Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jẹ́nẹ́sísì 7:1-24

7  Lẹ́yìn ìyẹn, Jèhófà sọ fún Nóà pé: “Lọ, ìwọ àti gbogbo agbo ilé+ rẹ, sínú áàkì náà, nítorí ìwọ ni mo rí pé ó jẹ́ olódodo níwájú mi nínú ìran yìí.+  Nínú gbogbo ẹranko tí ó mọ́, kí ìwọ mú méje-méje sọ́dọ̀ ara rẹ, àgbà-akọ àti abo rẹ̀;+ àti méjì péré láti inú gbogbo ẹranko tí kò mọ́, àgbà-akọ àti abo rẹ̀;  àti nínú àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run, méje-méje, akọ àti abo,+ láti pa ọmọ mọ́ láàyè lórí gbogbo ilẹ̀ ayé+ pátá.  Nítorí ní ọjọ́ méje péré sí i, èmi yóò mú kí òjò rọ̀+ sórí ilẹ̀ ayé fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru;+ èmi yóò sì nu gbogbo ohun tí ó wà tí mo ti ṣe kúrò ní orí ilẹ̀.”+  Nóà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Jèhófà ti pa láṣẹ fún un.  Nóà sì jẹ́ ẹni ẹgbẹ̀ta ọdún nígbà tí àkúnya omi ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé.+  Nítorí náà, Nóà wọlé, àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti aya rẹ̀ àti aya àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, sínú áàkì náà ṣáájú omi àkúnya+ náà.  Lára gbogbo ẹranko tí ó mọ́ àti lára gbogbo ẹranko tí kò mọ́ àti lára àwọn ẹ̀dá tí ń fò àti ohun gbogbo tí ń rìn lórí ilẹ̀,+  wọ́n wọlé ní méjì-méjì lọ bá Nóà nínú áàkì náà, akọ àti abo, gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún Nóà. 10  Ní ọjọ́ méje lẹ́yìn náà, ó wá ṣẹlẹ̀ pé omi àkúnya náà dé sórí ilẹ̀ ayé. 11  Ní ẹgbẹ̀ta ọdún ìwàláàyè Nóà, ní oṣù kejì, ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù, ní ọjọ́ yìí, gbogbo ìsun alagbalúgbú ibú omi ya, àwọn ibodè ibú omi ọ̀run sì ṣí.+ 12  Eji wọwọ lórí ilẹ̀ ayé sì ń bá a lọ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru.+ 13  Ní ọjọ́ yìí gan-an, Nóà wọlé sínú áàkì+ náà, Ṣémù àti Hámù àti Jáfẹ́tì, àwọn ọmọkùnrin Nóà,+ àti aya Nóà àti aya mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ̀; 14  àwọn àti gbogbo ẹranko ìgbẹ́ ní irú tirẹ̀,+ àti gbogbo ẹran agbéléjẹ̀ ní irú tirẹ̀, àti gbogbo ẹran tí ń rìn ká, tí ń rìn lórí ilẹ̀ ayé, ní irú tirẹ̀,+ àti gbogbo ẹ̀dá tí ń fò ní irú tirẹ̀,+ gbogbo ẹyẹ, gbogbo ẹ̀dá abìyẹ́lápá.+ 15  Wọ́n sì ń lọ bá Nóà nínú áàkì náà, ní méjì-méjì, nínú gbogbo onírúurú ẹran, nínú èyí tí ipá ìyè ń ṣiṣẹ́.+ 16  Àwọn tí ó sì ń wọlé, akọ àti abo nínú gbogbo onírúurú ẹran, wọlé, gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún un. Lẹ́yìn ìyẹn, Jèhófà ti ilẹ̀kùn mọ́ ọn.+ 17  Àkúnya omi náà sì ń bá a lọ fún ogójì ọjọ́ lórí ilẹ̀ ayé, omi náà sì ń pọ̀ sí i, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé áàkì náà, ó sì léfòó lókè ilẹ̀ ayé. 18  Omi náà kún bolẹ̀, ó sì ń pọ̀ sí i lọ́pọ̀lọ́pọ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ṣùgbọ́n áàkì náà ń lọ lójú omi.+ 19  Omi náà sì kún bo ilẹ̀ ayé mọ́lẹ̀ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí gbogbo òkè ńlá gíga lábẹ́ gbogbo ọ̀run fi wá di èyí tí a bò mọ́lẹ̀.+ 20  Títí dé ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ni omi náà fi kún bò wọ́n mọ́lẹ̀, àwọn òkè ńlá sì di bíbò mọ́lẹ̀.+ 21  Nítorí náà, gbogbo ẹran tí ń rìn lórí ilẹ̀ ayé gbẹ́mìí mì,+ nínú àwọn ẹ̀dá tí ń fò àti nínú àwọn ẹran agbéléjẹ̀ àti nínú àwọn ẹranko ìgbẹ́ àti nínú gbogbo àwọn ohun agbáyìn-ìn tí ń gbá yìn-ìn lórí ilẹ̀ ayé, àti gbogbo aráyé.+ 22  Ohun gbogbo tí èémí ipá ìwàláàyè ń ṣiṣẹ́ ní ihò imú rẹ̀ kú, èyíinì ni, gbogbo ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ gbígbẹ.+ 23  Nípa báyìí, ó nu gbogbo ohun tí ó wà lórí ilẹ̀ kúrò, láti orí ènìyàn dórí ẹranko, dórí ẹran tí ń rìn àti dórí ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run, a sì nù wọ́n kúrò lórí ilẹ̀ ayé;+ kìkì Nóà àti àwọn tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú áàkì ni wọ́n ń bá a nìṣó láti wà láàyè.+ 24  Omi náà sì ń bá a lọ ní kíkún bo ilẹ̀ ayé fún àádọ́jọ ọjọ́.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé