Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jẹ́nẹ́sísì 49:1-33

49  Lẹ́yìn náà, Jékọ́bù pe àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, ó sì wí pé: “Ẹ kó ara yín jọpọ̀, kí n lè sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí yín ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́.  Ẹ pe ara yín jọ, kí ẹ sì fetí sílẹ̀, ẹ̀yin ọmọkùnrin Jékọ́bù, bẹ́ẹ̀ ni, ẹ fetí sí Ísírẹ́lì baba yín.+  “Rúbẹ́nì, ìwọ ni àkọ́bí mi,+ okun inú mi àti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ agbára ìbímọ mi,+ ìtayọ iyì àti ìtayọ okun.  Pẹ̀lú òmìnira oníwàdùwàdù bí omi, kí ìwọ má ṣe ta yọ,+ nítorí tí o ti gun orí ibùsùn baba rẹ.+ Ní àkókò yẹn, o sọ àga ìrọ̀gbọ̀kú gbọọrọ mi di aláìmọ́.+ Ó gun orí rẹ̀!  “Síméónì àti Léfì jẹ́ tẹ̀gbọ́n-tàbúrò.+ Ohun èlò ìwà ipá ni ohun ìjà ìpani wọn.+  Inú àwùjọ tímọ́tímọ́ wọn ni kí o má ṣe dé,+ ìwọ ọkàn mi. Má ṣe bá ìpéjọ wọn so pọ̀ ṣọ̀kan,+ ìwọ ìtẹ̀sí-ọkàn mi, nítorí pé nínú ìbínú wọn, wọ́n pa àwọn ọkùnrin,+ àti nínú àìdúrógbẹ́jọ́ wọn, wọ́n já akọ màlúù ní pátì.  Ègún ni fún ìbínú wọn,+ nítorí tí ó níkà,+ àti ìbínú kíkan wọn, nítorí tí ó ń hùwà lọ́nà lílekoko.+ Jẹ́ kí n pín wọn sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ní Jékọ́bù, sì jẹ́ kí n tú wọn ká ní Ísírẹ́lì.+  “Ní ti ìwọ Júdà,+ àwọn arákùnrin rẹ yóò gbé ọ lárugẹ.+ Ọwọ́ rẹ yóò wà ní ẹ̀yìn ọrùn àwọn ọ̀tá rẹ.+ Àwọn ọmọ baba rẹ yóò wólẹ̀ fún ọ.+  Ọmọ kìnnìún ni Júdà.+ Ọmọkùnrin mi, láti inú ẹran ọdẹ ni ìwọ yóò ti gòkè lọ. Ó tẹrí ba, ó na ara rẹ̀ tàntàn bí kìnnìún, àti bí kìnníún, ta ní jẹ́ gbójú-gbóyà láti ta á jí?+ 10  Ọ̀pá aládé kì yóò yà kúrò lọ́dọ̀ Júdà,+ bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá àṣẹ kì yóò yà kúrò ní àárín ẹsẹ̀ rẹ̀, títí Ṣílò yóò fi dé;+ ìgbọràn àwọn ènìyàn yóò sì máa jẹ́ tirẹ̀.+ 11  Ní síso kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ tí ó ti dàgbà tán mọ́ àjàrà, àti ọmọ ìran abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ mọ́ ààyò àjàrà, dájúdájú, òun yóò fọ aṣọ rẹ̀ nínú wáìnì àti ẹ̀wù rẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ èso àjàrà.+ 12  Pípọ́n ṣẹ̀ẹ̀ ni ojú rẹ̀ nítorí wáìnì, funfun eyín rẹ̀ sì jẹ́ nítorí wàrà. 13  “Sébúlúnì yóò gbé ní etíkun,+ òun yóò sì wà ní èbúté níbi tí a ń dá àwọn ọkọ̀ òkun dúró sí;+ ìhà jíjìnnàréré rẹ̀ yóò sì wà níhà Sídónì.+ 14  “Ísákárì+ jẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ eléegun-líle, tí ń dùbúlẹ̀ láàárín àpò gàárì méjì. 15  Òun yóò sì rí i pé ibi ìsinmi náà dára àti pé ilẹ̀ náà wuni; òun yóò sì tẹ èjìká rẹ̀ wálẹ̀ láti ru ẹrù ìnira, òun yóò sì di ẹni tí ó wà lábẹ́ òpò àfipámúniṣe ti ìsìnrú. 16  “Dánì yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì.+ 17  Kí Dánì jẹ́ ejò lẹ́gbẹ̀ẹ́ ojú ọ̀nà, ejò abìwo ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà, tí ń bu gìgísẹ̀ ẹṣin ṣán tí ó fi jẹ́ pé ẹni tí ó gùn ún ṣubú sẹ́yìn.+ 18  Ní tòótọ́, èmi yóò dúró de ìgbàlà láti ọ̀dọ̀ rẹ, Jèhófà.+ 19  “Ní ti Gádì, ẹgbẹ́ onísùnmọ̀mí yóò gbé sùnmọ̀mí lọ bá a, ṣùgbọ́n òun yóò gbé sùnmọ̀mí lọ bá apá ẹ̀yìn pátápátá.+ 20  “Láti inú Áṣérì ni oúnjẹ rẹ̀ yóò ti lọ́ràá,+ òun yóò sì fúnni ní àwọn àdídùn ọba.+ 21  “Náfútálì+ jẹ́ egbin pẹ́lẹ́ńgẹ́. Ó ń fúnni ní àwọn ọ̀rọ̀ agbógoyọ.+ 22  “Èéhù igi tí ń so èso,+ Jósẹ́fù ni èéhù igi tí ń so èso lẹ́bàá ojúsun,+ tí ń yọ àwọn ẹ̀ka igi rẹ̀ sórí ògiri.+ 23  Ṣùgbọ́n àwọn tafàtafà ń fòòró rẹ̀ ṣáá, wọ́n sì ń ta á lọ́fà, wọ́n sì ń ṣe kèéta sí i.+ 24  Síbẹ̀, ọrun rẹ̀ ń gbé ní ibi wíwà títí lọ,+ okun ọwọ́ rẹ̀ sì rọ̀.+ Láti ọwọ́ Ẹni Alágbára ti Jékọ́bù,+ ibẹ̀ ni Olùṣọ́ Àgùntàn ti wá, Òkúta Ísírẹ́lì.+ 25  Láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run baba rẹ ni ó ti wá,+ òun yóò sì ràn ọ́ lọ́wọ́;+ òun sì wà pẹ̀lú Olódùmarè,+ òun yóò sì fi àwọn ìbùkún òkè ọ̀run bù kún ọ,+ pẹ̀lú àwọn ìbùkún ibú omi tí ó wà ní ìsàlẹ̀ lábẹ́lẹ̀,+ pẹ̀lú àwọn ìbùkún ọmú àti ilé ọlẹ̀.+ 26  Àwọn ìbùkún baba rẹ yóò ga lọ́lá ju àwọn ìbùkún òkè ńlá ayérayé+ lọ ní tòótọ́, ju ohun ọ̀ṣọ́ òkè kéékèèké tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ Wọn yóò máa wà lórí Jósẹ́fù, àní ní àtàrí ẹni tí a yà sọ́tọ̀ nínú àwọn arákùnrin rẹ̀.+ 27  “Bẹ́ńjámínì yóò máa fani ya bí ìkookò.+ Ní òwúrọ̀, òun yóò jẹ ẹran tí a mú, àti ní ìrọ̀lẹ́, òun yóò pín ohun ìfiṣèjẹ.”+ 28  Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ẹ̀yà méjèèjìlá Ísírẹ́lì, ohun tí baba wọn sì sọ fún wọn nìyí nígbà tí ó ń súre fún wọn. Ó súre fún wọn olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí ire tirẹ̀.+ 29  Lẹ́yìn ìyẹn, ó pàṣẹ fún wọn, ó sì wí fún wọn pé: “A óò kó mi jọ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn mi.+ Ẹ sin mí pẹ̀lú àwọn baba mi sínú hòrò tí ó wà nínú pápá Éfúrónì ọmọ Hétì,+ 30  sínú hòrò tí ó wà nínú pápá Mákípẹ́là tí ó wà ní iwájú Mámúrè ní ilẹ̀ Kénáánì, pápá tí Ábúráhámù rà lọ́wọ́ Éfúrónì ọmọ Hétì gẹ́gẹ́ bí ohun ìní láti fi sìnkú.+ 31  Ibẹ̀ ni wọ́n sin Ábúráhámù àti Sárà aya rẹ̀+ sí. Ibẹ̀ ni wọ́n sì sin Ísákì àti Rèbékà aya rẹ̀+ sí, ibẹ̀ ni mo sì sin Léà sí. 32  Pápá tí a rà àti hòrò tí ó wà nínú rẹ̀ jẹ́ láti ọwọ́ àwọn ọmọ Hétì.”+ 33  Nípa báyìí, Jékọ́bù parí pípa àṣẹ fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó kó ẹsẹ̀ rẹ̀ jọpọ̀ sórí àga ìrọ̀gbọ̀kú, ó sì gbẹ́mìí mì, a sì kó o jọ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé