàn+ máa tó wá sí ayé. 10  Ó ti wà ní ayé,+ ayé sì di wíwà nípasẹ̀ rẹ̀,+ ṣùgbọ́n ayé kò mọ̀ ọ́n. 11  Ó wá sí ilé òun fúnra rẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn tirẹ̀ kò gbà á wọlé.+ 12  Bí ó ti wù kí ó rí, gbogbo àwọn tí wọ́n gbà á,+ àwọn ni ó fún ní ọlá àṣẹ láti di ọmọ Ọlọ́run,+ nítorí pé wọ́n ń lo ìgbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀;+ 13  a sì bí wọn, kì í ṣe láti inú ẹ̀jẹ̀ tàbí láti inú ìfẹ́ ti ẹran ara tàbí láti inú ìfẹ́ ènìyàn, bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.+ 14  Bẹ́ẹ̀ ni Ọ̀rọ̀ náà di ẹlẹ́ran ara,+ ó sì gbé láàárín wa, a sì rí ògo rẹ̀, ògo kan irú èyí tí ó jẹ́ ti ọmọkùnrin bíbí kan ṣoṣo+ láti ọ̀dọ̀ baba kan; ó sì kún fún inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti òtítọ́.+ 15  (Jòhánù jẹ́rìí nípa rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni, ní ti gidi, ó ké jáde—èyí ni ẹni tí ó sọ ọ́—wí pé: “Ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi ti lọ jìnnà níwájú mi, nítorí pé ó wà ṣáájú mi.”)+ 16  Nítorí pé gbogbo wa ti gbà láti inú ẹ̀kún rẹ̀,+ àní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí lórí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí.+ 17  Nítorí pé nípasẹ̀ Mósè ni a fi Òfin fúnni,+ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí+ àti òtítọ́+ wá wà nípasẹ̀ Jésù Kristi. 18  Kò sí ènìyàn kankan tí ó ti rí Ọlọ́run nígbà kankan rí;+ ọlọ́run bíbí kan ṣoṣo+ tí ó wà ní ipò oókan àyà+ lọ́dọ̀ Baba ni ẹni tí ó ti ṣàlàyé rẹ̀.+ 19  Wàyí o, èyí ni ẹ̀rí Jòhánù nígbà tí àwọn Júù rán àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì jáde láti Jerúsálẹ́mù sí i láti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ta ni ọ́?”+ 20  Ó sì jẹ́wọ́, kò sì sẹ́, ṣùgbọ́n ó jẹ́wọ́ pé: “Èmi kọ́ ni Kristi náà.”+ 21  Wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí wá ni? Ìwọ ni Èlíjà bí?”+ Ó sì wí pé: “Èmi kọ́.” “Ìwọ ni Wòlíì Náà bí?”+ Ó sì dáhùn pé: “Ó tì o!” 22  Nítorí náà, wọ́n wí fún un pé: “Ta ni ọ́? kí a lè fi ìdáhùn fún àwọn tí wọ́n rán wa níṣẹ́. Kí ni ìwọ wí nípa ara rẹ?”+ 23  Ó wí pé: “Èmi ni ohùn ẹni tí ń ké jáde ní aginjù pé, ‘Ẹ mú kí ọ̀nà Jèhófà jẹ́ títọ́,’ gan-an gẹ́gẹ́ bí Aísáyà wòlíì ti wí.”+ 24  Wàyí o, àwọn tí a rán jáde jẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn Farisí. 25  Nítorí náà, wọ́n bi í léèrè, wọ́n sì wí fún un pé: “Èé ṣe tí o wá fi ń batisí+ bí ìwọ fúnra rẹ kì í bá ṣe Kristi náà tàbí Èlíjà tàbí Wòlíì Náà?” 26  Jòhánù dá wọn lóhùn, pé: “Mo ń batisí nínú omi. Ní àárín+ yín, ẹnì kan wà ní ìdúró tí ẹ kò mọ̀,+ 27  ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi, ṣùgbọ́n okùn sálúbàtà ẹni tí èmi kò tóó tú.”+ 28  Nǹkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ ní Bẹ́tánì ní òdì-kejì Jọ́dánì, níbi tí Jòhánù ti ń batisí.+ 29  Ní ọjọ́ kejì, ó rí tí Jésù ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé: “Wò ó, Ọ̀dọ́ Àgùntàn+ Ọlọ́run, tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀+ ayé lọ!+ 30  Èyí ni ẹni náà nípa ẹni tí mo wí pé, Lẹ́yìn mi, ọkùnrin kan ń bọ̀ tí ó ti lọ jìnnà níwájú mi, nítorí tí ó wà ṣáájú mi.+ 31  Èmi pàápàá kò mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n ìdí tí mo fi wá ń batisí nínú omi ni pé kí a lè fi í hàn kedere fún Ísírẹ́lì.”+ 32  Jòhánù tún jẹ́rìí, pé: “Mo rí tí ẹ̀mí ń sọ kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àdàbà láti ọ̀run, ó sì bà lé e.+ 33  Èmi pàápàá kò mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n Ẹni náà gan-an tí ó rán mi+ láti batisí nínú omi sọ fún mi pé, ‘Ẹnì yòówù tí o bá rí tí ẹ̀mí ń sọ kalẹ̀ lé, tí ó sì dúró, èyí ni ẹni tí ń fi ẹ̀mí mímọ́ batisí.’+ 34  Mo sì ti rí i, mo sì ti jẹ́rìí pé ẹni yìí ni Ọmọ Ọlọ́run.”+ 35  Ẹ̀wẹ̀, ní ọjọ́ kejì, Jòhánù wà ní ìdúró pẹ̀lú méjì lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, 36  bí ó sì ti wo Jésù tí ó ń rìn, ó wí pé: “Wò ó, Ọ̀dọ́ Àgùntàn+ Ọlọ́run!” 37  Àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjèèjì náà sì gbọ́ bí ó ti sọ̀rọ̀, wọ́n sì tẹ̀ lé Jésù. 38  Nígbà náà, Jésù yí padà, bí ó sì ti rí tí wọ́n ń tẹ̀ lé òun, ó wí fún wọn pé: “Kí ni ẹ ń wá?” Wọ́n wí fún un pé: “Rábì, (èyí tí ó túmọ̀ sí Olùkọ́, nígbà tí a bá túmọ̀ rẹ̀,) ibo ni o ń gbé?” 39  Ó wí fún wọn pé: “Ẹ wá, ẹ ó sì rí i.”+ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, wọ́n lọ, wọ́n sì rí ibi tí ó ń gbé, wọ́n sì bá a gbé ní ọjọ́ yẹn; ó jẹ́ nǹkan bí wákàtí kẹwàá. 40  Áńdérù+ arákùnrin Símónì Pétérù jẹ́ ọ̀kan lára àwọn méjì tí wọ́n gbọ́ ohun tí Jòhánù sọ, tí wọ́n sì tẹ̀ lé Jésù. 41  Lákọ̀ọ́kọ́, ẹni yìí rí arákùnrin tirẹ̀, Símónì, ó sì wí fún un pé: “Àwa ti rí Mèsáyà náà”+ (èyí tí ó túmọ̀ sí Kristi,+ nígbà tí a bá túmọ̀ rẹ̀). 42  Ó mú un lọ sọ́dọ̀ Jésù. Nígbà tí Jésù wò ó,+ ó wí pé: “Ìwọ ni Símónì+ ọmọkùnrin Jòhánù;+ a óò máa pè ọ́ ní Kéfà” (èyí tí a túmọ̀ sí Pétérù).+ 43  Ní ọjọ́ kejì, ó fẹ́ láti jáde lọ sí Gálílì. Bẹ́ẹ̀ ni Jésù rí Fílípì,+ ó sì wí fún un pé: “Di ọmọlẹ́yìn mi.”+ 44  Wàyí o, Fílípì wá láti Bẹtisáídà,+ láti ìlú ńlá Áńdérù àti Pétérù. 45  Fílípì rí Nàtáníẹ́lì,+ ó sì wí fún un pé: “Àwa ti rí ẹni tí Mósè, nínú Òfin,+ àti àwọn Wòlíì+ kọ̀wé nípa rẹ̀, Jésù, ọmọkùnrin Jósẹ́fù,+ láti Násárétì.” 46  Ṣùgbọ́n Nàtáníẹ́lì wí fún un pé: “Ohun rere kankan ha lè jáde wá láti Násárétì bí?”+ Fílípì wí fún un pé: “Wá wò ó.” 47  Jésù rí tí Nàtáníẹ́lì ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí nípa rẹ̀ pé: “Wò ó, ọmọ Ísírẹ́lì kan dájúdájú, nínú ẹni tí ẹ̀tàn kankan kò sí.”+ 48  Nàtáníẹ́lì wí fún un pé: “Báwo ni ó ṣe ṣẹlẹ̀ pé o mọ̀ mí?” Jésù ní ìdáhùn wí fún un pé: “Kí Fílípì tó pè ọ́, nígbà tí ìwọ wà lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́, mo ti rí ọ.” 49  Nàtáníẹ́lì dá a lóhùn pé: “Rábì, ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run,+ ìwọ ni Ọba+ Ísírẹ́lì.” 50  Jésù ní ìdáhùn wí fún un pé: “Ṣé nítorí mo sọ fún ọ pé mo rí ọ lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ ni o fi gbà gbọ́? Ìwọ yóò rí àwọn ohun tí ó tóbi ju ìwọ̀nyí lọ.” 51  Ó wí fún un síwájú sí i pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹ óò rí tí ọ̀run ṣí sílẹ̀, tí àwọn áńgẹ́lì+ Ọlọ́run ń gòkè, tí wọ́n sì ń sọ kalẹ̀ sọ́dọ̀ Ọmọ ènìyàn.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé