Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jẹ́nẹ́sísì 46:1-34

46  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Ísírẹ́lì àti gbogbo àwọn tí ó jẹ́ tirẹ̀ ṣí, wọ́n sì dé Bíá-ṣébà,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rúbọ sí Ọlọ́run baba rẹ̀ Ísákì.+  Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run bá Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ nínú ìran ní òru, ó sì wí pé:+ “Jékọ́bù, Jékọ́bù!” òun sì dáhùn pé: “Èmi nìyí!”+  Ó sì ń bá a lọ láti wí pé: “Èmi ni Ọlọ́run tòótọ́,+ Ọlọ́run baba rẹ.+ Má fòyà láti sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Íjíbítì, nítorí tí èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá+ níbẹ̀.  Èmi fúnra mi yóò bá ọ sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Íjíbítì, èmi fúnra mi yóò sì mú ọ gòkè pẹ̀lú;+ Jósẹ́fù yóò sì fi ọwọ́ rẹ̀ lé ojú rẹ.”+  Lẹ́yìn ìyẹn, Jékọ́bù gbéra kúrò ní Bíá-ṣébà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ń bá a nìṣó ní gbígbé Jékọ́bù baba wọn àti àwọn ọmọ wọn kéékèèké àti àwọn aya wọn lọ nínú àwọn kẹ̀kẹ́ tí Fáráò fi ránṣẹ́ láti gbé e.+  Síwájú sí i, wọ́n kó ọ̀wọ́ ẹran wọn àti àwọn ẹrù wọn, èyí tí wọ́n ti kó jọ rẹpẹtẹ ní ilẹ̀ Kénáánì.+ Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n dé Íjíbítì, Jékọ́bù àti gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀.  Àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọkùnrin tí ó jẹ́ ti ọmọkùnrin rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọbìnrin tí ó jẹ́ ti ọmọkùnrin rẹ̀, àní gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀, pẹ̀lú rẹ̀ ni ó kó wá sí Íjíbítì.+  Wàyí o, ìwọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì tí ó wá sí Íjíbítì:+ Jékọ́bù àti àwọn ọmọ rẹ̀: àkọ́bí Jékọ́bù ni Rúbẹ́nì.+  Àwọn ọmọkùnrin Rúbẹ́nì sì ni Hánókù àti Pálù àti Hésírónì àti Kámì.+ 10  Àwọn ọmọkùnrin Síméónì+ sì ni Jémúélì àti Jámínì àti Óhádì àti Jákínì+ àti Sóhárì àti Ṣọ́ọ̀lù+ ọmọkùnrin obìnrin ará Kénáánì kan. 11  Àwọn ọmọkùnrin Léfì+ sì ni Gẹ́ṣónì,+ Kóhátì+ àti Mérárì.+ 12  Àwọn ọmọkùnrin Júdà+ sì ni Éérì+ àti Ónánì+ àti Ṣélà+ àti Pérésì+ àti Síírà.+ Àmọ́ ṣá o, Éérì àti Ónánì kú ní ilẹ̀ Kénáánì.+ Àwọn ọmọkùnrin Pérésì sì ni Hésírónì+ àti Hámúlù.+ 13  Àwọn ọmọkùnrin Ísákárì+ sì ni Tólà+ àti Púfà+ àti Íóbù àti Ṣímúrónì.+ 14  Àwọn ọmọkùnrin Sébúlúnì+ sì ni Sérédì àti Élónì àti Jálíẹ́lì.+ 15  Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Léà,+ tí ó bí fún Jékọ́bù ní Padani-árámù, pa pọ̀ pẹ̀lú ọmọbìnrin rẹ̀ Dínà.+ Gbogbo ọkàn àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ jẹ́ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n. 16  Àwọn ọmọkùnrin Gádì+ sì ni Sífíónì àti Hágì, Ṣúnì àti Ésíbónì, Érì àti Áródì àti Árélì.+ 17  Àwọn ọmọkùnrin Áṣérì+ sì ni Ímúnà àti Íṣífà àti Íṣífì àti Bẹráyà,+ Sérà sì ni arábìnrin wọn. Àwọn ọmọkùnrin Bẹráyà sì ni Hébà àti Málíkíélì.+ 18  Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Sílípà,+ tí Lábánì fi fún Léà ọmọbìnrin rẹ̀. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó bí ìwọ̀nyí fún Jékọ́bù: ọkàn mẹ́rìndínlógún. 19  Àwọn ọmọkùnrin Rákélì,+ aya Jékọ́bù, ni Jósẹ́fù+ àti Bẹ́ńjámínì.+ 20  A sì wá bí Mánásè+ àti Éfúráímù+ fún Jósẹ́fù ní ilẹ̀ Íjíbítì, àwọn tí Ásénátì,+ ọmọbìnrin Pọ́tíférà àlùfáà Ónì bí fún un. 21  Àwọn ọmọkùnrin Bẹ́ńjámínì sì ni Bélà+ àti Békérì+ àti Áṣíbélì, Gérà+ àti Náámánì,+ Éhì àti Róṣì, Múpímù+ àti Húpímù+ àti Áádì. 22  Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Rákélì tí a bí fún Jékọ́bù. Gbogbo ọkàn náà jẹ́ mẹ́rìnlá. 23  Àwọn ọmọkùnrin Dánì+ sì ni Húṣímù.+ 24  Àwọn ọmọkùnrin Náfútálì+ sì ni Jáséélì àti Gúnì+ àti Jésérì àti Ṣílẹ́mù.+ 25  Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Bílíhà,+ tí Lábánì fi fún Rákélì ọmọbìnrin rẹ̀. Nígbà tí ó ṣe, ó bí ìwọ̀nyí fún Jékọ́bù; gbogbo ọkàn náà jẹ́ méje. 26  Gbogbo ọkàn tí ó tọ Jékọ́bù wá sí Íjíbítì jẹ́ àwọn tí ó jáde wá láti òkè itan rẹ̀,+ yàtọ̀ sí àwọn aya àwọn ọmọkùnrin Jékọ́bù. Gbogbo ọkàn náà jẹ́ mẹ́rìn-dín-láàádọ́rin. 27  Àwọn ọmọkùnrin Jósẹ́fù tí a bí fún un ní Íjíbítì sì jẹ́ ọkàn méjì. Gbogbo ọkàn ilé Jékọ́bù tí wọ́n wá sí Íjíbítì jẹ́ àádọ́rin.+ 28  Ó sì rán Júdà+ ṣíwájú rẹ̀ sí Jósẹ́fù láti fún un ní ìsọfúnni de òun ní Góṣénì. Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n dé ilẹ̀ Góṣénì.+ 29  Nígbà náà ni Jósẹ́fù múra kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ sílẹ̀, ó sì gòkè lọ láti pàdé Ísírẹ́lì baba rẹ̀ ní Góṣénì.+ Nígbà tí ó yọ sí i, lójú-ẹsẹ̀ ni ó gbórí lé e lọ́rùn, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí da omijé sí i lọ́rùn léraléra.+ 30  Níkẹyìn, Ísírẹ́lì wí fún Jósẹ́fù pé: “Ní báyìí, mo múra tán láti kú,+ nísinsìnyí tí mo ti rí ojú rẹ, níwọ̀n bí o ti wà láàyè síbẹ̀.” 31  Nígbà náà ni Jósẹ́fù wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ àti fún agbo ilé baba rẹ̀ pé: “Ẹ jẹ́ kí n gòkè lọ ròyìn fún Fáráò, kí n sì wí fún un pé,+ ‘Àwọn arákùnrin mi àti agbo ilé baba mi tí ó wà ní ilẹ̀ Kénáánì ti dé sọ́dọ̀ mi níhìn-ín.+ 32  Àwọn ènìyàn náà sì jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn,+ nítorí pé wọ́n jẹ́ olùsin ohun ọ̀sìn;+ agbo ẹran wọn àti ọ̀wọ́ ẹran wọn àti gbogbo ohun tí wọ́n ní ni wọ́n sì ti kó wá síhìn-ín.’+ 33  Ohun tí yóò sì ṣẹlẹ̀ ni pé, nígbà tí Fáráò bá pè yín, tí ó sì wí ní tòótọ́ pé, ‘Kí ni iṣẹ́ àjókòótì yín?’ 34  Kí ẹ sọ pé, ‘Àwa ìránṣẹ́ rẹ ti ń bá a lọ láti jẹ́ olùsin ohun ọ̀sìn láti ìgbà èwe wa títí di ìsinsìnyí, àti àwa àti àwọn baba ńlá wa,’+ kí ẹ bàa lè máa gbé ní ilẹ̀ Góṣénì,+ nítorí pé gbogbo olùda àgùntàn jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Íjíbítì.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé