Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jẹ́nẹ́sísì 8:1-22

8  Lẹ́yìn ìyẹn, Ọlọ́run rántí+ Nóà àti gbogbo ẹranko ìgbẹ́ àti gbogbo ẹran agbéléjẹ̀ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú áàkì,+ Ọlọ́run sì mú kí ẹ̀fúùfù kọjá lórí ilẹ̀ ayé, omi náà sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ sílẹ̀.+  A sì sé àwọn ìsun ibú omi+ àti àwọn ibodè ibú omi+ ojú ọ̀run pa, eji wọwọ láti ojú ọ̀run sì tipa bẹ́ẹ̀ dá.  Omi náà sì bẹ̀rẹ̀ sí fọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ni ó ń fọn; àti ní òpin àádọ́jọ ọjọ́, omi náà ti dínkù.+  Ní oṣù keje, ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù, áàkì+ náà sì wá gúnlẹ̀ sórí òkè ńlá Árárátì.+  Omi náà sì ń bá a nìṣó láti dínkù ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ títí di oṣù kẹwàá. Ní oṣù kẹwàá, ní ọjọ́ kìíní oṣù, téńté àwọn òkè ńlá fara hàn.+  Nítorí náà, ó ṣẹlẹ̀ pé, ní òpin ogójì ọjọ́, Nóà tẹ̀ síwájú láti ṣí fèrèsé+ áàkì náà tí ó ti ṣe.  Lẹ́yìn ìyẹn, ó rán ẹyẹ ìwò+ kan jáde, ó sì ń bá a lọ láti fò lóde, ó ń lọ, ó sì ń padà, títí di ìgbà tí omi náà fi gbẹ kúrò lórí ilẹ̀ ayé.  Lẹ́yìn náà, ó rán àdàbà+ kan jáde láti ọ̀dọ̀ ara rẹ̀, láti rí i bóyá omi náà ti fà kúrò ní orí ilẹ̀.  Àdàbà náà kò sì rí ibi ìsinmi fún àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀, nítorí náà, ó padà sọ́dọ̀ rẹ̀ nínú áàkì nítorí pé omi náà ṣì wà ní orí gbogbo ilẹ̀ ayé.+ Látàrí èyí, ó na ọwọ́ rẹ̀ jáde, ó sì mú un, ó sì mú un wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ nínú áàkì. 10  Ó sì ń bá a lọ láti dúró fún ọjọ́ méje mìíràn sí i, ó sì tún rán àdàbà náà jáde láti inú áàkì lẹ́ẹ̀kan sí i. 11  Lẹ́yìn náà, àdàbà náà wá bá a ní nǹkan bí àkókò ìrọ̀lẹ́, sì wò ó! ewé ólífì+ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ já wà ní àgógó rẹ̀, Nóà sì tipa bẹ́ẹ̀ wá mọ̀ pé omi náà ti fà kúrò ní ilẹ̀ ayé.+ 12  Ó sì ń bá a lọ láti dúró fún ọjọ́ méje mìíràn sí i. Lẹ́yìn náà, ó rán àdàbà náà jáde, ṣùgbọ́n kò tún padà wá sọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́ rárá.+ 13  Wàyí o, ní ọdún kọkàn-lé-lẹ́gbẹ̀ta,+ ní oṣù kìíní, ní ọjọ́ kìíní oṣù, ó ṣẹlẹ̀ pé omi náà ti fà kúrò ní ilẹ̀ ayé; Nóà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣí ìbòrí áàkì kúrò, ó sì wò, sì kíyè sí i, orí ilẹ̀ ti gbẹ.+ 14  Ní oṣù kejì, ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù, ilẹ̀ ayé sì ti gbẹ tán.+ 15  Wàyí o, Ọlọ́run bá Nóà sọ̀rọ̀, pé: 16  “Jáde kúrò nínú áàkì, ìwọ àti aya rẹ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ àti aya àwọn ọmọkùnrin rẹ pẹ̀lú rẹ.+ 17  Gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó jẹ́ onírúurú ẹran ara+ tí ó wà pẹ̀lú rẹ, nínú àwọn ẹ̀dá tí ń fò+ àti nínú àwọn ẹranko+ àti nínú gbogbo ẹran tí ń rìn ká, tí ń rìn lórí ilẹ̀ ayé,+ ni kí o mú jáde pẹ̀lú rẹ, bí ó ti jẹ́ pé wọn yóò máa gbá yìn-ìn ní ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa so èso, wọn yóò sì di púpọ̀ lórí ilẹ̀ ayé.”+ 18  Látàrí èyí, Nóà jáde, àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀+ pẹ̀lú àti aya rẹ̀ àti aya àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀. 19  Gbogbo ẹ̀dá alààyè, gbogbo ẹran tí ń rìn àti gbogbo ẹ̀dá tí ń fò, olúkúlùkù ohun tí ń rìn lórí ilẹ̀ ayé, ní ìbámu pẹ̀lú ìdílé wọn ni wọ́n jáde kúrò nínú áàkì.+ 20  Nóà sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ pẹpẹ+ kan fún Jèhófà, ó sì mú díẹ̀ lára gbogbo ẹranko tí ó mọ́+ àti lára gbogbo àwọn ẹ̀dá tí ń fò tí ó mọ́,+ ó sì rú ọrẹ ẹbọ sísun lórí pẹpẹ+ náà. 21  Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ òórùn amáratuni,+ nítorí náà, Jèhófà wí nínú ọkàn-àyà+ rẹ̀ pé: “Èmi kì yóò tún pe ibi wá sórí ilẹ̀+ ní tìtorí ènìyàn mọ́ láé, nítorí pé ìtẹ̀sí+ èrò ọkàn-àyà ènìyàn jẹ́ búburú láti ìgbà èwe rẹ̀ wá;+ èmi kì yóò sì tún mú ìyọnu àgbálù bá gbogbo ohun alààyè mọ́, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe.+ 22  Ní gbogbo ọjọ́ tí ilẹ̀ ayé yóò máa bá a lọ ní wíwà, fífún irúgbìn àti ìkórè, àti òtútù àti ooru, àti ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òtútù, àti ọ̀sán àti òru, kì yóò kásẹ̀ nílẹ̀ láé.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé