Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jẹ́nẹ́sísì 9:1-29

9  Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti súre fún Nóà àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé.+  Ìbẹ̀rù yín àti ìpayà yín yóò sì máa wà lára gbogbo ẹ̀dá alààyè ilẹ̀ ayé àti lára gbogbo ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run, lára ohun gbogbo tí ń rìn lórí ilẹ̀, àti lára gbogbo ẹja inú òkun. Ọwọ́ yín ni a fi wọ́n lé nísinsìnyí.+  Gbogbo ẹran tí ń rìn, tí ó wà láàyè, lè jẹ́ oúnjẹ fún yín.+ Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ti ewéko tútù yọ̀yọ̀, mo fi gbogbo rẹ̀ fún yín ní ti gidi.+  Kìkì ẹran pẹ̀lú ọkàn+ rẹ̀—ẹ̀jẹ̀+ rẹ̀—ni ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ.+  Àti pé, ní àfikún sí ìyẹn, ẹ̀jẹ̀ yín ti ọkàn yín ni èmi yóò béèrè padà. Lọ́wọ́ olúkúlùkù ẹ̀dá alààyè ni èmi yóò ti béèrè rẹ̀ padà; àti lọ́wọ́ ènìyàn, lọ́wọ́ olúkúlùkù ẹni tí ó jẹ́ arákùnrin rẹ̀, ni èmi yóò ti béèrè ọkàn ènìyàn padà.+  Ẹnikẹ́ni tí ó bá ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀, láti ọwọ́ ènìyàn ni a ó ti ta ẹ̀jẹ̀ tirẹ̀ sílẹ̀,+ nítorí ní àwòrán Ọlọ́run ni ó ṣe ènìyàn.  Àti ní tiyín, ẹ máa so èso kí ẹ sì di púpọ̀, ẹ máa gbá yìn-ìn lórí ilẹ̀ ayé kí ẹ sì di púpọ̀ nínú rẹ̀.”+  Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti wí fún Nóà àti fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ pé:  “Àti ní tèmi, kíyè sí i, èmi ń fìdí májẹ̀mú+ mi múlẹ̀ pẹ̀lú yín àti pẹ̀lú ọmọ yín lẹ́yìn yín,+ 10  àti pẹ̀lú gbogbo alààyè ọkàn tí ó wà pẹ̀lú yín, nínú àwọn ẹ̀dá abìyẹ́, nínú àwọn ẹranko àti nínú gbogbo ẹ̀dá alààyè orí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú yín, láti orí gbogbo àwọn tí ó jáde kúrò nínú áàkì títí dórí gbogbo ẹ̀dá alààyè orí ilẹ̀ ayé.+ 11  Bẹ́ẹ̀ ni, mo fìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ ní ti gidi pẹ̀lú yín: A kì yóò fi àkúnya omi ké gbogbo ẹran ara kúrò mọ́, àkúnya omi kì yóò sì ṣẹlẹ̀ mọ́ láti run ilẹ̀ ayé.”+ 12  Ọlọ́run sì fi kún un pé: “Èyí ni àmì+ májẹ̀mú tí mo ń dá láàárín èmi àti ẹ̀yin àti gbogbo alààyè ọkàn tí ó wà pẹ̀lú yín, ní ìran-ìran fún àkókò tí ó lọ kánrin. 13  Òṣùmàrè+ mi ni mo fi sí àwọsánmà, yóò sì jẹ́ àmì májẹ̀mú láàárín èmi àti ilẹ̀ ayé. 14  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí mo bá mú àwọsánmà wá sórí ilẹ̀ ayé, nígbà náà, òṣùmàrè yóò fara hàn dájúdájú ní àwọsánmà. 15  Èmi yóò sì rántí májẹ̀mú+ mi dájúdájú, èyí tí ń bẹ láàárín èmi àti ẹ̀yin àti gbogbo alààyè ọkàn láàárín gbogbo ẹran ara;+ omi kì yóò sì di àkúnya omi mọ́ láti run+ gbogbo ẹran ara. 16  Òṣùmàrè yóò sì yọ ní àwọsánmà,+ dájúdájú, èmi yóò sì rí i láti rántí májẹ̀mú náà fún àkókò tí ó lọ kánrin+ láàárín Ọlọ́run àti gbogbo alààyè ọkàn nínú gbogbo ẹran ara tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé.”+ 17  Ọlọ́run sì tún un wí fún Nóà pé: “Èyí ni àmì májẹ̀mú náà tí mo fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ní ti gidi láàárín èmi àti gbogbo ẹran ara tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé.”+ 18  Àwọn ọmọkùnrin Nóà+ tí wọ́n jáde kúrò nínú áàkì ni Ṣémù àti Hámù àti Jáfẹ́tì. Lẹ́yìn náà, Hámù ni baba Kénáánì.+ 19  Àwọn mẹ́ta wọ̀nyí ni ọmọkùnrin Nóà, láti ọ̀dọ̀ àwọn wọ̀nyí sì ni gbogbo iye àwọn ènìyàn orí ilẹ̀ ayé ti tàn káàkiri.+ 20  Wàyí o, Nóà bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àgbẹ̀,+ ó sì tẹ̀ síwájú láti gbin ọgbà àjàrà kan.+ 21  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mu lára wáìnì náà, ọtí sì ń pa á,+ nípa bẹ́ẹ̀ ó tú ara rẹ̀ sí ìhòòhò ní àárín àgọ́ rẹ̀. 22  Lẹ́yìn náà, Hámù+ baba Kénáánì rí ìhòòhò baba rẹ̀,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ méjèèjì ní òde.+ 23  Látàrí ìyẹn, Ṣémù àti Jáfẹ́tì mú aṣọ àlàbora kan,+ àwọn méjèèjì sì fi lé èjìká wọn, wọ́n sì fi ẹ̀yìn rìn wọlé. Wọ́n tipa báyìí bo ìhòòhò baba wọn, bí ojú wọn ti wà ní yíyíkúrò, wọn kò sì rí ìhòòhò baba wọn.+ 24  Níkẹyìn, Nóà jí kúrò nínú wáìnì rẹ̀, ó sì wá mọ ohun tí ọmọkùnrin rẹ̀ tí ó kéré jù lọ ṣe sí i. 25  Látàrí èyí, ó sọ pé: “Ègún ni fún Kénáánì.+ Kí ó di ẹrú tí ó rẹlẹ̀ jù lọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀.”+ 26  Ó sì fi kún un pé: “Ìbùkún ni fún Jèhófà,+ Ọlọ́run Ṣémù, Kí Kénáánì sì di ẹrú fún un.+ 27  Kí Ọlọ́run fún Jáfẹ́tì ní àyè fífẹ̀ tó, Kí ó sì máa gbé inú àwọn àgọ́ Ṣémù.+ Kí Kénáánì di ẹrú fún un pẹ̀lú.” 28  Nóà sì ń bá a lọ láti wà láàyè fún àádọ́ta-dín-nírínwó ọdún lẹ́yìn àkúnya omi.+ 29  Nítorí náà, gbogbo ọjọ́ Nóà jẹ́ àádọ́ta-dín-lẹ́gbẹ̀rún ọdún, ó sì kú.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé