Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jẹ́nẹ́sísì 48:1-22

48  Ó sì ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí pé a sọ fún Jósẹ́fù pé: “Wò ó, baba rẹ ń di aláìlera.” Látàrí ìyẹn, ó mú ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì, Mánásè àti Éfúráímù pẹ̀lú rẹ̀.+  Nígbà náà ni a ròyìn rẹ̀ fún Jékọ́bù pé: “Kíyè sí i, Jósẹ́fù ọmọkùnrin rẹ ti wá sọ́dọ̀ rẹ.” Nítorí náà, Ísírẹ́lì sa okun rẹ̀, ó sì dìde jókòó lórí àga ìrọ̀gbọ̀kú rẹ̀.  Jékọ́bù sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún Jósẹ́fù pé: “Ọlọ́run Olódùmarè fara hàn mí ní Lúsì+ ní ilẹ̀ Kénáánì, kí ó lè bù kún mi.+  Ó sì ń bá a lọ láti wí fún mi pé, ‘Kíyè sí i, èmi yóò mú kí o máa so èso,+ èmi yóò sì sọ ọ́ di púpọ̀, èmi yóò sì pa ọ́ dà di ìjọ àwọn ènìyàn,+ èmi yóò sì fi ilẹ̀ yìí fún irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ gẹ́gẹ́ bí ohun ìní fún àkókò tí ó lọ kánrin.’+  Wàyí o, ọmọkùnrin rẹ méjèèjì tí a bí fún ọ ní ilẹ̀ Íjíbítì, kí n tó wá sọ́dọ̀ rẹ níhìn-ín ní Íjíbítì, tèmi ni wọ́n.+ Éfúráímù àti Mánásè yóò di tèmi bí Rúbẹ́nì àti Síméónì.+  Ṣùgbọ́n àtọmọdọ́mọ rẹ tí ìwọ yóò bí lẹ́yìn wọn, yóò jẹ́ tìrẹ. A ó pè wọ́n pa pọ̀ pẹ̀lú orúkọ àwọn arákùnrin wọn níbi ogún wọn.+  Àti ní tèmi, nígbà tí mo ń bọ̀ láti Pádánì,+ Rákélì kú+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi ní ilẹ̀ Kénáánì lójú ọ̀nà nígbà tí ilẹ̀ tí ó lọ salalu ṣì wà, kí n tó dé Éfúrátì,+ nítorí náà, mo sin ín sí ibẹ̀ lójú ọ̀nà Éfúrátì, èyíinì ni Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.”+  Lẹ́yìn náà, Ísírẹ́lì rí àwọn ọmọkùnrin Jósẹ́fù, ó sì wí pé: “Àwọn wo nìwọ̀nyí?”+  Nítorí náà, Jósẹ́fù wí fún baba rẹ̀ pé: “Àwọn ọmọkùnrin mi tí Ọlọ́run fi fún mi ní ibí yìí ni.”+ Látàrí èyí, ó wí pé: “Jọ̀wọ́, mú wọn wá sọ́dọ̀ mi, kí n lè súre fún wọn.”+ 10  Wàyí o, ojú Ísírẹ́lì ti di bàìbàì nítorí ọjọ́ ogbó.+ Òun kò lè ríran. Nítorí náà, ó mú wọn sún mọ́ ọn, ó sì fi ẹnu kò wọ́n lẹ́nu, ó sì gbá wọn mọ́ra.+ 11  Ísírẹ́lì sì ń bá a lọ láti wí fún Jósẹ́fù pé: “Èmi kò lérò pé mo lè rí ojú rẹ,+ ṣùgbọ́n kíyè sí i, Ọlọ́run ti jẹ́ kí n rí ọmọ rẹ pẹ̀lú.” 12  Lẹ́yìn náà, Jósẹ́fù gbé wọn kúrò lórí eékún rẹ̀, ó sì tẹrí ba ní dídojúbolẹ̀.+ 13  Wàyí o, Jósẹ́fù mú àwọn méjèèjì, Éfúráímù ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ sí ọwọ́ òsì Ísírẹ́lì,+ àti Mánásè ní ọwọ́ òsì rẹ̀ sí ọwọ́ ọ̀tún Ísírẹ́lì,+ ó sì mú wọn sún mọ́ ọn. 14  Bí ó ti wù kí ó rí, Ísírẹ́lì na ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ó sì gbé e lé orí Éfúráímù,+ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni àbúrò,+ àti ọwọ́ òsì rẹ̀ lé orí Mánásè.+ Ó mọ̀ọ́mọ́ gbé ọwọ́ rẹ̀ bẹ́ẹ̀, níwọ̀n bí Mánásè ti jẹ́ àkọ́bí.+ 15  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí súre fún Jósẹ́fù pé:+ “Ọlọ́run tòótọ́, níwájú ẹni tí àwọn baba mi Ábúráhámù àti Ísákì rìn,+ Ọlọ́run tòótọ́ tí ó ti ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn mi ní gbogbo wíwà mi títí di òní,+ 16  Áńgẹ́lì tí ó ti ń gbà mí padà lọ́wọ́ gbogbo ìyọnu àjálù,+ bù kún àwọn ọmọdékùnrin yìí.+ Kí o sì jẹ́ kí a máa pe orúkọ mi àti orúkọ àwọn baba mi, Ábúráhámù àti Ísákì,+ mọ́ wọn lára, Kí o sì jẹ́ kí wọ́n di ògìdìgbó ní àárín ilẹ̀ ayé.”+ 17  Nígbà tí Jósẹ́fù rí i pé baba òun gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé orí Éfúráímù títí, kò dùn mọ́ ọn nínú,+ ó sì gbìyànjú láti di ọwọ́ baba rẹ̀ mú láti mú un kúrò lórí Éfúráímù sí orí Mánásè.+ 18  Nítorí náà, Jósẹ́fù wí fún baba rẹ̀ pé: “Kì í ṣe bẹ́ẹ̀ baba mi, nítorí pé èyí ni àkọ́bí.+ Gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ lé orí rẹ̀.” 19  Ṣùgbọ́n baba rẹ̀ ń kọ̀ ṣáá, ó sì wí pé: “Mo mọ̀, ọmọkùnrin mi, mo mọ̀. Òun pẹ̀lú yóò di ọ̀pọ̀ ènìyàn, òun pẹ̀lú yóò sì di ńlá.+ Ṣùgbọ́n, síbẹ̀síbẹ̀, àbúrò rẹ̀ yóò tóbi jù ú lọ,+ àwọn ọmọ rẹ̀ yóò sì di alábàádọ́gba lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè.”+ 20  Ó sì ń bá a lọ láti bù kún wọn ní ọjọ́ náà,+ pé: “Nípasẹ̀ rẹ ni kí Ísírẹ́lì máa súre léraléra pé, ‘Kí Ọlọ́run mú kí o dà bí Éfúráímù àti bí Mánásè.’”+ Nípa báyìí, ó ń fi Éfúráímù ṣáájú Mánásè.+ 21  Lẹ́yìn ìyẹn, Ísírẹ́lì wí fún Jósẹ́fù pé: “Wò ó, èmi ń kú lọ,+ ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò máa wà pẹ̀lú yín dájúdájú, yóò sì dá yín padà sí ilẹ̀ àwọn baba ńlá yín.+ 22  Ní ti èmi, mo fi èjìká ilẹ̀ kan fún ọ ju àwọn arákùnrin rẹ,+ èyí tí mo fi idà àti ọrun mi gbà ní ọwọ́ àwọn Ámórì.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé