Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jẹ́nẹ́sísì 50:1-26

50  Nígbà náà ni Jósẹ́fù ṣubú lé baba rẹ̀ lójú,+ ó sì bú sẹ́kún lórí rẹ̀, ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu.+  Lẹ́yìn náà, Jósẹ́fù pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn oníṣègùn, pé kí wọ́n kun baba òun lọ́ṣẹ.+ Nítorí náà, àwọn oníṣègùn náà kun Ísírẹ́lì lọ́ṣẹ.  Wọ́n sì lo ogójì ọjọ́ gbáko fún un, nítorí ọjọ́ púpọ̀ bí èyí ni wọ́n máa ń lò gẹ́gẹ́ bí àṣà fún kíkun òkú lọ́ṣẹ, àwọn ará Íjíbítì sì ń bá a lọ láti sunkún rẹ̀ fún àádọ́rin ọjọ́.+  Níkẹyìn, àwọn ọjọ́ sísunkún fún un kọjá, Jósẹ́fù sì bá agbo ilé Fáráò sọ̀rọ̀, pé: “Wàyí o, bí mo bá ti rí ojú rere ní ojú yín,+ ẹ jọ̀wọ́, ẹ sọ̀rọ̀ ní etí-ìgbọ́ Fáráò pé,  ‘Baba mi mú kí n búra,+ pé: “Wò ó! èmi ń kú lọ.+ Inú ibi ìsìnkú mi tí mo ti gbẹ́ fún ara mi ní ilẹ̀ Kénáánì+ ni kí o sin mí sí.”+ Wàyí o, jọ̀wọ́, jẹ́ kí n gòkè lọ, kí n sì sin baba mi, lẹ́yìn èyí, èmi ṣe tán láti padà.’”  Nítorí náà, Fáráò wí pé: “Gòkè lọ, kí o sì sin baba rẹ, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti mú kí o búra.”+  Nítorí náà, Jósẹ́fù gòkè lọ láti sin baba rẹ̀, gbogbo ìránṣẹ́ Fáráò, àwọn àgbà ọkùnrin+ agbo ilé rẹ̀ àti gbogbo àgbà ọkùnrin ilẹ̀ Íjíbítì sì bá a gòkè lọ,  àti gbogbo agbo ilé Jósẹ́fù àti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti agbo ilé baba rẹ̀.+ Kìkì àwọn ọmọ wọn kéékèèké àti àwọn agbo ẹran wọn àti àwọn ọ̀wọ́ ẹran wọn ni wọ́n fi sílẹ̀ ní ilẹ̀ Góṣénì.  Àwọn ẹlẹ́ṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin+ tún bá a gòkè lọ, ibùdó náà sì pọ̀ níye gidigidi. 10  Lẹ́yìn náà, wọ́n dé ilẹ̀ ìpakà+ Átádì, tí ó wà ní ẹkùn ilẹ̀ Jọ́dánì,+ ibẹ̀ ni wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ ìpohùnréré ẹkún tí ó pọ̀ gidigidi tí ó sì bùáyà, ó sì ń bá ààtò ọ̀fọ̀ baba rẹ̀ nìṣó fún ọjọ́ méje.+ 11  Àwọn olùgbé ilẹ̀ náà, àwọn ọmọ Kénáánì, sì rí ààtò ọ̀fọ̀ náà ní ilẹ̀ ìpakà Átádì, wọ́n sì fi ìyàlẹ́nu sọ pé: “Ọ̀fọ̀ bíbùáyà ni èyí jẹ́ fún àwọn ará Íjíbítì!” Ìdí nìyẹn tí a fi pe orúkọ rẹ̀ ní Ebẹli-mísíráímù, èyí tí ó wà ní ẹkùn ilẹ̀ Jọ́dánì.+ 12  Àwọn ọmọ rẹ̀ sì ń bá a lọ láti ṣe fún un gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pàṣẹ fún wọn.+ 13  Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ rẹ̀ gbé e lọ sí ilẹ̀ Kénáánì, wọ́n sì sin ín sínú hòrò pápá Mákípẹ́là, pápá tí Ábúráhámù rà ní ọwọ́ Éfúrónì ọmọ Hétì ní iwájú Mámúrè+ gẹ́gẹ́ bí ohun ìní láti fi sìnkú. 14  Lẹ́yìn ìgbà náà, Jósẹ́fù padà sí Íjíbítì, òun àti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo àwọn tí ó bá a gòkè lọ láti sin baba rẹ̀, lẹ́yìn tí ó ti sin baba rẹ̀. 15  Nígbà tí àwọn arákùnrin Jósẹ́fù rí i pé baba àwọn ti kú, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Ó lè jẹ́ pé Jósẹ́fù ń dì wá sínú,+ tí ó sì dájú pé òun yóò san án padà fún wa nítorí gbogbo ibi tí a ṣe sí i.”+ 16  Nítorí náà, wọ́n sọ fún Jósẹ́fù nípa àṣẹ kan ní ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Baba rẹ pàṣẹ ṣáájú ikú rẹ̀, pé, 17  ‘Èyí ni kí ẹ sọ fún Jósẹ́fù pé: “Mo fi taratara bẹ̀ ọ́, jọ̀wọ́, dárí ìdìtẹ̀ àwọn arákùnrin rẹ jì+ àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ní ti pé wọ́n ṣe ibi sí ọ.”’+ Wàyí o, jọ̀wọ́, dárí ìdìtẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run baba rẹ jì.”+ Jósẹ́fù sì bú sẹ́kún nígbà tí wọ́n bá a sọ̀rọ̀. 18  Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn arákùnrin rẹ̀ tún wa, wọ́n sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n sì wí pé: “Àwa rèé bí ẹrú rẹ!”+ 19  Nígbà náà ni Jósẹ́fù wí fún wọn pé: “Ẹ má fòyà, nítorí èmi ha wà ní ipò Ọlọ́run bí?+ 20  Ní tiyín, ẹ ní ibi lọ́kàn sí mi. Ọlọ́run ní in lọ́kàn fún rere, fún ète ṣíṣe gẹ́gẹ́ bí ti òní yìí, láti pa àwọn ènìyàn púpọ̀ mọ́ láàyè.+ 21  Ǹjẹ́ nísinsìnyí, ẹ má fòyà. Èmi fúnra mi yóò máa pèsè oúnjẹ fún ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín kéékèèké.”+ Nípa báyìí, ó tù wọ́n nínú, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà ìfinilọ́kànbalẹ̀. 22  Jósẹ́fù sì ń bá a lọ láti gbé ní Íjíbítì, òun àti ilé baba rẹ̀; Jósẹ́fù sì wà láàyè fún àádọ́fà ọdún. 23  Jósẹ́fù sì rí àwọn ọmọ Éfúráímù ti ìran kẹta,+ àti àwọn ọmọ Mákírù,+ tí ó jẹ́ ọmọkùnrin Mánásè. Orí eékún Jósẹ́fù ni a bí wọn sí.+ 24  Níkẹyìn, Jósẹ́fù wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé: “Èmi ń kú lọ; ṣùgbọ́n, láìkùnà, Ọlọ́run yóò yí àfiyèsí rẹ̀ sí yín,+ dájúdájú, òun yóò mú yín gòkè kúrò ní ilẹ̀ yìí, lọ sí ilẹ̀ tí ó búra nípa rẹ̀ fún Ábúráhámù, fún Ísákì àti fún Jékọ́bù.”+ 25  Nítorí náà, Jósẹ́fù mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì búra pé: “Láìkùnà, Ọlọ́run yóò yí àfiyèsí rẹ̀ sí yín. Nítorí náà, kí ẹ kó egungun mi gòkè kúrò níhìn-ín.”+ 26  Lẹ́yìn ìyẹn, Jósẹ́fù kú ní ẹni àádọ́fà ọdún; wọ́n sì kùn ún lọ́ṣẹ,+ wọ́n sì gbé e sínú pósí ní Íjíbítì.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé