Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jẹ́nẹ́sísì 43:1-34

43  Ìyàn náà sì mú gidigidi ní ilẹ̀ náà.+  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí wọ́n jẹ hóró ọkà tí wọ́n mú wá láti Íjíbítì tán,+ baba wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún wọn pé: “Ẹ padà lọ, ẹ ra oúnjẹ díẹ̀ fún wa.”+  Nígbà náà ni Júdà wí fún un pé:+ “Ọkùnrin náà fún wa ní ẹ̀rí dídánilójú pé, ‘Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ tún rí ojú mi mọ́, bí kò ṣe pé arákùnrin yín wà pẹ̀lú yín.’+  Bí ìwọ yóò bá rán arákùnrin wa pẹ̀lú wa,+ a múra tán láti sọ̀ kalẹ̀ lọ ra oúnjẹ fún ọ.  Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá ní rán an, àwa kì yóò sọ̀ kalẹ̀ lọ, nítorí pé ọkùnrin náà sọ fún wa pé, ‘Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ tún rí ojú mi mọ́, bí kò ṣe pé arákùnrin yín bá wà pẹ̀lú yín.’”+  Ísírẹ́lì sì figbe ta pé:+ “Èé ṣe tí ẹ̀yin fi ní láti ṣe ìpalára fún mi nípa sísọ fún ọkùnrin náà pé ẹ ní arákùnrin mìíràn?”  Látàrí èyí, wọ́n wí pé: “Ọkùnrin náà wádìí ní tààràtà nípa wa àti àwọn ìbátan wa, pé, ‘Ṣé baba yín ṣì wà láàyè?+ Ṣé ẹ ní arákùnrin mìíràn?’ àwa náà sì ń bá a lọ láti sọ fún un ní ìbámu pẹ̀lú òtítọ́ wọ̀nyí.+ Báwo ni àwa ṣe lè mọ̀ dájú pé òun yóò sọ pé, ‘Ẹ mú arákùnrin yín sọ̀ kalẹ̀ wá’?”+  Níkẹyìn, Júdà sọ fún Ísírẹ́lì baba rẹ̀ pé: “Rán ọmọdékùnrin náà pẹ̀lú mi,+ kí a lè dìde, kí a sì lọ, kí a lè máa wà láàyè nìṣó, kí a má sì kú dànù,+ àti àwa àti ìwọ àti àwọn ọmọ wa kéékèèké.+  Èmi ni yóò jẹ́ onídùúró fún un.+ Ọwọ́ mi ni kí o ti yọró ìdájọ́ rẹ̀.+ Bí mo bá kùnà láti mú un wá fún ọ, kí n sì fi í lé ọ lọ́wọ́, nígbà náà, èmi yóò ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ títí láé. 10  Ṣùgbọ́n bí kì í bá ṣe pé a ń lọ́ra ni, nísinsìnyí à bá ti lọ bọ̀ lẹ́ẹ̀mejì báyìí.”+ 11  Nítorí náà, Ísírẹ́lì baba wọn wí fún wọn pé: “Nígbà náà, bí ó bá ṣe pé bí ọ̀ràn ti rí nìyẹn,+ ẹ ṣe báyìí: Ẹ kó àmújáde dídára jù lọ ilẹ̀ yìí sínú àwọn ìkóhunsí yín, kí ẹ sì mú un lọ fún ọkùnrin náà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn:+ básámù+ díẹ̀, àti oyin+ díẹ̀, gọ́ọ̀mù lábídánúmù àti èèpo-igi olóje,+ ẹ̀pà pítáṣíò àti álímọ́ńdì.+ 12  Kí ẹ tún mú owó ìlọ́po méjì lọ́wọ́; àti owó tí a dá padà sí ẹnu àpò yín ni ẹ̀yin yóò mú padà ní ọwọ́ yín.+ Bóyá àṣìṣe ni.+ 13  Kí ẹ mú arákùnrin yín, kí ẹ sì gbéra, kí ẹ padà sọ́dọ̀ ọkùnrin náà. 14  Kí Ọlọ́run Olódùmarè sì ṣe ojú àánú sí yín ní ojú ọkùnrin náà,+ kí ó lè tú arákùnrin yín tọ̀hún àti Bẹ́ńjámínì sílẹ̀ fún yín dájúdájú. Ṣùgbọ́n èmi, bí ó bá ṣe pé ọ̀fọ̀ yóò ṣẹ̀ mí, dájúdájú, ọ̀fọ̀ yóò ṣẹ̀ mí!”+ 15  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn ọkùnrin náà mú ẹ̀bùn yìí, wọ́n sì mú ìlọ́po owó méjì náà lọ́wọ́, àti Bẹ́ńjámínì. Nígbà náà ni wọ́n gbéra, wọ́n sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Íjíbítì, wọ́n wá dúró níwájú Jósẹ́fù.+ 16  Nígbà tí Jósẹ́fù rí Bẹ́ńjámínì pẹ̀lú wọn, ní kíá, ó sọ fún ọkùnrin tí ó jẹ́ olórí ilé rẹ̀ pé: “Mú àwọn ọkùnrin náà lọ sínú ilé, kí o sì pa ẹran, kí o sì pèsè sílẹ̀,+ nítorí pé àwọn ọkùnrin náà yóò bá mi jẹun ní ọ̀sán.” 17  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ọkùnrin náà ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí Jósẹ́fù ti wí.+ Nípa bẹ́ẹ̀, ọkùnrin náà mú àwọn ọkùnrin náà lọ sí ilé Jósẹ́fù. 18  Ṣùgbọ́n àyà fo àwọn ọkùnrin náà nítorí pé a mú wọn lọ sí ilé Jósẹ́fù,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Tìtorí owó tí ó bá wa padà nínú àwọn àpò wa nígbà àkọ́kọ́ ni a ṣe mú wa wá síhìn-ín, kí wọ́n lè rọ́ lù wá, kí wọ́n sì gbéjà kò wá, kí wọ́n sì lè kó wa ṣe ẹrú àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wa pẹ̀lú!”+ 19  Nítorí náà, wọ́n tọ ọkùnrin tí ó jẹ́ olórí ilé Jósẹ́fù lọ, wọ́n sì bá a sọ̀rọ̀ ní ẹnu ọ̀nà ilé náà, 20  wọ́n sì wí pé: “Dákun, olúwa mi! Dájúdájú, a wá nígbà àkọ́kọ́ láti ra oúnjẹ.+ 21  Ṣùgbọ́n ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ni pé, nígbà tí a dé ibùwọ̀,+ tí a sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣí àwọn àpò wa, họ́wù, owó olúkúlùkù rèé ní ẹnu àpò rẹ̀, owó wa ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwọ̀n. Nítorí náà, àwa yóò fẹ́ fi ọwọ́ ara wa dá a padà.+ 22  Owó púpọ̀ sí i ni a sì mú wá ní ọwọ́ wa láti fi ra oúnjẹ. Dájúdájú, a kò mọ ẹni tí ó fi owó wa sínú àwọn àpò wa.”+ 23  Nígbà náà ni ó wí pé: “Ẹ kò ní ìṣòro. Ẹ má fòyà.+ Ọlọ́run yín àti Ọlọ́run baba yín ni ó fún yín ní ìṣúra nínú àwọn àpò yín.+ Owó yín kọ́kọ́ wá sọ́dọ̀ mi.” Lẹ́yìn náà, ó mú Síméónì jáde wá bá wọn.+ 24  Lẹ́yìn náà, ọkùnrin náà mú àwọn ọkùnrin náà wá sí ilé Jósẹ́fù, ó sì pèsè omi, kí wọ́n lè wẹ ẹsẹ̀ wọn,+ ó sì pèsè oúnjẹ ẹran fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn.+ 25  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣètò ẹ̀bùn náà+ sílẹ̀ fún dídé Jósẹ́fù ní ọ̀sán, nítorí pé wọ́n ti gbọ́ pé ibẹ̀ ni àwọn yóò ti jẹun.+ 26  Nígbà tí Jósẹ́fù wọ inú ilé lọ, nígbà náà ni wọ́n mú ẹ̀bùn tí ó wà ní ọwọ́ wọn wá fún un nínú ilé, wọ́n sì wólẹ̀ fún un.+ 27  Lẹ́yìn èyí, ó wádìí bóyá wọ́n wà dáadáa, ó sì wí pé:+ “Ṣé baba yín, àgbàlagbà, tí ẹ sọ̀rọ̀ rẹ̀, wà dáadáa? Ṣé ó ṣì wà láàyè?”+ 28  Wọ́n fèsì pé: “Ìránṣẹ́ rẹ, baba wa, wà dáadáa. Ó ṣì wà láàyè.” Lẹ́yìn náà, wọ́n tẹrí ba, wọ́n sì wólẹ̀.+ 29  Nígbà tí ó gbé ojú rẹ̀ sókè, tí ó sì rí Bẹ́ńjámínì arákùnrin rẹ̀, ọmọkùnrin ìyá rẹ̀,+ ó ń bá a lọ láti wí pé: “Ṣé arákùnrin yín, àbíkẹ́yìn tí ẹ sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún mi nìyí?”+ Ó sì fi kún un pé: “Kí Ọlọ́run fi ojú rere rẹ̀ hàn sí ọ,+ ọmọkùnrin mi.” 30  Jósẹ́fù ti ń kánjú wàyí, nítorí pé àwọn èrò ìmọ̀lára inú rẹ̀ lọ́hùn-ún ru sókè sí arákùnrin rẹ̀,+ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi wá [ibì kan] láti sunkún, ó sì wọ yàrá kan ní inú lọ́hùn-ún, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí da omijé níbẹ̀.+ 31  Lẹ́yìn náà, ó wẹ ojú rẹ̀, ó jáde, ó sì kó ara rẹ̀ níjàánu, ó sì wí pé:+ “Ẹ gbé oúnjẹ kalẹ̀.”+ 32  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé tirẹ̀ kalẹ̀ fún un lọ́tọ̀ àti tiwọn lọ́tọ̀ àti fún àwọn ara Íjíbítì tí wọ́n ń bá a jẹun lọ́tọ̀; nítorí pé àwọn ará Íjíbítì kò lè bá àwọn Hébérù jẹun, nítorí tí ìyẹn jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú àwọn ará Íjíbítì.+ 33  A sì mú wọn jókòó níwájú rẹ̀, àkọ́bí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀tọ́ rẹ̀ bí àkọ́bí+ àti àbíkẹ́yìn bí ó ṣe kéré sí; àwọn ọkùnrin náà sì bẹ̀rẹ̀ sí wo ara wọn pẹ̀lú kàyéfì. 34  Ó sì ń bù lára oúnjẹ ọ̀dọ̀ rẹ̀ fún wọn, ṣùgbọ́n òun yóò mú ìpín Bẹ́ńjámínì pọ̀ sí i ní ìlọ́po márùn-ún ju ìwọ̀n ìpín gbogbo àwọn yòókù.+ Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n ń bá a lọ ní bíbá a jẹ àkànṣe àsè àti ní mímu tẹ́rùntẹ́rùn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé