Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jẹ́nẹ́sísì 47:1-31

47  Nítorí náà, Jósẹ́fù wá ròyìn fún Fáráò, ó sì wí pé:+ “Baba mi àti àwọn arákùnrin mi àti agbo ẹran wọn àti ọ̀wọ́ ẹran wọn àti gbogbo ohun tí wọ́n ní ti dé láti ilẹ̀ Kénáánì, sì kíyè sí i, wọ́n wà ní ilẹ̀ Góṣénì.”+  Ó sì mú ọkùnrin márùn-ún láti inú iye àwọn arákùnrin rẹ̀, kí ó lè fi wọ́n han Fáráò.+  Nígbà náà ni Fáráò sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé: “Kí ni iṣẹ́ àjókòótì yín?”+ Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sọ fún Fáráò pé: “Àwa ìránṣẹ́ rẹ jẹ́ olùda àgùntàn,+ àti àwa àti àwọn baba ńlá wa.”+  Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n sọ fún Fáráò pé: “A wá láti ṣe àtìpó ní ilẹ̀ yìí,+ nítorí pé kò sí pápá ìjẹko fún agbo ẹran tí àwa ìránṣẹ́ rẹ ní,+ nítorí ìyàn náà mú gidigidi ní ilẹ̀ Kénáánì.+ Wàyí o, jọ̀wọ́, jẹ́ kí àwa ìránṣẹ́ rẹ máa gbé ní ilẹ̀ Góṣénì.”+  Látàrí èyí, Fáráò wí fún Jósẹ́fù pé: “Baba rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ ti dé sí ọ̀dọ̀ rẹ níhìn-ín.  Ilẹ̀ Íjíbítì wà ní ìkáwọ́ rẹ.+ Mú kí baba rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ máa gbé ibi tí ó dára jù lọ ní ilẹ̀ yìí.+ Jẹ́ kí wọ́n máa gbé ní ilẹ̀ Góṣénì,+ bí o bá sì mọ̀ pé onìgboyà ọkùnrin+ wà láàárín wọn, kí o yàn wọ́n ṣe olórí ẹran ọ̀sìn lórí èyí tí ó jẹ́ tèmi.”+  Nígbà náà ni Jósẹ́fù mú Jékọ́bù baba rẹ̀ wọlé, ó sì mú un mọ Fáráò, Jékọ́bù sì bẹ̀rẹ̀ sí súre fún Fáráò.+  Wàyí o, Fáráò wí fún Jékọ́bù pé: “Mélòó ni ọjọ́ ọdún ìgbésí ayé rẹ?”  Nítorí náà, Jékọ́bù sọ fún Fáráò pé: “Ọjọ́ ọdún tí mo ti fi ṣe àtìpó jẹ́ àádóje ọdún.+ Ọjọ́ ọdún ìgbésí ayé mi kéré níye, ó sì kún fún wàhálà,+ wọn kò sì tíì tó ọjọ́ ọdún ìgbésí ayé àwọn baba mi ní ọjọ́ tí wọ́n fi ṣe àtìpó.”+ 10  Lẹ́yìn ìyẹn, Jékọ́bù súre fún Fáráò, ó sì jáde kúrò níwájú Fáráò.+ 11  Nípa báyìí, Jósẹ́fù mú kí baba rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ máa gbé ibẹ̀, ó sì fún wọn ní ohun ìní ní ilẹ̀ Íjíbítì, ní ibi dídára jù lọ ní ilẹ̀ náà, ní ilẹ̀ Rámésésì,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí Fáráò ti pàṣẹ. 12  Jósẹ́fù sì ń pèsè oúnjẹ+ fún baba rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo agbo ilé baba rẹ̀ pátá, ní ìbámu pẹ̀lú iye àwọn ọmọ kéékèèké.+ 13  Wàyí o, kò sí oúnjẹ ní gbogbo ilẹ̀ náà, nítorí pé ìyàn náà mú gidigidi;+ ilẹ̀ Íjíbítì àti ilẹ̀ Kénáánì sì gbẹ táútáú nítorí ìyàn náà.+ 14  Jósẹ́fù sì ń ṣàkójọ gbogbo owó tí a lè rí ní ilẹ̀ Íjíbítì àti ní ilẹ̀ Kénáánì fún àwọn hóró ọkà tí àwọn ènìyàn ń rà;+ Jósẹ́fù sì ń mú owó náà wá sínú ilé Fáráò. 15  Nígbà tí ó ṣe, owó tí ń ti ilẹ̀ Íjíbítì àti ilẹ̀ Kénáánì wá tán, gbogbo àwọn ará Íjíbítì sì bẹ̀rẹ̀ sí wá sọ́dọ̀ Jósẹ́fù, wọ́n wí pé: “Fún wa ní oúnjẹ!+ Èé sì ti ṣe tí àwa yóò fi kú ní iwájú rẹ nítorí pé owó ti tán?” 16  Nígbà náà ni Jósẹ́fù wí pé: “Ẹ mú ohun ọ̀sìn yín wá, èmi yóò sì fún yín ní oúnjẹ ní pàṣípààrọ̀ fún ohun ọ̀sìn yín, bí owó bá ti tán.”+ 17  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí mú ohun ọ̀sìn wọn wá fún Jósẹ́fù; Jósẹ́fù sì ń fún wọn ní oúnjẹ ní pàṣípààrọ̀ fún àwọn ẹṣin àti ohun ọ̀sìn agbo ẹran àti ohun ọ̀sìn ọ̀wọ́ ẹran àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,+ ó sì ń pèsè oúnjẹ fún wọn ní pàṣípààrọ̀ fún gbogbo ohun ọ̀sìn wọn ní ọdún yẹn. 18  Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ọdún yẹn wá sí òpin rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní ọdún tí ó tẹ̀ lé e, wọ́n sì wí fún un pé: “Àwa kò ní fi í pa mọ́ fún olúwa mi ṣùgbọ́n a ti ná owó àti ìpèsè ẹran agbéléjẹ̀ fún olúwa mi.+ Kò ku nǹkan kan níwájú olúwa mi bí kò ṣe ara wa àti ilẹ̀ wa.+ 19  Èé ṣe tí àwa yóò fi kú ní ojú rẹ,+ àti àwa àti ilẹ̀ wa? Fi oúnjẹ ra àwa àti ilẹ̀ wa,+ àwa àti ilẹ̀ wa yóò sì di ẹrú Fáráò; kí o sì fún wa ní irúgbìn kí a lè wà láàyè, kí a má kú, kí ilẹ̀ wa má sì di ahoro.”+ 20  Nítorí náà, Jósẹ́fù ra gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Íjíbítì fún Fáráò,+ nítorí pé olúkúlùkù ará Íjíbítì ta pápá rẹ̀, nítorí tí ìyàn náà mú wọn gidigidi; ilẹ̀ náà sì wá di ti Fáráò. 21  Ní ti àwọn ènìyàn náà, ó kó wọn kúrò lọ sínú ìlú ńlá láti ìpẹ̀kun ìpínlẹ̀ kan Íjíbítì sí ìpẹ̀kun rẹ̀ kejì.+ 22  Ilẹ̀ àwọn àlùfáà nìkan ni òun kò rà,+ nítorí pé ìpín àwọn àlùfáà ń wá láti ọ̀dọ̀ Fáráò, wọ́n sì ń jẹ ìpín wọn tí Fáráò fi fún wọn.+ Ìdí nìyẹn tí wọn kò fi ta ilẹ̀ wọn.+ 23  Nígbà náà ni Jósẹ́fù wí fún àwọn ènìyàn náà pé: “Ẹ wò ó, mo ti ra ẹ̀yin àti ilẹ̀ yín fún Fáráò lónìí. Irúgbìn nìyí fún yín, kí ẹ sì gbìn ín sí ilẹ̀ náà.+ 24  Nígbà tí ó bá ti mú èso+ wá, nígbà náà, kí ẹ fi ìdá márùn-ún fún Fáráò,+ ṣùgbọ́n apá mẹ́rin yóò jẹ́ tiyín, gẹ́gẹ́ bí irúgbìn fún pápá àti gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ fún yín àti fún àwọn tí wọ́n wà ní ilé yín àti fún àwọn ọmọ yín kéékèèké láti jẹ.”+ 25  Nítorí náà, wọ́n wí pé: “O ti pa ìwàláàyè wa mọ́.+ Jẹ́ kí a rí ojú rere ní ojú olúwa mi, àwa yóò sì di ẹrú Fáráò.”+ 26  Jósẹ́fù sì tẹ̀ síwájú láti sọ ọ́ di àṣẹ àgbékalẹ̀ títí di òní yìí lórí ilẹ̀ ìní Íjíbítì fún Fáráò láti ní ìdá márùn-ún. Kìkì ilẹ̀ àwọn àlùfáà gẹ́gẹ́ bí àwùjọ tí ó yàtọ̀ ni kò di ti Fáráò.+ 27  Ísírẹ́lì sì ń bá a lọ láti máa gbé ní ilẹ̀ Íjíbítì, ní ilẹ̀ Góṣénì;+ wọ́n sì tẹ̀ dó sínú rẹ̀, wọ́n sì ń so èso, wọ́n sì gbèrú láti di púpọ̀ gan-an.+ 28  Jékọ́bù sì ń bá a nìṣó láti gbé ní ilẹ̀ Íjíbítì fún ọdún mẹ́tàdínlógún, tí ó fi jẹ́ pé ọjọ́ Jékọ́bù, ọdún ìgbésí ayé rẹ̀, wá jẹ́ ọdún mẹ́tà-dín-láàádọ́jọ.+ 29  Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ọjọ́ sún mọ́lé fún Ísírẹ́lì láti kú.+ Nítorí náà, ó pe Jósẹ́fù ọmọkùnrin rẹ̀, ó sì wí fún un pé: “Wàyí o, bí mo bá ti rí ojú rere ní ojú rẹ, jọ̀wọ́, fi ọwọ́ rẹ sí abẹ́ itan mi,+ kí ìwọ sì lo inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti ìṣeégbẹ́kẹ̀lé sí mi.+ (Jọ̀wọ́, má sin mí sí Íjíbítì.)+ 30  Èmi yóò sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba mi,+ kí ìwọ sì gbé mi jáde kúrò ní Íjíbítì, kí o sì sin mí sínú sàréè wọn.”+ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó wí pé: “Èmi yóò ṣe bẹ́ẹ̀ ní pípa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́.” 31  Nígbà náà ni ó wí pé: “Búra fún mi.” Nítorí náà, ó búra fún un.+ Látàrí ìyẹn, Ísírẹ́lì wólẹ̀ lórí àga ìrọ̀gbọ̀kú.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé