Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jẹ́nẹ́sísì 5:1-32

5  Èyí ni ìwé ọ̀rọ̀-ìtàn nípa Ádámù. Ní ọjọ́ tí Ọlọ́run dá Ádámù, ó ṣe é ní ìrí Ọlọ́run.+  Akọ àti abo ni ó dá wọn.+ Lẹ́yìn èyíinì, ó súre fún wọn, ó sì pe orúkọ wọn ní Ènìyàn+ ní ọjọ́ dídá wọn.+  Ádámù sì ń bá a nìṣó láti wà láàyè fún àádóje ọdún. Lẹ́yìn náà, ó bí ọmọkùnrin kan ní ìrí rẹ̀, ní àwòrán rẹ̀, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Sẹ́ẹ̀tì.+  Àwọn ọjọ́ Ádámù lẹ́yìn tí ó bí Sẹ́ẹ̀tì wá jẹ́ ẹgbẹ̀rin ọdún. Láàárín àkókò náà, ó bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin.+  Nítorí náà, gbogbo ọjọ́ Ádámù tí ó fi wà láàyè jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé ọgbọ̀n, ó sì kú.+  Sẹ́ẹ̀tì sì ń bá a nìṣó láti wà láàyè fún ọdún márùnlé-lọ́gọ́rùn-ún. Lẹ́yìn náà, ó bí Énọ́ṣì.+  Lẹ́yìn tí ó sì bí Énọ́ṣì, Sẹ́ẹ̀tì ń bá a lọ láti wà láàyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún ó lé méje. Láàárín àkókò náà, ó bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin.  Nítorí náà, gbogbo ọjọ́ Sẹ́ẹ̀tì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé méjìlá, ó sì kú.  Énọ́ṣì sì ń bá a nìṣó láti wà láàyè fún àádọ́rùn-ún ọdún. Lẹ́yìn náà, ó bí Kénánù.+ 10  Lẹ́yìn tí ó sì bí Kénánù, Énọ́ṣì ń bá a lọ láti wà láàyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Láàárín àkókò náà, ó bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin. 11  Nítorí náà, gbogbo ọjọ́ Énọ́ṣì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé márùn-ún, ó sì kú. 12  Kénánù sì ń bá a nìṣó láti wà láàyè fún àádọ́rin ọdún. Lẹ́yìn náà, ó bí Máhálálélì.+ 13  Lẹ́yìn tí ó sì bí Máhálálélì, Kénánù ń bá a lọ láti wà láàyè fún òjì-lé-lẹ́gbẹ̀rin ọdún. Láàárín àkókò náà, ó bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin. 14  Nítorí náà, gbogbo ọjọ́ Kénánù jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé mẹ́wàá, ó sì kú. 15  Máhálálélì sì ń bá a nìṣó láti wà láàyè fún ọdún márùn-dín-láàádọ́rin. Lẹ́yìn náà, ó bí Járédì.+ 16  Lẹ́yìn tí ó sì bí Járédì, Máhálálélì ń bá a lọ láti wà láàyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún ó lé ọgbọ̀n. Láàárín àkókò náà, ó bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin. 17  Nítorí náà, gbogbo ọjọ́ Máhálálélì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó dín márùn-ún, ó sì kú. 18  Járédì sì ń bá a nìṣó láti wà láàyè fún ọdún méjìlélọ́gọ́jọ. Lẹ́yìn náà, ó bí Énọ́kù.+ 19  Lẹ́yìn tí ó sì bí Énọ́kù, Járédì ń bá a lọ láti wà láàyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún. Láàárín àkókò náà, ó bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin. 20  Nítorí náà, gbogbo ọjọ́ Járédì jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún ó dín méjìdínlógójì, ó sì kú. 21  Énọ́kù sì ń bá a nìṣó láti wà láàyè fún ọdún márùn-dín-láàádọ́rin. Lẹ́yìn náà, ó bí Mètúsélà.+ 22  Lẹ́yìn tí ó sì bí Mètúsélà, Énọ́kù ń bá a lọ ní rírìn pẹ̀lú Ọlọ́run tòótọ́ fún ọ̀ọ́dúnrún ọdún. Láàárín àkókò náà, ó bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin. 23  Nítorí náà, gbogbo ọjọ́ Énọ́kù jẹ́ òjì-dín-nírínwó ọdún ó lé márùn-ún. 24  Énọ́kù sì ń bá a nìṣó ní rírìn+ pẹ̀lú Ọlọ́run tòótọ́.+ Lẹ́yìn náà, òun kò sì sí mọ́, nítorí tí Ọlọ́run mú un lọ.+ 25  Mètúsélà sì ń bá a nìṣó láti wà láàyè fún ọgọ́sàn-án ọdún ó lé méje. Lẹ́yìn náà, ó bí Lámékì.+ 26  Lẹ́yìn tí ó sì bí Lámékì, Mètúsélà ń bá a lọ láti wà láàyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún ó dín méjìdínlógún. Láàárín àkókò náà, ó bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin. 27  Nítorí náà, gbogbo ọjọ́ Mètúsélà jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún ó dín mọ́kànlélọ́gbọ̀n, ó sì kú. 28  Lámékì sì ń bá a nìṣó láti wà láàyè fún ọdún méjì-lé-lọ́gọ́sàn-án. Lẹ́yìn náà, ó bí ọmọkùnrin kan. 29  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pe orúkọ rẹ̀ ní Nóà,+ pé: “Ẹni yìí ni yóò mú ìtùnú wá fún wa nínú iṣẹ́ wa àti nínú ìrora ọwọ́ wa tí ó jẹ́ àbáyọrí ilẹ̀ tí Jèhófà ti fi gégùn-ún.”+ 30  Lẹ́yìn tí ó sì bí Nóà, Lámékì ń bá a lọ láti wà láàyè fún ẹgbẹ̀ta ọdún ó dín márùn-ún. Láàárín àkókò náà, ó bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin. 31  Nítorí náà, gbogbo ọjọ́ Lámékì jẹ́ ẹgbẹ̀rin ọdún ó dín mẹ́tàlélógún, ó sì kú. 32  Nóà sì di ẹni ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún. Lẹ́yìn ìyẹn, Nóà bí Ṣémù,+ Hámù+ àti Jáfẹ́tì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé