Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jẹ́nẹ́sísì 45:1-28

45  Látàrí èyí, kò ṣeé ṣe fún Jósẹ́fù mọ́ láti ṣàkóso ara rẹ̀ níwájú gbogbo àwọn tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.+ Nítorí náà, ó ké jáde pé: “Ẹ mú kí gbogbo ènìyàn jáde kúrò ní ọ̀dọ̀ mi!” Kò sì sí ẹnì kankan lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tí Jósẹ́fù sọ ara rẹ̀ di mímọ̀ fún àwọn arákùnrin rẹ̀.+  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ohùn rẹ̀ sókè nínú ẹkún sísun,+ tí ó fi jẹ́ pé àwọn ará Íjíbítì gbọ́, ilé Farao sì gbọ́.  Níkẹyìn, Jósẹ́fù wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé: “Èmi ni Jósẹ́fù. Ṣé baba mi ṣì wà láàyè?” Ṣùgbọ́n àwọn arákùnrin rẹ̀ kò lè dá a lóhùn rárá, nítorí pé ìyọnu bá wọ́n nítorí rẹ̀.+  Nítorí náà, Jósẹ́fù wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ sún mọ́ mi.” Látàrí ìyẹn, wọ́n sún mọ́ ọn. Nígbà náà ni ó wí pé: “Èmi ni Jósẹ́fù arákùnrin yín, tí ẹ tà sí Íjíbítì.+  Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, ẹ má ṣe jẹ́ kí inú yín bàjẹ́,+ ẹ má sì ṣe bínú sí ara yín nítorí pé ẹ tà mí síhìn-ín; nítorí àtipa ìwàláàyè mọ́ ni Ọlọ́run fi rán mi ṣáájú yín.+  Nítorí, èyí ni ọdún kejì ìyàn ní ilẹ̀ ayé,+ ọdún márùn-ún ṣì ń bẹ síbẹ̀ nínú èyí tí kò ní sí ìgbà ìtúlẹ̀ tàbí ìkórè.+  Nítorí náà, Ọlọ́run rán mi ṣáájú yín, kí a lè fi àṣẹ́kù sílẹ̀+ fún yín lórí ilẹ̀ ayé àti láti pa yín mọ́ láàyè nípasẹ̀ àsálà ńlá.  Ǹjẹ́ nísinsìnyí, kì í ṣe ẹ̀yin ni ó rán mi síhìn-ín,+ bí kò ṣe Ọlọ́run tòótọ́, kí ó lè yàn mí ṣe baba+ fún Fáráò àti olúwa fún gbogbo ilé rẹ̀ àti gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń jọba lórí gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì.  “Ẹ tètè gòkè lọ sọ́dọ̀ baba mi, kí ẹ sì wí fún un pé, ‘Èyí ni ohun tí Jósẹ́fù ọmọkùnrin rẹ wí: “Ọlọ́run ti yàn mí ṣe olúwa fún gbogbo Íjíbítì.+ Sọ̀ kalẹ̀ wá sọ́dọ̀ mi. Má ṣe jáfara. 10  Kí ìwọ sì máa gbé ilẹ̀ Góṣénì,+ kí o sì máa bá a lọ nítòsí mi, ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ àti àwọn agbo ẹran rẹ àti ọ̀wọ́ ẹran rẹ àti ohun gbogbo tí o ní. 11  Èmi yóò sì pèsè oúnjẹ fún ọ níbẹ̀, nítorí ọdún márùn-ún ìyàn ni ó ṣì kù;+ kí ó má bàa di pé ìwọ àti ilé rẹ àti ohun gbogbo tí o ní wà ní ipò òṣì.”’ 12  Sì kíyè sí i, ojú yín àti ojú arákùnrin mi Bẹ́ńjámínì rí i pé ẹnu mi ni ó ń bá yín sọ̀rọ̀.+ 13  Nítorí náà, kí ẹ sọ fún baba mi nípa gbogbo ògo mi ní Íjíbítì àti ohun gbogbo tí ẹ ti rí; kí ẹ sì ṣe wéré láti mú baba mi sọ̀ kalẹ̀ wá síhìn-ín.” 14  Lẹ́yìn náà, ó rọ̀ mọ́ ọrùn Bẹ́ńjámínì arákùnrin rẹ̀, ó sì bú sẹ́kún, Bẹ́ńjámínì sì sunkún ní ọrùn rẹ̀.+ 15  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹnu ko gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ lẹ́nu, ó sì ń sunkún sí wọn lọ́rùn,+ lẹ́yìn náà, àwọn arákùnrin rẹ̀ bá a sọ̀rọ̀. 16  A sì gbọ́ ìhìn náà ní ilé Fáráò, pé: “Àwọn arákùnrin Jósẹ́fù ti dé!” Ó sì dára ní ojú Fáráò àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.+ 17  Nítorí náà, Farao sọ fún Jósẹ́fù pé: “Sọ fún àwọn arákùnrin rẹ pé, ‘Ẹ ṣe èyí: Ẹ di ẹrù lé àwọn ẹranko arẹrù yín, kí ẹ sì wọ ilẹ̀ Kénáánì lọ,+ 18  kí ẹ sì mú baba yín àti agbo ilé yín, kí ẹ sì wá sọ́dọ̀ mi níbí, kí n lè fún yín ní ohun rere ilẹ̀ Íjíbítì; kí ẹ sì jẹ apá tí ó lọ́ràá ní ilẹ̀ náà.+ 19  A sì pàṣẹ fún ìwọ alára pé:+ “Ṣe èyí: Ẹ kó àwọn kẹ̀kẹ́+ fún ara yín láti ilẹ̀ Íjíbítì fún àwọn ọmọ yín kéékèèké àti àwọn aya yín, kí ẹ sì gbé baba yín lé ọ̀kan kí ẹ sì wá síbí.+ 20  Ẹ má sì jẹ́ kí ojú yín káàánú fún ohun ìṣiṣẹ́ yín,+ nítorí tí ohun rere gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì jẹ́ tiyín.”’”+ 21  Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe bẹ́ẹ̀, Jósẹ́fù sì fún wọn ní àwọn kẹ̀kẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ ìtọ́ni láti ọ̀dọ̀ Fáráò, ó sì fún wọn ní àwọn ìpèsè+ ìlò lójú ọ̀nà. 22  Ó fi ìpààrọ̀ aṣọ àlàbora+ fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, ṣùgbọ́n Bẹ́ńjámínì ni ó fi ọ̀ọ́dúnrún ẹyọ fàdákà àti ìpààrọ̀ aṣọ àlàbora+ márùn-ún fún. 23  Baba rẹ̀ ni ó sì fi ohun tí ó tẹ̀ lé yìí ránṣẹ́ sí: kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá tí ó ru ohun rere Íjíbítì àti abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá tí ó ru ọkà àti búrẹ́dì àti ohun ìgbẹ́mìíró fún ìlò baba rẹ̀ ní ọ̀nà. 24  Nípa báyìí, ó rán àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ. Bí ó ti wù kí ó rí, ó wí fún wọn pé: “Ẹ má ṣe dá ara yín lágara lójú ọ̀nà.”+ 25  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gòkè lọ kúrò ní Íjíbítì, nígbà tí ó sì yá, wọ́n dé ilẹ̀ Kénáánì lọ́dọ̀ Jékọ́bù baba wọn. 26  Nígbà náà ni wọ́n ròyìn fún un pé: “Jósẹ́fù ṣì wà láàyè, òun sì ni ó ń jọba lórí gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì!”+ Ṣùgbọ́n ọkàn-àyà rẹ̀ kú tipiri, nítorí pé kò gbà wọ́n gbọ́.+ 27  Nígbà tí wọ́n ń sọ gbogbo ọ̀rọ̀ Jósẹ́fù tí ó ti sọ fún wọn fún un, tí ó sì wá rí àwọn kẹ̀kẹ́ tí Jósẹ́fù fi ránṣẹ́ láti gbé e, ẹ̀mí Jékọ́bù baba wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ jí.+ 28  Nígbà náà ni Ísírẹ́lì figbe ta pé: “Ó tó! Jósẹ́fù ọmọkùnrin mi ṣì wà láàyè! Áà, jẹ́ kí n lọ rí i kí n tó kú!”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé